bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 22
Deuteronomy 22
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 23 →
1
IWỌ kò gbọdọ ri akọ-malu tabi agutan arakunrin rẹ ti o nṣako, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn; bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o mú wọn pada tọ̀ arakunrin rẹ wá.
2
Bi arakunrin rẹ kò ba si sí nitosi rẹ, tabi bi iwọ kò ba mọ̀ ọ, njẹ ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ, ki o si wà lọdọ rẹ titi arakunrin rẹ yio fi wá a wá, ki iwọ ki o si fun u pada.
3
Bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o ṣe si aṣọ rẹ̀; bẹ̃ na ni ki iwọ ki o si ṣe si gbogbo ohun ninù arakunrin rẹ, ti o nù lọwọ rẹ̀, ti iwọ si ri: ki iwọ ki o máṣe mú oju rẹ kuro.
4
Iwọ kò gbọdọ ri kẹtẹkẹtẹ tabi akọ-malu arakunrin rẹ ki o ṣubu li ọ̀na, ki iwọ ki o si mú oju rẹ kuro lara wọn: iwọ o si ràn a lọwọ nitõtọ lati gbé e dide.
5
Obinrin kò gbọdọ mú ohun ti iṣe ti ọkunrin wọ̀, bẹ̃li ọkunrin kò gbọdọ mú aṣọ obinrin wọ̀: nitoripe gbogbo ẹniti o ba ṣe bẹ̃ irira ni nwọn si OLUWA Ọlọrun rẹ.
6
Bi iwọ ba bá itẹ́ ẹiyẹ kan pade lori igi kan, tabi ni ilẹ, ti o ní ọmọ tabi ẹyin, ti iya si bà lé ọmọ tabi lé ẹyin na, iwọ kò gbọdọ kó iya pẹlu ọmọ:
7
Bikoṣe ki iwọ ki o jọwọ iya lọwọ lọ, ki iwọ ki o si kó ọmọ fun ara rẹ; ki o le dara fun ọ, ati ki iwọ ki o le mu ọjọ́ rẹ pẹ.
8
Nigbati iwọ ba kọ ile titun kan, ki iwọ ki o ṣe igbáti si orule rẹ, ki iwọ o má ba mú ẹ̀jẹ wá sara ile rẹ, bi ẹnikan ba ti ibẹ̀ ṣubu.
9
Iwọ kò gbọdọ fi irú meji irugbìn gbìn ọgbà-àjara rẹ; ki eso irugbìn rẹ gbogbo ti iwọ ti gbìn, ati asunkún ọgbà-àjara rẹ, ki o má ba di ti Ọlọrun.
10
Iwọ kò gbọdọ fi akọ-malu ati kẹtẹkẹtẹ tulẹ pọ̀.
11
Iwọ kò gbọdọ wọ̀ aṣọ olori-ori, ti kubusu ati ti ọ̀gbọ pọ̀.
12
Ki iwọ ki o ṣe wajawaja si igun mẹrẹrin aṣọ rẹ, ti iwọ fi mbò ara rẹ.
13
Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo kan, ti o wọle tọ̀ ọ, ti o si korira rẹ̀,
14
Ti o si kà ọ̀ran si i lọrùn, ti o si bà orukọ rẹ̀ jẹ́, ti o si wipe, Mo gbé obinrin yi, nigbati mo si wọle tọ̀ ọ, emi kò bá a ni wundia:
15
Nigbana ni ki baba ọmọbinrin na, ati iya rẹ̀, ki o mú àmi wundia ọmọbinrin na tọ̀ awọn àgba ilu lọ li ẹnu-bode:
16
Ki baba ọmọbinrin na ki o si wi fun awọn àgba na pe, Emi fi ọmọbinrin mi fun ọkunrin yi li aya, o si korira rẹ̀;
17
Si kiyesi i, o si kà ọ̀ran si i lọrùn, wipe, Emi kò bá ọmọbinrin rẹ ni wundia; bẹ̃ni wọnyi ni àmi wundia ọmọbinrin mi. Ki nwọn ki o si nà aṣọ na niwaju awọn àgba ilu.
18
Ki awọn àgba ilu na ki o si mú ọkunrin na ki nwọn ki o si nà a;
19
Ki nwọn ki o si bù ọgọrun ṣekeli fadakà fun u, ki nwọn ki o si fi i fun baba ọmọbinrin na, nitoriti o bà orukọ wundia kan ni Israeli jẹ́: ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀; ki o máṣe kọ̀ ọ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
20
Ṣugbọn bi ohun na ba ṣe otitọ, ti a kò ba si ri àmi wundia ọmọbinrin na:
21
Nigbana ni ki nwọn ki o mú ọmọbinrin na wá si ẹnu-ọ̀na ile baba rẹ̀, ki awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: nitoriti o hù ìwa-buburu ni Israeli, ni ṣiṣe àgbere ninu ile baba rẹ̀: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
22
Bi a ba mú ọkunrin kan ti o bá obinrin kan dàpọ, ti a gbé ni iyawo fun ọkọ, njẹ ki awọn mejeji ki o kú, ati ọkunrin ti o bá obinrin na dàpo, ati obinrin na: bẹ̃ni ki iwọ ki o si mú ìwa-buburu kuro ni Israeli.
23
Bi ọmọbinrin wundia kan ba wà ni afẹsọna fun ọkọ, ti ọkunrin kan si ri i ni ilu, ti o si bá a dàpọ;
24
Njẹ ki ẹnyin ki o mú awọn mejeji wá si ẹnu-bode ilu na, ki ẹnyin ki o si ṣo wọn li okuta pa; eyi ọmọbinrin nitoriti kò kigbe, nigbati o wà ni ilu; ati eyi ọkunrin nitoriti o tẹ́ aya ẹnikeji rẹ̀ logo: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-buburu kuro lãrin nyin.
25
Ṣugbọn bi ọkunrin na ba ri ọmọbinrin ti afẹsọna na ni igbẹ́, ti ọkunrin na si fi agbara mú u, ti o si bà a dàpọ; njẹ kìki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ni ki o kú:
26
Ṣugbọn si ọmọbinrin na ni ki iwọ ki o máṣe ohun kan; ẹ̀ṣẹ ti o yẹ si ikú kò sí lara ọmọbinrin na: nitori bi igbati ọkunrin kan dide si ẹnikeji rẹ̀, ti o si pa a, bẹ̃li ọ̀ran yi ri:
27
Nitoripe o bá a ninu igbẹ́; ọmọbinrin na ti afẹsọna kigbe, kò si sí ẹniti yio gbà a silẹ.
28
Bi ọkunrin kan ba si ri ọmọbinrin kan ti iṣe wundia, ti a kò ti fẹsọna fun ọkọ, ti o si mú u, ti o si bá a dàpọ, ti a si mú wọn;
29
Njẹ ki ọkunrin na ti o bá a dàpọ ki o fi ãdọta ṣekeli fadakà fun baba ọmọbinrin na, ki on ki o si ma ṣe aya rẹ̀, nitoriti o ti tẹ́ ẹ logo, ki on ki o máṣe kọ̀ ọ silẹ li ọjọ́ aiye rẹ̀ gbogbo.
30
Ki ọkunrin kan ki o máṣe fẹ́ aya baba rẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe tú aṣọ baba rẹ̀.
← Chapter 21
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 23 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34