bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Ezekiel 13
Ezekiel 13
Yoruba 2010
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 14 →
1
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2
“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn wolii Israẹli. Sọ àsọtẹ́lẹ̀, kí o sì wí fún àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ara wọn pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA!’ ”
3
OLUWA Ọlọrun ní, “Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wolii tí wọn ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn láì jẹ́ pé wọ́n ríran rárá.
4
Israẹli, àwọn wolii rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láàrin òkítì àlàpà.
5
Wọn kò gun ibi tí odi ti lanu lọ, kí wọn tún un mọ yípo agbo ilé Israẹli, kí ó má baà wó lulẹ̀ lọ́jọ́ ìdájọ́ OLUWA.
6
Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.
7
Ǹjẹ́ ìran èké kọ́ ni wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́, nígbàkúùgbà tí wọn bá wí pé, ‘OLUWA wí báyìí’, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ̀rọ̀?”
8
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ, ati ìran èké tí ẹ̀ ń rí, mo lòdì si yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ.
9
N óo jẹ àwọn wolii tí wọn ń ríran èké níyà ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ irọ́. Wọn kò ní bá àwọn eniyan mi péjọ mọ́, tabi kí á kọ orúkọ wọn mọ́ ilé Israẹli, tabi kí wọ́n wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.
10
“Nítorí pé wọ́n ti ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà wọ́n ń wí fún wọn pé, ‘Alaafia’ nígbà tí kò sí alaafia. Ati pé nígbà tí àwọn eniyan mi ń mọ odi, àwọn wolii wọnyi ń kùn ún ní ọ̀dà funfun.
11
Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà.
12
Nígbà tí odi náà bá wó, ǹjẹ́ àwọn eniyan kò ní bi yín pé, ‘Ọ̀dà funfun tí ẹ fi ń kun ara rẹ̀ ńkọ́?’ ”
13
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fi ibinu mú kí ìjì líle jà, n óo fi ìrúnú rọ ọ̀wààrà òjò ńlá, n óo mú kí yìnyín ńláńlá bọ́ kí ó pa á run.
14
N óo wó ògiri tí ẹ kùn lẹ́fun, n óo wó o lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo hàn síta. Nígbà tí ó bá wó, ẹ óo ṣègbé ninu rẹ̀. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
15
“Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára odi náà ati àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun. N óo wí fun yín pé, odi kò sí mọ́, àwọn tí wọn ń kùn ún lẹ́fun náà kò sì sí mọ́;
16
àwọn wolii Israẹli tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jerusalẹmu tí wọn ń ríran alaafia nípa rẹ̀, nígbà tí kò sí alaafia. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun wí.”
17
OLUWA ní, “Ìwọ ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn ọmọbinrin àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ti ọkàn wọn. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn, kí o wí pé
18
èmi OLUWA Ọlọrun sọ pé, ‘Ègbé ni fún àwọn obinrin tí wọn ń so ẹ̀gbà òògùn mọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́, tí wọ́n sì ń ṣe ìbòjú fún gbogbo eniyan, kí ọwọ́ wọn lè ká eniyan. Ṣé ẹ̀ ń dọdẹ ẹ̀mí àwọn eniyan mi ni, kí ẹ lè dá àwọn ẹlòmíràn sí fún èrè ara yín?
19
Ẹ ti sọ mí di ẹni ìríra lójú àwọn eniyan mi nítorí ẹ̀kún ọwọ́ ọkà baali mélòó kan ati èérún burẹdi. Ẹ̀ ń pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì ń dá àwọn tí kò yẹ kí wọ́n wà láàyè sí, nípa irọ́ tí ẹ̀ ń pa fún àwọn eniyan mi, tí wọn ń fetí sí irọ́ yín.’
20
“Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, ‘Mo kórìíra àwọn ẹ̀gbà ọwọ́, òògùn tí ẹ fi ń dọdẹ ẹ̀mí eniyan. N óo já wọn kúrò lápá yín, n óo sì tú àwọn ẹ̀mí tí ẹ dè sílẹ̀ bí ẹyẹ.
21
N óo ya ìbòjú yín kúrò, n óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín. Wọn kò ní jẹ́ ohun ọdẹ lọ́wọ́ yín mọ́, ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’
22
“Nítorí pé ẹ̀ ń fi àrékérekè ba àwọn olódodo lọ́kàn jẹ́, nígbà tí n kò fẹ́ bà wọ́n lọ́kàn jẹ́; ẹ sì ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn eniyan burúkú kí wọn má baà yipada lọ́nà ibi wọn, kí wọn sì rí ìgbàlà.
23
Nítorí náà, ẹ kò ní ríran èké mọ́, ẹ kò sì ní woṣẹ́ mọ́. N óo gba àwọn eniyan mi lọ́wọ́ yín, nígbà náà, ni ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48