bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Leviticus 2
Leviticus 2
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 3 →
1
NIGBATI ẹnikan ba si nta ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ fun OLUWA, ki ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ki o jẹ ti iyẹfun daradara; ki o si dà oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀.
2
Ki o si mú u tọ̀ awọn alufa, awọn ọmọ Aaroni wá: ki alufa si bù ikunwọ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun na, ati ninu oróro na, pẹlu gbogbo turari rẹ̀; ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀ lori pẹpẹ, lati ṣe ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA:
3
Iyokù ti ẹbọ ohunjijẹ na, a si jẹ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ lati inu ẹbọ OLUWA ni ti a fi iná ṣe.
4
Bi iwọ ba si mú ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ wá, ti a yan ninu àro, ki o jẹ́ àkara alaiwu iyẹfun didara, ti a fi oróro pò, tabi àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si.
5
Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ ba ṣe ohunjijẹ, ti a ṣe ninu awopẹtẹ, ki o jẹ́ ti iyẹfun didara alaiwu, ti a fi òróró pò.
6
Ki iwọ ki o si dá a kelekele, ki o si dà oróro sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.
7
Ati bi ọrẹ-ẹbọ rẹ ba ṣe ẹbọ ohunjijẹ, ti a yan ninu apẹ, iyẹfun didara ni ki a fi ṣe e pẹlu oróro.
8
Ki iwọ ki o si mú ẹbọ ohunjijẹ na wá, ti a fi nkan wọnyi ṣe fun OLUWA: on o si mú u tọ̀ alufa na wá, ki on ki o si mú u wá sori pẹpẹ nì.
9
Alufa yio si mú ẹbọ-iranti ninu ohunjijẹ na, yio si sun u lori pẹpẹ: ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
10
Eyiti o si kù ninu ẹbọ ohunjijẹ, ki o jẹ́ ti Aaroni, ati ti awọn ọmọ rẹ̀: ohun mimọ́ julọ ni, ọrẹ-ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe.
11
A kò gbọdọ fi iwukàra ṣe gbogbo ẹbọ ohunjijẹ ti ẹnyin o mú tọ̀ OLUWA wá: nitori ẹnyin kò gbọdọ sun iwukàra, tabi: oyinkoyin, ninu ọrẹ-ẹbọ OLUWA, ti a fi iná ṣe.
12
Bi ọrẹ-ẹbọ akọ́so, ẹnyin le mú wọn wá fun OLUWA: ṣugbọn a ki yio sun wọn lori pẹpẹ fun õrùn didùn.
13
Ati gbogbo ọrẹ-ẹbọ ohunjijẹ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ dùn; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ jẹ ki iyọ̀ majẹmu Ọlọrun rẹ ki o má sí ninu ẹbọ ohunjijẹ rẹ: gbogbo ọrẹ-ẹbọ rẹ ni ki iwọ ki o fi iyọ̀ si.
14
Bi iwọ ba si mú ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ wá fun OLUWA, ki iwọ ki o si mú ṣiri ọkà daradara ti a yan lori iná wá fun ẹbọ ohunjijẹ akọ́so rẹ, ọkà gigún, ti ṣiri tutù.
15
Ki iwọ ki o si fi oróro sori rẹ̀, ki o si fi turari sori rẹ̀: ẹbọ ohunjijẹ ni.
16
Ki alufa ki o si sun ẹbọ-iranti rẹ̀, apakan ninu ọkà gigún rẹ̀, ati apakan ninu oróro rẹ̀, pẹlu gbogbo turari rẹ̀: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27