bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Leviticus 3
Leviticus 3
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 4 →
1
BI ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ẹbọ alafia, bi o ba mú u lati inu ọwọ́-ẹran wá, on iba ṣe akọ tabi abo, ki o mú u wá siwaju OLUWA li ailabùku.
2
Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ: ki awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ nì yiká.
3
Ki o si mú ninu ẹbọ alafia nì wá, ọrẹ-ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun na.
4
Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ́ lara wọn, ti mbẹ li ẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
5
Ki awọn ọmọ Aaroni ki o si sun u lori pẹpẹ nì lori ẹbọ sisun, ti mbẹ lori igi ti o wà lori iná: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni, õrùn didùn si OLUWA.
6
Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ fun ọrẹ-ẹbọ alafia si OLUWA ba ṣe ti agbo-ẹran; akọ tabi abo, ki o mú u wá li ailabùku.
7
Bi o ba mu ọdọ-agutan wá fun ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:
8
Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori ọrẹ-ẹbọ rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.
9
Ki o si múwa ninu ẹbọ alafia nì, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá rẹ̀, ati gbogbo ìru rẹ̀ ti o lọrá, on ni ki o mú kuro sunmọ egungun ẹhin; ati ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti mbẹ lara ifun,
10
Ati iwe mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
11
Ki alufa ki o si sun u lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA ni.
12
Bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba si ṣe ewurẹ, njẹ ki o mú u wá siwaju OLUWA:
13
Ki o si fi ọwọ́ rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si pa a niwaju agọ́ ajọ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o si fi ẹ̀jẹ rẹ̀ wọ́n ori pẹpẹ na yiká.
14
Ki o si mú ninu ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ wá, ani ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA; ọrá ti o bò ifun lori, ati gbogbo ọrá ti o mbẹ lara ifun,
15
Ati iwe nì mejeji, ati ọrá ti mbẹ lara wọn, ti mbẹ lẹba ìha, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ, pẹlu iwe nì, on ni ki o mú kuro.
16
Ki alufa ki o si sun wọn lori pẹpẹ: onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe fun õrùn didùn ni: ti OLUWA ni gbogbo ọrá.
17
Ìlana titilai ni fun irandiran nyin, ni gbogbo ibugbé nyin, pe ki ẹnyin ki o máṣe jẹ ọrá tabi ẹ̀jẹ.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27