bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Ezekiel 31
Ezekiel 31
Yoruba 2010
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 32 →
1
Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹta, ọdún kọkanla tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
2
“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún Farao, ọba Ijipti, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé, Ta ni ó lágbára tó ọ?
3
Wò ó! Mo fi ọ́ wé igi kedari Lẹbanoni, àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lẹ́wà, wọ́n sì ní ìbòòji ó ga fíofío, orí rẹ̀ sì kan ìkùukùu lójú ọ̀run.
4
Omi mú kí ó dàgbà, ibú omi sì mú kí ó ga. Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká. Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó.
5
Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn, nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí.
6
Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí. Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé.
7
Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wà nítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ, ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀.
8
Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀. Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀.
9
Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀. Gbogbo igi ọgbà Edẹni, tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀.
10
“Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀.
11
N óo fi lé ẹni tí ó lágbára jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, yóo sì ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo lé e jáde.
12
Àwọn àjèjì láti inú orílẹ̀-èdè, tí ó burú jùlọ, yóo gé e lulẹ̀, wọn yóo sì fi í sílẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo bọ́ sílẹ̀ lórí àwọn òkè ati ní àwọn àfonífojì, igi rẹ̀ yóo sì wà nílẹ̀ káàkiri ní gbogbo ipadò ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo kúrò lábẹ́ òjìji rẹ̀, wọn yóo sì fi sílẹ̀.
13
Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run yóo kọ́lé sórí ìtì igi rẹ̀ tí ó wó lulẹ̀. Gbogbo ẹranko inú igbó yóo tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ mọ́lẹ̀.
14
Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.”
15
OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀.
16
Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù.
17
Àwọn náà yóo lọ sí ipò òkú pẹlu rẹ̀, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń gbé abẹ́ òjìji rẹ̀ yóo sì parun.
18
“Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà, pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 32 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48