bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Ezekiel 8
Ezekiel 8
Yoruba 2010
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 9 →
1
Ní ọjọ́ karun-un, oṣù kẹfa ọdún kẹfa tí a ti wà ní ìgbèkùn, bí mo ti jókòó ninu ilé mi, tí àwọn àgbààgbà Juda sì jókòó níwájú mi, agbára OLUWA Ọlọrun bà lé mi níbẹ̀.
2
Nígbà tí mo wò, mo rí nǹkankan tí ó dàbí eniyan. Láti ibi tí ó dàbí ìbàdí rẹ̀ dé ilẹ̀ jẹ́ iná, ibi ìbàdí rẹ̀ sókè ń kọ mànàmànà bí idẹ dídán.
3
Ó na nǹkankan tí ó dàbí ọwọ́, ó fi gbá ìdí irun orí mi mú, ẹ̀mí sì gbé mi sókè sí agbede meji ọ̀run ati ayé, ó gbé mi lọ sí Jerusalẹmu, ninu ìran Ọlọrun, ó gbé mi sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá gbọ̀ngàn ti inú tí ó kọjú sí ìhà àríwá, níbi tí wọ́n gbé ère tí ń múni jowú sí.
4
Mo rí ìfarahàn ògo Ọlọrun Israẹli níbẹ̀ bí mo ti rí i lákọ̀ọ́kọ́ ní àfonífojì.
5
Ó bá sọ fún mi, pé: “Ọmọ eniyan, gbójú sókè sí apá àríwá.” Mo bá gbójú sókè sí apá àríwá. Wò ó! Mo rí ère kan tí ń múni jowú ní ìhà àríwá ẹnu ọ̀nà pẹpẹ ìrúbọ.
6
OLUWA sọ fún mi pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe? Ṣé o rí nǹkan ìríra ńlá tí àwọn ọmọ Israẹli ń ṣe níhìn-ín láti lé mi jìnnà sí ilé mímọ́ mi? N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn hàn ọ́.”
7
OLUWA bá tún gbé mi lọ sí ẹnu ọ̀nà gbọ̀ngàn, nígbà tí mo wò yíká, mo rí ihò kan lára ògiri.
8
Ó bá sọ fún mi pé, “Ọmọ eniyan, gbẹ́ ara ògiri yìí.” Nígbà tí mo gbẹ́ ara ògiri náà, mo rí ìlẹ̀kùn kan!
9
Ó bá sọ fún mi pé, “Wọlé kí o rí nǹkan ìríra tí wọn ń ṣe níbẹ̀.”
10
Mo bá wọlé láti wo ohun tí ó wà níbẹ̀. Mo rí àwòrán oríṣìíríṣìí kòkòrò ati ti ẹranko, tí ń rí ni lára, ati gbogbo oriṣa àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n yà sí ara ògiri yíká.
11
Mo sì rí aadọrin ninu àwọn àgbààgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n dúró níwájú àwọn oriṣa wọnyi, Jaasanaya ọmọ Ṣafani dúró láàrin wọn. Olukuluku mú ohun tí ó fi ń sun turari lọ́wọ́, èéfín turari sì ń fẹ́ lọ sókè.
12
OLUWA tún bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí àwọn àgbààgbà ilé Israẹli ń ṣe ninu òkùnkùn? Ṣé o rí ohun tí olukuluku ń ṣe ninu yàrá tí ó kún fún àwòrán ère oriṣa? Wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA kò rí wa, ó ti kọ ilẹ̀ wa sílẹ̀.’ ”
13
Ó tún sọ fún mi pé, “N óo fi nǹkan ìríra ńlá mìíràn tí ó jù báyìí lọ tí wọn ń ṣe hàn ọ́.”
14
Nígbà náà ni ó mú mi lọ sí ẹnu ọ̀nà tí ó wà ní ìhà àríwá ilé OLUWA. Wò ó, mo rí àwọn obinrin kan níbẹ̀, tí wọ́n jókòó, tí wọn ń sunkún nítorí Tamusi.
15
Ó sì bi mí pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, ǹjẹ́ o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? O óo tún rí nǹkan ìríra tí ó ju èyí lọ.”
16
Ó mú mi wọ inú gbọ̀ngàn tí ó wà ninu ilé OLUWA; mo bá rí àwọn ọkunrin mẹẹdọgbọn kan, wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà tẹmpili ilé OLUWA, láàrin ìloro ati pẹpẹ. Wọ́n kẹ̀yìn sí tẹmpili OLUWA, wọ́n sì kọjú sí ìlà oòrùn. Wọ́n ń foríbalẹ̀ wọ́n ń bọ oòrùn.
17
Ó bi mí pé: “Ọmọ eniyan, ṣé o rí ohun tí wọn ń ṣe yìí? Ṣé nǹkan ìríra tí àwọn ọmọ ilé Juda ń ṣe níhìn-ín kò jọ wọ́n lójú ni wọ́n ṣe mú kí ìwà ìkà kún ilẹ̀ yìí, tí wọn ń mú mi bínú sí i? Wò bí wọ́n ti ń tàbùkù mi, tí wọn ń fín mi níràn.
18
Nítorí náà, n óo bínú sí wọn, n kò ní fojú fo iṣẹ́ wọn, n kò sì ní ṣàánú wọn. Wọ́n ìbáà máa kígbe sí mi létí, n kò ní dá wọn lóhùn.”
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48