bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Ezekiel 42
Ezekiel 42
Yoruba 2010
← Chapter 41
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 43 →
1
Lẹ́yìn náà ó mú mi jáde, ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn ti inú lápá ìhà àríwá, ó sì mú mi wọ inú àwọn yàrá tí ó wà níwájú àgbàlá Tẹmpili, ati níwájú ilé tí ó wà ní ìhà àríwá.
2
Òòró ilé tí ó wà ní ìhà àríwá náà jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ aadọta igbọnwọ (mita 25).
3
Ibùjókòó-òkè meji tí ó kọjú sí ara wọn wà ní àgbékà mẹtẹẹta; wọ́n wà lára ògiri láti nǹkan bíi ogún igbọnwọ sí ara gbọ̀ngàn inú, ati ibi tí ó kọjú sí pèpéle tí ó wà lára gbọ̀ngàn òde.
4
Ọ̀nà kan wà níwájú àwọn yàrá tí ó lọ sinu, ó fẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá (mita 5), ó sì gùn ní ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50), àwọn ìlẹ̀kùn rẹ̀ wà ní ìhà àríwá.
5
Àwọn yàrá ti àgbékà kẹta kéré, nítorí ibùjókòó-òkè ti àgbékà kẹta fẹ̀ ju àwọn tí wọ́n wà níwájú àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti àgbékà ààrin lọ.
6
Àgbékà mẹta ni àwọn yàrá náà, ọgbọ̀n yàrá ni ó wà lára ògiri ní àjà kọ̀ọ̀kan, wọn kò sì ní òpó bíi ti gbọ̀ngàn ìta, nítorí náà ni wọ́n ṣe sún àwọn yàrá àgbékà òkè kẹta sinu ju ti àwọn yàrá àgbékà kinni ati ti ààrin lọ.
7
Ògiri kan wà ní ìta tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ àwọn yàrá ní apá ti gbọ̀ngàn ìta, ó wà níwájú àwọn yàrá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, (mita 25).
8
Àwọn yàrá ti gbọ̀ngàn ìta gùn ní aadọta igbọnwọ (mita 25), ṣugbọn àwọn tí wọ́n wà níwájú tẹmpili jẹ́ ọgọrun-un (100) igbọnwọ (mita 50).
9
Nísàlẹ̀ àwọn yàrá wọnyi, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn bí eniyan bá ti ń bọ̀ láti ibi gbọ̀ngàn ìta.
10
Bákan náà, àwọn yàrá kan wà ní ìhà gúsù, lára ògiri òòró àgbàlá ti ìta, wọ́n fara kan àgbàlá tẹmpili,
11
ọ̀nà wà níwájú wọn. Wọ́n rí bí àwọn yàrá ti ìhà àríwá, òòró ati ìbú wọn rí bákan náà. Bákan náà ni ẹnu ọ̀nà wọn rí, ati ìlẹ̀kùn wọn.
12
Nísàlẹ̀ àwọn yàrá ìhà gúsù, ọ̀nà kan wà ní apá ìlà oòrùn. Bí eniyan bá wọ àlàfo náà, ògiri kan dábùú rẹ̀ níwájú.
13
Lẹ́yìn náà, ọkunrin náà wí fún mi pé, “Àwọn yàrá ẹ̀gbẹ́ ìhà àríwá ati àwọn yàrá ìhà gúsù tí wọ́n kọjú sí àgbàlá ni àwọn yàrá mímọ́. Níbẹ̀ ni àwọn alufaa tí ń rú ẹbọ sí OLUWA yóo ti máa jẹ ẹbọ mímọ́ jùlọ. Níbẹ̀ ni wọn yóo máa kó àwọn ẹbọ mímọ́ jùlọ sí; ati àwọn ẹbọ ohun jíjẹ, ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, nítorí ibẹ̀ jẹ́ ibi mímọ́.
14
Nígbà tí àwọn alufaa bá wọ ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ jáde sí gbọ̀ngàn ìta láìbọ́ aṣọ tí wọ́n lò sinu yàrá wọnyi, nítorí pé aṣọ mímọ́ ni wọ́n. Wọ́n gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọ́n tó súnmọ́ àwọn ohun tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan.”
15
Nígbà tí ó ti parí wíwọn inú Tẹmpili, ó mú mi gba ẹnu ọ̀nà tí ó kọjú sí ìlà oòrùn jáde, ó sì wọn ẹ̀yìn Tẹmpili yíká.
16
Ó wọn apá ìlà oòrùn pẹlu ọ̀pá rẹ̀, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.
17
Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà àríwá, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.
18
Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn ìhà gúsù, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.
19
Lẹ́yìn náà, ó yipada, ó wọn apá ìwọ̀ oòrùn, ó jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), gẹ́gẹ́ bí ọ̀pá rẹ̀.
20
Ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin ni ó wọ̀n. Tẹmpili náà ní ògiri yíká, òòró rẹ̀ jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ẹẹdẹgbẹta (500) igbọnwọ (mita 250), èyí ni ó jẹ́ ààlà láàrin ibi mímọ́ ati ibi tí ó jẹ́ ti gbogbo eniyan.
← Chapter 41
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 43 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48