bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Leviticus 15
Leviticus 15
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 16 →
1
OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
2
Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnikan ba ní àrun isun lara rẹ̀, nitori isun rẹ̀ alaimọ́ li on.
3
Eyi ni yio si jẹ́ aimọ́ rẹ̀ ninu isun rẹ̀: ara rẹ̀ iba ma sun isun rẹ̀, tabi bi ara rẹ̀ si dá kuro ninu isun rẹ̀, aimọ́ rẹ̀ ni iṣe.
4
Gbogbo ori akete ti ẹniti o ní isun na ba dubulẹ lé, aimọ́ ni: ati gbogbo ohun ti o joko lé yio jẹ́ alaimọ́.
5
Ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀ ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
6
Ẹniti o si joko lé ohunkohun ti ẹniti o ní isun ti joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
7
Ẹniti o si farakàn ara ẹniti o ní isun, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
8
Bi ẹniti o ní isun ba tutọ sara ẹniti o mọ́; nigbana ni ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
9
Ati asákasá ti o wù ki ẹniti o ní isun ki o gùn ki o jẹ́ alaimọ́.
10
Ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o wà nisalẹ rẹ̀, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ: ati ẹniti o rù ohun kan ninu nkan wọnni, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
11
Ati ẹnikẹni ti ẹniti o ní isun ba farakàn, ti kò ti wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ ninu omi, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
12
Ati ohunèlo amọ̀, ti ẹniti o ní isun ba fọwọkàn, fifọ́ ni ki a fọ́ ọ: ati gbogbo ohunèlo igi ni ki a ṣàn ninu omi.
13
Nigbati ẹniti o ní isun ba si di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, fun isọdimimọ́ rẹ̀, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi ti nṣàn, yio si jẹ́ mimọ́.
14
Ati ni ijọ́ kẹjọ, ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si wá siwaju OLUWA si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si fi wọn fun alufa:
15
Ki alufa ki o si fi wọn rubọ, ọkan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji fun ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun rẹ̀.
16
Ati bi ohun irú ìdapọ ọkunrin ba ti ara rẹ̀ jade, nigbana ni ki o wẹ̀ gbogbo ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
17
Ati gbogbo aṣọ, ati gbogbo awọ, lara eyiti ohun irú ìdapọ ba wà, on ni ki a fi omi fọ̀, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
18
Ati obinrin na, ẹniti ọkunrin ba bá dàpọ ti on ti ohun irú ìdapọ, ki awọn mejeji ki o wẹ̀ ninu omi, ki nwọn ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
19
Bi obinrin kan ba si ní isun, ti isun rẹ̀ li ara rẹ̀ ba jasi ẹ̀jẹ, ki a yà a sapakan ni ijọ́ meje: ẹnikẹni ti o ba si farakàn a, ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
20
Ati ohun gbogbo ti o dubulẹ lé ninu ile ìyasapakan rẹ̀ yio jẹ́ aimọ́: ohunkohun pẹlu ti o joko lé yio jẹ́ aimọ́.
21
Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn akete rẹ̀, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
22
Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn ohun kan ti o joko lé, ki o fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
23
Bi o ba si ṣepe lara akete rẹ̀ ni, tabi lara ohun ti o joko lé, nigbati o ba farakàn a, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
24
Bi ọkunrin kan ba si bá a dàpọ rára, ti ohun obinrin rẹ̀ ba mbẹ lara ọkunrin na, ki on ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; ati gbogbo akete ti on dubulẹ lé ki o jẹ́ aimọ́.
25
Ati bi obinrin kan ba ní isun ẹ̀jẹ li ọjọ́ pupọ̀ le ìgba ìyasapakan rẹ̀; tabi bi o ba si sun rekọja ìgba ìyasapakan rẹ̀; gbogbo ọjọ́ isun aimọ́ rẹ̀ yio si ri bi ọjọ́ ìyasapakan rẹ̀: o jẹ́ alaimọ́.
26
Gbogbo akete ti o dubulẹ lé ni gbogbo ọjọ́ isun rẹ̀ ki o si jẹ́ fun u bi akete ìyasapakan rẹ̀: ati ohunkohun ti o joko lé ki o jẹ́ aimọ́, bi aimọ́ ìyasapakan rẹ̀.
27
Ati ẹnikẹni ti o ba farakàn nkan wọnni ki o jẹ́ alaimọ́, ki o si fọ̀ aṣọ rẹ̀, ki o si wẹ̀ ara rẹ̀ ninu omi, ki o si jẹ̀ alaimọ́ titi di aṣalẹ.
28
Ṣugbọn bi obinrin na ba di mimọ́ kuro ninu isun rẹ̀, nigbana ni ki o kà ijọ́ meje fun ara rẹ̀, lẹhin eyinì ni ki o si jẹ́ mimọ́.
29
Ati ni ijọ́ kẹjọ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji fun ara rẹ̀, ki o si mú wọn tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
30
Ki alufa ki o si ru ọkan li ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ekeji li ẹbọ sisun; ki alufa ki o si ṣètutu fun u niwaju OLUWA nitori isun aimọ́ rẹ̀.
31
Bayi ni ki ẹnyin ki o yà awọn ọmọ Israeli kuro ninu aimọ́ wọn; ki nwọn ki o má ba kú ninu aimọ́ wọn, nigbati nwọn ba sọ ibugbé mi ti mbẹ lãrin wọn di aimọ́.
32
Eyi li ofin ẹniti o ní isun, ati ti ẹniti ohun irú rẹ̀ jade lara rẹ̀, ti o si ti ipa rẹ̀ di alaimọ́;
33
Ati ti ẹniti o ri ohun obinrin rẹ̀, ati ti ẹniti o ní isun, ati ti ọkunrin, ati ti obinrin, ati ti ẹniti o ba bá ẹniti iṣe alaimọ́ dàpọ.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27