bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Leviticus 6
Leviticus 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 7 →
1
OLUWA si sọ fun Mose pe,
2
Bi ẹnikan ba ṣẹ̀, ti o dẹ̀ṣẹ si OLUWA, ti o si sẹ́ fun ẹnikeji rẹ̀, li ohun ti o fi fun u pamọ́, tabi li ohun ti a fi dógo, tabi ohun ti a fi agbara gbà, tabi ti o rẹ ẹnikeji rẹ̀ jẹ;
3
Tabi ti o ri ohun ti o nù he, ti o si ṣeké nitori rẹ̀, ti o si bura eké; li ọkan ninu gbogbo ohun ti enia ṣe, ti o ṣẹ̀ ninu rẹ̀:
4
Yio si ṣe, bi o ba ti ṣẹ̀, ti o si jẹbi, ki o si mú ohun ti o fi agbara gbà pada, tabi ohun ti o fi irẹjẹ ní, tabi ohun ti a fi fun u pamọ́, tabi ohun ti o nù ti o rihe.
5
Tabi gbogbo eyi na nipa eyiti o bura eké; ki o tilẹ mú u pada li oju-owo rẹ̀, ki o si fi idamarun rẹ̀ lé ori rẹ̀, ki o si fi i fun olohun, li ọjọ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀.
6
Ki o si mú ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wá fun OLUWA, àgbo kan alailabùku lati inu agbo-ẹran tọ̀ alufa wá, ni idiyele rẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ:
7
Alufa yio si ṣètutu fun u niwaju OLUWA, a o si dari rẹ̀ jì; nitori ohunkohun ninu gbogbo ohun eyiti o ti ṣe ti o si jẹbi ninu rẹ̀.
8
OLUWA si sọ fun Mose pe,
9
Paṣẹ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ sisun: Ẹbọ sisun ni, nitori sisun rẹ̀ lori pẹpẹ ni gbogbo oru titi di owurọ̀, iná pẹpẹ na yio si ma jò ninu rẹ̀.
10
Ki alufa ki o si mú ẹ̀wu ọ̀gbọ rẹ̀ wọ̀, ati ṣòkoto ọ̀gbọ rẹ̀ nì ki o fi si ara rẹ̀, ki o si kó ẽru ti iná jọ, ti on ti ẹbọ sisun lori pẹpẹ, ki o si fi i si ìha pẹpẹ.
11
Ki o si bọ́ ẹ̀wu rẹ̀ silẹ, ki o si mú ẹ̀wu miran wọ̀, ki o si gbé ẽru wọnni jade lọ sẹhin ibudó si ibi kan ti o mọ́.
12
Ki iná ori pẹpẹ nì ki o si ma jó lori rẹ̀; ki a máṣe pa a; ki alufa ki o si ma kòná igi lori rẹ̀ li orowurọ̀, ki o si tò ẹbọ sisun sori rẹ̀; ki o si ma sun ọrá ẹbọ alafia lori rẹ̀.
13
Ki iná ki o ma jó titi lori pẹpẹ na; kò gbọdọ kú lai.
14
Eyi si li ofin ẹbọ ohunjijẹ: ki awọn ọmọ Aaroni ki o ru u niwaju OLUWA, niwaju pẹpẹ.
15
Ki o si bù ikunwọ rẹ̀ kan ninu rẹ̀, ninu iyẹfun didara ẹbọ ohunjijẹ na, ati ti oróro rẹ̀, ati gbogbo turari ti mbẹ lori ẹbọ ohunjijẹ, ki o si sun u lori pẹpẹ fun õrùn didùn, ani fun iranti rẹ̀, si OLUWA.
16
Iyokù rẹ̀ ni Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio jẹ: àkara alaiwu ni, ki a jẹ ẹ ni ibi mimọ́; ni agbalá agọ́ ajọ ni ki nwọn ki o jẹ ẹ.
17
Ki a máṣe fi iwukàra yan a. Mo ti fi i fun wọn ni ipín ti wọn ninu ẹbọ mi ti a fi iná ṣe; mimọ́ julọ ni, bi ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati bi ẹbọ ẹbi.
18
Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn ọmọ Aaroni ni ki o jẹ ninu rẹ̀, yio jasi aṣẹ titilai ni iraniran nyin, nipa ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: ẹnikẹni ti o ba kàn wọn yio di mimọ́.
19
OLUWA si sọ fun Mose pe,
20
Eyi li ọrẹ-ẹbọ Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, ti nwọn o ru si OLUWA, li ọjọ́ ti a fi oróro yàn a; idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun didara fun ẹbọ ohunjijẹ titilai, àbọ rẹ̀ li owurọ̀, ati àbọ rẹ̀ li alẹ.
21
Ninu awopẹtẹ ni ki a fi oróro ṣe e; nigbati a ba si bọ̀ ọ, ki iwọ ki o si mú u wọ̀ ile: ati ìṣu yiyan ẹbọ ohunjijẹ na ni ki iwọ ki o fi rubọ õrùn didùn si OLUWA.
22
Ati alufa ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti a fi oróro yàn ni ipò rẹ̀ ni ki o ru u: aṣẹ titilai ni fun OLUWA, sisun ni ki a sun u patapata.
23
Nitori gbogbo ẹbọ ohunjijẹ alufa, sisun ni ki a sun u patapata: a kò gbọdọ jẹ ẹ.
24
OLUWA si sọ fun Mose pe,
25
Sọ fun Aaroni ati fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Eyi li ofin ẹbọ ẹ̀ṣẹ: ni ibi ti a gbé pa ẹbọ sisun, ni ki a si pa ẹbọ ẹ̀ṣẹ niwaju OLUWA: mimọ́ julọ ni.
26
Alufa ti o ru u fun ẹ̀ṣẹ ni ki o jẹ ẹ: ni ibi mimọ́ kan ni ki a jẹ ẹ, ninu agbalá agọ́ ajọ.
27
Ohunkohun ti o ba kàn ẹran rẹ̀ yio di mimọ́: nigbati ẹ̀jẹ rẹ̀ ba si ta sara aṣọ kan, ki iwọ ki o si fọ̀ eyiti o ta si na ni ibi mimọ́ kan.
28
Ṣugbọn ohunèlo àmọ, ninu eyiti a gbé bọ̀ ọ on ni ki a fọ́; bi a ba si bọ̀ ọ ninu ìkoko idẹ, ki a si fọ̀ ọ, ki a si ṣìn i ninu omi.
29
Gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa ni ki o jẹ ninu rẹ̀: mimọ́ julọ ni.
30
Kò si sí ẹbọ ẹ̀ṣẹ kan, ẹ̀jẹ eyiti a múwa sinu agọ́ ajọ, lati fi ṣètutu ni ibi mimọ́, ti a gbọdọ jẹ: sisun ni ki a sun u ninu iná.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27