bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 20
Deuteronomy 20
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 21 →
1
NIGBATI iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti iwọ si ri ẹṣin, ati kẹkẹ́-ogun, ati awọn enia ti o pọ̀ jù ọ, máṣe bẹ̀ru wọn: nitori OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ, ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá.
2
Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba sunmọ ogun na, ki alufa ki o sunmọtosi, ki o si sọ̀rọ fun awọn enia.
3
Ki o si wi fun wọn pe, Gbọ́, Israeli, li oni ẹnyin sunmọ ogun si awọn ọtá nyin: ẹ máṣe jẹ ki àiya nyin ki o ṣojo, ẹ máṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe warìri, bẹ̃ni ẹ má si ṣe fòya nitori wọn;
4
Nitoripe OLUWA Ọlọrun nyin ni mbá nyin lọ, lati bá awọn ọtá nyin jà fun nyin, lati gbà nyin là.
5
Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia, pe, Ọkunrin wo li o kọ ile titun, ti kò ti ikó si i? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba kó si i.
6
Ati ọkunrin wo li o gbìn ọgbà-àjara, ti kò si ti ijẹ ninu rẹ̀? jẹ ki on pẹlu ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba jẹ ẹ.
7
Ati ọkunrin wo li o fẹ́ iyawo, ti kò ti igbé e? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki on ki o má ba kú li ogun na, ki ọkunrin miran ki o má ba gbé e.
8
Ki awọn olori-ogun ki o si sọ fun awọn enia na si i, ki nwọn ki o si wipe, Ọkunrin wo li o wà ti o bẹ̀ru ti o si nṣojo? jẹ ki o pada lọ si ile rẹ̀, ki àiya awọn arakunrin rẹ̀ ki o má ba ṣojo pẹlu bi àiya tirẹ̀.
9
Yio si ṣe, nigbati awọn olori-ogun ba pari ọ̀rọ sisọ fun awọn enia tán, ki nwọn ki o si fi awọn balogun jẹ lori awọn enia na.
10
Nigbati iwọ ba sunmọ ilu kan lati bá a jà, nigbana ni ki iwọ ki o fi alafia lọ̀ ọ.
11
Yio si ṣe, bi o ba da ọ lohùn alafia, ti o si ṣilẹkun silẹ fun ọ, njẹ yio ṣe, gbogbo awọn enia ti a ba bá ninu rẹ̀, nwọn o si ma jẹ́ ọlọsin fun ọ, nwọn o si ma sìn ọ.
12
Bi kò ba si fẹ́ bá ọ ṣe alafia, ṣugbọn bi o ba fẹ́ bá ọ jà, njẹ ki iwọ ki o dótì i:
13
Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi i lé ọ lọwọ, ki iwọ ki o si fi oju idà pa gbogbo ọkunrin ti mbẹ ninu rẹ̀:
14
Ṣugbọn awọn obinrin, ati awọn ọmọ wẹ́wẹ ati ohun-ọ̀sin, ati ohun gbogbo ti mbẹ ni ilu na, ani gbogbo ikogun rẹ̀, ni ki iwọ ki o kó fun ara rẹ; ki iwọ ki o si ma jẹ ikogun awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ.
15
Bayi ni ki iwọ ki o ṣe si gbogbo ilu ti o jìna rére si ọ, ti ki iṣe ninu ilu awọn orilẹ-ède wọnyi.
16
Ṣugbọn ninu ilu awọn enia wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ki iwọ ki o máṣe da ohun kan si ti o nmí:
17
Ṣugbọn ki iwọ ki o pa wọn run patapata; awọn ọmọ Hitti, ati awọn Amori, awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun ọ:
18
Ki nwọn ki o má ba kọ́ nyin lati ma ṣe bi gbogbo iṣẹ-irira wọn, ti nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; ẹnyin a si ṣẹ̀ bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin.
19
Nigbati iwọ ba dótì ilu kan pẹ titi, lati bá a jà lati kó o, ki iwọ ki o máṣe run igi tutù rẹ̀ ni yiyọ ãke tì wọn; nitoripe iwọ le ma jẹ ninu wọn, iwọ kò si gbọdọ ke wọn lulẹ; nitori igi igbẹ́ ha ṣe enia bi, ti iwọ o ma dòtí i?
20
Kìki igi ti iwọ mọ̀ pe nwọn ki iṣe igi jijẹ, on ni ki iwọ ki o run, ki o si ke lulẹ; ki iwọ ki o si sọ agbàra tì ilu na ti mbá ọ jà, titi a o fi ṣẹ́ ẹ.
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34