bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 8
Deuteronomy 8
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 9 →
1
GBOGBO ofin ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati ṣe, ki ẹnyin ki o le yè, ki ẹnyin si ma pọ̀ si i, ki ẹnyin si wọnu rẹ̀ lọ lati gbà ilẹ na ti OLUWA ti bura fun awọn baba nyin.
2
Ki iwọ ki o si ranti ọ̀na gbogbo ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti mu ọ rìn li aginjù lati ogoji ọdún yi wá, lati rẹ̀ ọ silẹ, ati lati dan ọ wò, lati mọ̀ ohun ti o wà li àiya rẹ, bi iwọ o pa ofin rẹ̀ mọ́, bi bẹ̃kọ.
3
O si rẹ̀ ọ silẹ, o si fi ebi pa ọ, o si fi manna bọ́ ọ, ti iwọ kò mọ̀, bẹ̃ni awọn baba rẹ kò mọ̀; ki o le mu ọ mọ̀ pe enia kò ti ipa onjẹ nikan wà lãye, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu OLUWA jade li enia wà lãye.
4
Aṣọ rẹ kò gbó mọ́ ọ lara, bẹ̃li ẹsẹ̀ rẹ kò wú, lati ogoji ọdún yi wá.
5
Ki iwọ ki o si mọ̀ li ọkàn rẹ pe, bi enia ti ibá ọmọ rẹ̀ wi, bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ wi.
6
Ki iwọ ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun rẹ mọ́, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma bẹ̀ru rẹ̀.
7
Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ mú ọ wá sinu ilẹ rere, ilẹ odò omi, ti orisun ati ti abẹ-ilẹ, ti nrú soke lati afonifoji ati òke jade wa;
8
Ilẹ alikama ati ọkà-barle, ati àjara ati igi ọpọtọ ati igi pomegranate; ilẹ oróro olifi, ati oyin;
9
Ilẹ ninu eyiti iwọ ki o fi ìṣẹ jẹ onjẹ, iwọ ki yio fẹ ohun kan kù ninu rẹ̀; ilẹ ti okuta rẹ̀ iṣe irin, ati lati inu òke eyiti iwọ o ma wà idẹ.
10
Nigbati iwọ ba si jẹun tán ti o si yo, nigbana ni iwọ o fi ibukún fun OLUWA Ọlọrun rẹ, nitori ilẹ rere na ti o fi fun ọ.
11
Ma kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ṣe gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, li aipa ofin rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti mo filelẹ li aṣẹ fun ọ li oni:
12
Ki iwọ ki o má ba jẹ yó tán, ki o kọ ile daradara, ki o si ma gbé inu rẹ̀;
13
Ati ki ọwọ́-ẹran rẹ ati agbo-ẹran rẹ, ki o ma ba pọ̀si i tán, ki fadakà rẹ ati wurà rẹ pọ̀si i, ati ki ohun gbogbo ti iwọ ní pọ̀si i;
14
Nigbana ni ki ọkàn rẹ wa gbé soke, iwọ a si gbagbé OLUWA Ọlọrun rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú;
15
Ẹniti o mu ọ rìn aginjù nla ti o si li ẹ̀ru, nibiti ejò amubina wà, ati akẽkẽ, ati ọdá, nibiti omi kò sí; ẹniti o mú omi jade fun ọ lati inu okuta akọ wá;
16
Ẹniti o fi manna bọ́ ọ li aginjù, ti awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; ki o le rẹ̀ ọ silẹ, ki o le dan ọ wò, lati ṣe ọ li ore nigbẹhin rẹ:
17
Iwọ a si wi li ọkàn rẹ pe, Agbara mi ati ipa ọwọ́ mi li o fun mi li ọrọ̀ yi.
18
Ṣugbọn ki iwọ ki o ranti OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe, on li o fun ọ li agbara lati lí ọrọ̀, ki on ki o le fi idi majẹmu rẹ̀ ti o bura fun awọn baba rẹ kalẹ, bi o ti ri li oni yi.
19
Yio si ṣe, bi iwọ ba gbagbe OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ si tẹle ọlọrun miran, ti o si nsìn wọn, ti o si mbọ wọn, emi tẹnumọ́ ọ fun nyin pe, rirun li ẹnyin o run.
20
Bi awọn orilẹ-ède ti OLUWA run kuro niwaju nyin, bẹ̃li ẹnyin o run; nitoripe ẹnyin ṣe àigbọran si ohùn OLUWA Ọlọrun nyin.
← Chapter 7
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 9 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34