bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Leviticus 1
Leviticus 1
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 2 →
1
OLUWA si pè Mose, o si sọ fun u lati inu agọ́ ajọ wa, pe,
2
Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikan ninu nyin ba mú ọrẹ-ẹbọ wá fun OLUWA, ki ẹnyin ki o mú ọrẹ-ẹbọ nyin wá ninu ohunọ̀sin, ani ti inu ọwọ́-ẹran, ati ti agbo-ẹran.
3
Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ẹbọ sisun ti inu ọwọ́-ẹran, ki on ki o mú akọ wá alailabùku: ki o mú u wá tinutinu rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ siwaju OLUWA.
4
Ki o si fi ọwọ rẹ̀ lé ori ẹbọ sisun na; yio si di itẹwọgbà fun u lati ṣètutu fun u.
5
Ki o si pa akọmalu na niwaju OLUWA: awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni, yio si mú ẹ̀jẹ na wá, nwọn o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká ti mbẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
6
Ki o si bó ẹbọ sisun na; ki o si kun u.
7
Awọn ọmọ Aaroni alufa ni yio si fi iná sori pẹpẹ na, nwọn o si tò igi lori iná na:
8
Awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si tò ninu rẹ̀, ani ori ati ọrá wọn sori igi ti mbẹ lori iná, ti mbẹ lori pẹpẹ:
9
Ṣugbọn ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀ ni ki o ṣàn ninu omi: ki alufa ki o si sun gbogbo rẹ̀ lori pẹpẹ na lati ṣe ẹbọ sisun, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
10
Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ti agbo-ẹran, eyinì ni ti agutan, tabi ti ewurẹ, fun ẹbọ sisun; akọ ni ki o múwa alailabùku.
11
Ki o si pa a niwaju OLUWA li ẹba pẹpẹ ni ìha ariwa: ati awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni yio si bù ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.
12
Ki o si kun u, ori rẹ̀ ati ọrá rẹ̀: alufa na yio si tò wọn sori igi ti mbẹ lori iná ti mbẹ lori pẹpẹ:
13
Ṣugbọn ki o ṣìn ifun ati itan rẹ̀ ninu omi: ki alufa na ki o si mú gbogbo rẹ̀ wá, ki o si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
14
Bi o ba si ṣepe ti ẹiyẹ ni ẹbọ sisun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ si OLUWA, njẹ ki o mú ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá ninu àdaba, tabi ninu ọmọ ẹiyẹle.
15
Ki alufa na ki o si mú u wá si pẹpẹ na, ki o si mi i li ọrùn, ki o si sun u lori pẹpẹ na; ẹ̀jẹ rẹ̀ ni ki o si ro si ẹba pẹpẹ na.
16
Ki o si fà ajẹsi rẹ̀ já pẹlu ẽri rẹ̀, ki o si kó o lọ si ẹba pẹpẹ na ni ìha ìlà-õrùn, lori ibi ẽru nì:
17
Ki o si là a ti on ti iyẹ́-apa rẹ̀, ṣugbọn ki yio pín i ni meji jalẹ: ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ na, lori igi na ti mbẹ lori iná: ẹbọ sisun ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27