bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 6
Deuteronomy 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 7 →
1
NJẸ wọnyi li ofin, ìlana, ati idajọ, ti OLUWA Ọlọrun nyin ti palaṣẹ lati ma kọ́ nyin, ki ẹnyin ki o le ma ṣe wọn ni ilẹ nibiti ẹnyin gbé nlọ lati gbà a:
2
Ki iwọ ki o le ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa gbogbo ìlana rẹ̀ ati ofin rẹ̀ mọ́, ti emi fi fun ọ, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ, li ọjọ́ aiye rẹ gbogbo; ki ọjọ́ rẹ ki o le pẹ.
3
Nitorina gbọ́, Israeli, ki o si ma kiyesi i lati ṣe e; ki o le dara fun ọ, ati ki ẹnyin ki o le ma pọ̀si i li ọ̀pọlọpọ, bi OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ ti ṣe ileri fun ọ, ni ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.
4
Gbọ́, Israeli: OLUWA Ọlọrun wa, OLUWA kan ni.
5
Ki iwọ ki o si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ.
6
Ati ọ̀rọ wọnyi, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, ki o ma wà ni àiya rẹ:
7
Ki iwọ ki o si ma fi wọn kọ́ awọn ọmọ rẹ gidigidi, ki iwọ ki o si ma fi wọn ṣe ọ̀rọ isọ nigbati iwọ ba joko ninu ile rẹ, ati nigbati iwọ ba nrìn li ọ̀na, ati nigbati iwọ ba dubulẹ, ati nigbati iwọ ba dide.
8
Ki iwọ ki o si so wọn mọ́ ọwọ́ rẹ fun àmi, ki nwọn ki o si ma ṣe ọja-igbaju niwaju rẹ.
9
Ki iwọ ki o si kọ wọn sara opó ile rẹ, ati sara ilẹkun ọ̀na-ode rẹ.
10
Yio si ṣe, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na, ti o bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fun ọ ni ilu ti o tobi ti o si dara, ti iwọ kò mọ̀,
11
Ati ile ti o kún fun ohun rere gbogbo, ti iwọ kò kún, ati kanga wiwà, ti iwọ kò wà, ọgbà-àjara ati igi oróro, ti iwọ kò gbìn; nigbati iwọ ba jẹ tán ti o ba si yó;
12
Kiyesara rẹ ki iwọ ki o má ba gbagbé OLUWA ti o mú ọ lati ilẹ Egipti jade wá, kuro li oko-ẹrú.
13
Bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ, ki o si ma sìn i, ki o si ma bura li orukọ rẹ̀.
14
Ẹnyin kò gbọdọ tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia, ti o yi nyin ká kiri;
15
Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ Ọlọrun owú ni ninu nyin; ki ibinu OLUWA Ọlọrun rẹ ki o má ba rú si ọ, on a si run ọ kuro lori ilẹ.
16
Ẹnyin kò gbọdọ dán OLUWA Ọlọrun nyin wò, bi ẹnyin ti dan a wò ni Massa.
17
Ki ẹnyin ki o pa ofin OLUWA Ọlọrun nyin mọ́ gidigidi, ati ẹrí rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ti o filelẹ li aṣẹ fun ọ.
18
Ki iwọ ki o ma ṣe eyiti o tọ́, ti o si dara li oju OLUWA: ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le wọ̀ ilẹ rere nì lọ ki o si gbà a, eyiti OLUWA bura fun awọn baba rẹ,
19
Lati tì awọn ọtá rẹ gbogbo jade kuro niwaju rẹ, bi OLUWA ti wi.
20
Nigbati ọmọ rẹ ba bi ọ lère lẹhin-ọla, wipe, Kini èredi ẹrí, ati ìlana, ati idajọ wọnyi, ti OLUWA Ọlọrun filelẹ li aṣẹ fun nyin?
21
Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun ọmọ rẹ pe, Ẹrú Farao li awa ti ṣe ni Egipti; OLUWA si fi ọwọ́ agbara mú wa jade lati Egipti wá.
22
OLUWA si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ti o tobi ti o si buru hàn lara Egipti, lara Farao, ati lara gbogbo ara ile rẹ̀ li oju wa:
23
O si mú wa jade lati ibẹ̀ wá, ki o le mú wa wọ̀ inu rẹ̀, lati fun wa ni ilẹ na ti o bura fun awọn baba wa.
24
OLUWA si pa a laṣẹ fun wa, lati ma ṣe gbogbo ìlana wọnyi, lati ma bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun wa, fun ire wa nigbagbogbo, ki o le pa wa mọ́ lãye, bi o ti ri li oni yi.
25
Yio si jẹ́ ododo wa, bi awa ba nṣọ́ ati ma ṣe gbogbo ofin wọnyi niwaju OLUWA Ọlọrun wa, bi o ti paṣẹ fun wa.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34