bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 19
Deuteronomy 19
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 20 →
1
NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro, ilẹ ẹniti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilu wọn, ati ni ile wọn;
2
Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ lãrin ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.
3
Ki iwọ ki o là ọ̀na kan fun ara rẹ, ki iwọ ki o si pín àgbegbe ilẹ rẹ si ipa mẹta, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní, ki gbogbo apania ki o ma sá sibẹ̀.
4
Eyi si ni ọ̀ran apania, ti yio ma sá sibẹ̀, ki o le yè: ẹnikẹni ti o ba ṣeṣi pa ẹnikeji rẹ̀, ti on kò korira rẹ̀ tẹlẹrí;
5
Bi nigbati enia ba wọ̀ inu igbó lọ pélu ẹnikeji rẹ̀ lati ke igi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ gbé ãke lati fi ke igi na lulẹ, ti ãke si yọ kuro ninu erú, ti o si bà ẹnikeji rẹ̀, ti on kú; ki o salọ si ọkan ninu ilu wọnni, ki o si yè:
6
Ki agbẹsan ẹ̀jẹ ki o má ba lepa apania na, nigbati ọkàn rẹ̀ gboná, ki o si lé e bá, nitoriti ọ̀na na jìn, a si pa a; nigbati o jẹ pe kò yẹ lati kú, niwọnbi on kò ti korira rẹ̀ tẹlẹrí.
7
Nitorina emi fi aṣẹ fun ọ, wipe, Ki iwọ ki o yà ilu mẹta sọ̀tọ fun ara rẹ.
8
Ati bi OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, ti on ti bura fun awọn baba rẹ, ti o sì fun ọ ni gbogbo ilẹ na, ti o si ṣe ileri fun awọn baba rẹ;
9
Bi iwọ ba pa gbogbo ofin yi mọ́ lati ma ṣe e, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni, lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, ati lati ma rìn titi li ọ̀na rẹ̀; nigbana ni ki iwọ ki o fi ilu mẹta kún u si i fun ara rẹ, pẹlu mẹta wọnyi;
10
Ki a má ba tà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ ninu ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki ẹ̀jẹ ki o má ba wà li ọrùn rẹ.
11
Ṣugbọn bi ọkunrin kan ba korira ẹnikeji rẹ̀, ti o si ba dè e, ti o si dide si i, ti o si lù u li alupa, ti o si kú, ti on si salọ sinu ọkan ninu ilu wọnyi:
12
Njẹ ki awọn àgba ilu rẹ̀ ki o ránni ki nwọn ki o si mú u ti ibẹ̀ wá, ki nwọn ki o si fà a lé agbẹsan ẹ̀jẹ lọwọ ki o ba le kú.
13
Ki oju rẹ ki o máṣe ṣãnu fun u, ṣugbọn ki iwọ ki o mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lori Israeli, ki o si le dara fun ọ.
14
Iwọ kò gbọdọ yẹ̀ àla ẹnikeji rẹ, ti awọn ara iṣaju ti pa ni ilẹ iní rẹ ti iwọ o ní, ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati ní.
15
Ki ẹlẹri kanṣoṣo ki o máṣe dide jẹri tì enia nitori aiṣedede kan, tabi nitori ẹ̀ṣẹ kan ninu ẹ̀ṣẹ ti o ba ṣẹ̀: li ẹnu ẹlẹri meji, tabi li ẹnu ẹlẹri mẹta, li ọ̀ran yio fẹsẹmulẹ.
16
Bi ẹlẹri eké ba dide si ọkunrin lati jẹri tì i li ohun ti kò tọ́:
17
Njẹ ki awọn ọkunrin mejeji na lãrin ẹniti ọ̀rọ iyàn na gbé wà, ki o duro niwaju OLUWA, niwaju awọn alufa ati awọn onidajọ, ti yio wà li ọjọ wọnni,
18
Ki awọn onidajọ na ki o si tọ̀sẹ rẹ̀ pẹlẹpẹlẹ: si kiyesi i bi ẹlẹri na ba ṣe ẹlẹri eké, ti o si jẹri-eké si arakunrin rẹ̀;
19
Njẹ ki ẹnyin ki o ṣe si i, bi on ti rò lati ṣe si arakunrin rẹ̀: bẹ̃ni iwọ o si mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
20
Awọn ti o kù yio si gbọ́, nwọn o si bẹ̀ru, nwọn ki o si tun hù irú ìwa-buburu bẹ̃ mọ́ lãrin nyin.
21
Ki oju rẹ ki o má si ṣe ṣãnu; ẹmi fun ẹmi, oju fun oju, ehín fun ehín, ọwọ́ fun ọwọ́, ẹsẹ̀ fun ẹsẹ̀.
← Chapter 18
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 20 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34