bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Ezekiel 7
Ezekiel 7
Yoruba 2010
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 8 →
1
OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:
2
“Ìwọ ọmọ eniyan, ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun sọ nípa ilẹ̀ Israẹli ni pé: òpin ti dé. Òpin dé sórí igun mẹrẹẹrin ilẹ̀ náà.
3
“Òpin ti dé ba yín báyìí, n óo bínú si yín, n óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín; n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín.
4
N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò sì ní ṣàánú yín. Ṣugbọn n óo jẹ yín níyà fún gbogbo ìwà yín níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi ni OLUWA.”
5
OLUWA Ọlọrun ní: “Àjálù dé! Ẹ wò ó! Àjálù ń ré lu àjálù.
6
Òpin dé! Òpin ti dé; ó ti dé ba yín.
7
Ẹ wò ó! Ó ti dé. Ìparun ti dé ba yín, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ yìí. Àkókò tó, ọjọ́ ti súnmọ́lé, ọjọ́ ìdàrúdàpọ̀, tí kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí àwọn òkè.
8
“Ó yá tí n óo bínú si yín, tí inú mi óo ru si yín gidi. N óo da yín lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, n óo sì jẹ yín níyà nítorí gbogbo ìwà ìríra yín.
9
N kò ní fojú fo ọ̀rọ̀ yín, n kò ní ṣàánú yín. N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà yín, níwọ̀n ìgbà tí ohun ìríra ṣì wà láàrin yín. Ẹ óo wá mọ̀ nígbà náà pé èmi OLUWA, ni mò ń jẹ yín níyà.”
10
Ọjọ́ pé. Ẹ wò ó! Ọjọ́ ti pé! Ìparun yín ti dé. Ìwà àìṣẹ̀tọ́ ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìgbéraga ń rúwé.
11
Ìwà ipá hù, ó dàgbà, ó di ọ̀pá ìwà ibi; bí ẹ ti pọ̀ tó, ẹ kò ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan, àtẹ̀yin ati àwọn ohun ìní yín, ati ọrọ̀ yín ati ògo yín.
12
Àkókò tó; ọjọ́ náà sì ti dé tán, kí ẹni tí ń ra nǹkan má ṣe yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ń tà má sì banújẹ́, nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn.
13
Ẹni tí ń tà kò ní sí láyé láti pada síbi ohun tí ó tà ní ìgbà ayé ẹni tí ó rà á. Nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Kò sì ní yipada, bẹ́ẹ̀ ni nítorí ẹ̀ṣẹ̀ olukuluku, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní sí láàyè.
14
Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn.
15
Ogun ń bẹ lóde; àjàkálẹ̀-àrùn ati ìyàn wà ninu ilé. Ẹni tí ó bá wà lóko yóo kú ikú ogun. Ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn yóo pa ẹni tí ó bá wà ninu ìlú.
16
Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
17
Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára.
18
Wọn óo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ìpayà óo sì bá wọn. Ojú óo ti gbogbo wọn; gbogbo wọn óo sì di apárí.
19
Wọ́n óo fọ́n fadaka wọn dà sílẹ̀ láàrin ìgboro. Wúrà wọn yóo sì dàbí ohun àìmọ́. Fadaka ati wúrà wọn kò ní lè gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́jọ́ ibinu OLUWA. Kò ní lè tẹ́ ọkàn wọn lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní lè jẹ ẹ́ yó. Nítorí pé wúrà ati fadaka ló mú wọn dẹ́ṣẹ̀.
20
Wọ́n ń lo ohun ọ̀ṣọ́ wọn dáradára fún ògo asán; òun ni wọ́n fi ń ṣe àwọn ère ati oriṣa wọn, àwọn ohun ìríra tí wọn ń bọ. Nítorí náà, OLUWA óo sọ wọ́n di ohun àìmọ́ fún wọn.
21
OLUWA ní, “N óo sọ wọ́n di ìjẹ fún àwọn àjèjì, n óo sì fi wọ́n ṣe ìkógun fún àwọn eniyan burúkú ilé ayé. Wọn óo sọ wọ́n di ohun eléèérí.
22
N óo mójú kúrò lọ́dọ̀ wọn, kí wọ́n lè sọ ibi dídára mi di eléèérí. Àwọn ọlọ́ṣà yóo wọnú rẹ̀, wọn yóo sì sọ ọ́ di eléèérí.
23
“Nítorí pé ìpànìyàn kún ilẹ̀ náà, ìlú wọn sì kún fún ìwà ipá.
24
N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí.
25
Nígbà tí ìrora bá dé, wọn yóo máa wá alaafia, ṣugbọn wọn kò ní rí i.
26
Àjálù yóo máa yí lu àjálù, ọ̀rọ̀ àhesọ yóo máa gorí ara wọn. Wọn yóo máa wo ojú wolii fún ìran ṣugbọn kò ní sí, alufaa kò ní náání òfin mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ìmọ̀ràn mọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àgbààgbà.
27
Ọba yóo máa ṣọ̀fọ̀; àwọn olórí yóo sì wà ninu ìdààmú; ọwọ́ àwọn eniyan yóo sì máa gbọ̀n nítorí ìpayà. N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn fún wọn; n óo sì dá wọn lẹ́jọ́ bí àwọn náà tí ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Wọn óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48