bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Leviticus 18
Leviticus 18
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 19 →
1
OLUWA si sọ fun Mose pe,
2
Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
3
Ẹnyin kò gbọdọ hùwa bi ìwa ilẹ Egipti nibiti ẹnyin ti ngbé: ẹnyin kò si gbọdọ hùwa ìwa ilẹ Kenaani, nibiti emi o mú nyin lọ: bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ rìn nipa ìlana wọn.
4
Ki ẹnyin ki o ma ṣe ofin mi, ki ẹnyin si ma pa ìlana mi mọ́, lati ma rìn ninu wọn: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
5
Ẹnyin o si ma pa ìlana mi mọ́, ati ofin mi: eyiti bi enia ba ṣe, on o ma yè ninu wọn: Emi li OLUWA.
6
Ẹnikẹni kò gbọdọ sunmọ ẹnikan ti iṣe ibatan rẹ̀ lati tú ìhoho rẹ̀: Emi li OLUWA.
7
Ihoho baba rẹ, tabi ìhoho iya rẹ̀, ni iwọ kò gbọdọ tú: iya rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
8
Ihoho aya baba rẹ ni iwọ kò gbọdọ tú: ìhoho baba rẹ ni.
9
Ihoho arabinrin rẹ, ọmọ baba rẹ, tabi ọmọ iya rẹ, ti a bi ni ile, tabi ti a bi li ode, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú.
10
Ìhoho ọmọbinrin ọmọ rẹ ọkunrin, tabi ti ọmọbinrin ọmọ rẹ obinrin, ani ìhoho wọn ni iwọ kò gbọdọ tú: nitoripe ìhoho ara rẹ ni nwọn.
11
Ìhoho ọmọbinrin aya baba rẹ, ti a bi lati inu baba rẹ wá, arabinrin rẹ ni, iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
12
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin baba rẹ: ibatan baba rẹ ni.
13
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arabinrin iya rẹ: nitoripe ibatan iya rẹ ni.
14
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho arakunrin baba rẹ, iwọ kò gbọdọ sunmọ aya rẹ̀: arabinrin baba rẹ ni.
15
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya ọmọ rẹ: nitoripe aya ọmọ rẹ ni iṣe; iwọ kò gbọdọ tú ìhoho rẹ̀.
16
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho aya arakunrin rẹ: ìhoho arakunrin rẹ ni.
17
Iwọ kò gbọdọ tú ìhoho obinrin ati ti ọmọbinrin rẹ̀; bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọbinrin ọmọ rẹ̀ obinrin, lati tú ìhoho wọn; nitoripe ibatan ni nwọn: ohun buburu ni.
18
Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ fẹ́ arabinrin aya rẹ li aya, lati bà a ninu jẹ́, lati tú ìhoho rẹ̀, pẹlu rẹ̀ nigbati o wà lãye.
19
Ati pẹlu iwọ kò gbọdọ sunmọ obinrin kan lati tú u ni ìhoho, ni ìwọn igbati a yà a sapakan nitori aimọ́ rẹ̀.
20
Pẹlupẹlu iwọ kò gbọdọ bá aya ẹnikeji rẹ dàpọ lati bà ara rẹ jẹ́ pẹlu rẹ̀.
21
Iwọ kò si gbọdọ fi irú-ọmọ rẹ kan fun Moleki, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bà orukọ Ọlọrun rẹ jẹ́: Emi li OLUWA.
22
Iwọ kò gbọdọ bá ọkunrin dápọ bi obinrin: irira ni.
23
Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bá ẹranko kan dàpọ, lati fi i bà ara rẹ jẹ́: bẹ̃ni obinrin kan kò gbọdọ duro niwaju ẹranko kan lati dubulẹ tì i: idaru-dàpọ ni.
24
Ẹ máṣe bà ara nyin jẹ́ ninu gbogbo nkan wọnyi: nitoripe ninu gbogbo nkan wọnyi li awọn orilẹ-ède, ti mo lé jade niwaju nyin dibajẹ́:
25
Ilẹ na si dibajẹ́: nitorina ni mo ṣe bẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wò lori rẹ̀, ilẹ tikararẹ̀ si bì awọn olugbé rẹ̀ jade.
26
Nitorina ni ki ẹnyin ki o ṣe ma pa ìlana ati ofin mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ṣe ọkan ninu irira wọnyi; tabi ẹnikan ninu ibilẹ nyin, tabi alejò ti nṣe atipo ninu nyin:
27
Nitoripe gbogbo irira wọnyi li awọn ọkunrin ilẹ na ṣe, ti o ti wà ṣaju nyin, ilẹ na si dibajẹ́;
28
Ki ilẹ na ki o má ba bì nyin jade pẹlu, nigbati ẹnyin ba bà a jẹ́, bi o ti bì awọn orilẹ-ède jade, ti o ti wà ṣaju nyin.
29
Nitoripe ẹnikẹni ti o ba ṣe ọkan ninu irira wọnyi, ani ọkàn wọnni ti o ba ṣe wọn li a o ke kuro lãrin awọn enia wọn.
30
Nitorina ni ki ẹnyin ki o pa aṣẹ mi mọ́, ki ẹnyin ki o máṣe ọkan ninu irira wọnyi, ti nwọn ti ṣe ṣaju nyin, ki ẹnyin ki o má si bà ara nyin jẹ́ ninu rẹ̀: Emi li OLUWA Ọlọrun nyin.
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 19 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27