bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Ezekiel 6
Ezekiel 6
Yoruba 2010
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 7 →
1
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2
“Ọmọ eniyan, dojú kọ àwọn òkè Israẹli kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí wọn.
3
Sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Israẹli, ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun wí. OLUWA Ọlọrun ń bá àwọn òkè ńláńlá ati àwọn òkè kéékèèké wí! Ó ń sọ fún àwọn ọ̀gbun ati àwọn àfonífojì pé, èmi fúnra mi ni n óo kó ogun wá ba yín, n óo sì pa àwọn ibi ìrúbọ yín run.
4
Àwọn pẹpẹ ìrúbọ yín yóo di ahoro, a óo fọ́ àwọn pẹpẹ turari yín, n óo sì da òkú yín sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín.
5
N óo da òkú ẹ̀yin ọmọ Israẹli sílẹ̀ níwájú àwọn oriṣa yín, n óo sì fọ́n egungun yín ká níbi pẹpẹ ìrúbọ yín.
6
Ní ibikíbi tí ẹ bá ń gbé, àwọn ìlú yín yóo di ahoro, àwọn ibi ìrúbọ yín yóo di òkítì àlàpà, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn pẹpẹ oriṣa yín yóo di ahoro ati àlàpà. A óo fọ́ àwọn ère oriṣa yín, a óo pa wọ́n run, a óo wó pẹpẹ turari yín, iṣẹ́ yín yóo sì parẹ́.
7
Òkú yóo sùn lọ bẹẹrẹ láàrin yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
8
“ ‘Sibẹsibẹ n óo dá díẹ̀ sí ninu yín; kí ẹ lè ní àwọn tí yóo bọ́ lọ́wọ́ ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nígbà tí ẹ bá fọ́n káàkiri ilé ayé.
9
Nígbà náà, àwọn tí wọ́n sá àsálà ninu yín yóo ranti mi láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a bá kó wọn ní ìgbèkùn lọ, nígbà tí mo bá mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn tí ó ń mú wọn kọ̀ mí sílẹ̀ kúrò, tí mo bá sì fọ́ ojú tí wọ́n fi ń ṣe àgbèrè tẹ̀lé àwọn oriṣa wọn. Ojú ara wọn yóo tì wọ́n nítorí ibi tí wọ́n ṣe, ati nítorí gbogbo ìwà ìríra wọn.
10
Wọn yóo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA, ati pé kì í ṣe pé mo sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ẹnu lásán pé n óo ṣe wọ́n níbi.’ ”
11
OLUWA Ọlọrun ní: “Ẹ káwọ́ lérí kí ẹ máa fi ẹsẹ̀ janlẹ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Háà! Ó mà ṣe o!’ Ogun ati ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa ilé Israẹli nítorí ìwà ìríra wọn.
12
Àjàkálẹ̀-àrùn ni yóo pa àwọn tí wọ́n wà lókèèrè; idà yóo pa àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ìyàn yóo sì pa àwọn yòókù tí ogun ati àjàkálẹ̀-àrùn bá dá sí. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe tẹ́ ibinu mi lọ́rùn lára wọn patapata.
13
Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA nígbà tí òkú wọn bá sùn lọ káàkiri láàrin àwọn ère oriṣa wọn yíká pẹpẹ ìrúbọ wọn, ní gbogbo ibi ìrúbọ ati lórí gbogbo òkè ńlá, lábẹ́ gbogbo igi tútù ati gbogbo igi oaku eléwé tútù; ní gbogbo ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ olóòórùn dídùn sí àwọn oriṣa wọn.
14
Ọwọ́ mi óo tẹ̀ wọ́n; n óo sọ ilẹ̀ wọn di ahoro ati òkítì àlàpà, ní gbogbo ibùgbé wọn, láti ibi aṣálẹ̀ títí dé Ribila. Wọn óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48