bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 27
Deuteronomy 27
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 28 →
1
MOSE pẹlu awọn àgba Israeli si paṣẹ fun awọn enia na wipe, Ẹ ma pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni.
2
Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
3
Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ.
4
Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani tán, ẹnyin o kó okuta wọnyi jọ, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, li òke Ebali, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
5
Nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pẹpẹ okuta kan: iwọ kò gbọdọ fi ohun-èlo irin kàn wọn.
6
Okuta aigbẹ́ ni ki iwọ ki o fi mọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA Ọlọrun rẹ:
7
Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ alafia, ki iwọ ki o si jẹun nibẹ̀; ki iwọ ki o ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
8
Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara okuta wọnyi, ki o hàn gbangba.
9
Mose ati awọn alufa awọn ọmọ Lefi si sọ fun gbogbo Israeli pe, Israeli, dakẹ, ki o si gbọ́; li oni ni iwọ di enia OLUWA Ọlọrun rẹ.
10
Nitorina ki iwọ ki o gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, ki o si ma ṣe aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.
11
Mose si paṣẹ fun awọn enia na li ọjọ́ na, wipe,
12
Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini:
13
Awọn wọnyi ni yio si duro lori òke Ebali lati gegún; Reubeni, Gadi, ati Aṣeri, ati Sebuluni, Dani, ati Naftali.
14
Awọn ọmọ Lefi yio si dahùn, nwọn o si wi fun gbogbo awọn ọkunrin Israeli li ohùn rara pe,
15
Egún ni fun ọkunrin na ti o yá ere gbigbẹ́ tabi didà, irira si OLUWA, iṣẹ ọwọ́ oniṣọnà, ti o si gbé e kalẹ ni ìkọ̀kọ̀. Gbogbo enia yio si dahùn wipe, Amin.
16
Egún ni fun ẹniti kò fi baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀ pè. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
17
Egún ni fun ẹniti o ṣí àla ẹnikeji rẹ̀ kuro. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
18
Egún ni fun ẹniti o ṣì afọju li ọ̀na. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
19
Egún ni fun ẹniti o nyi idajọ alejò po, ati ti alainibaba, ati ti opó. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
20
Egún ni fun ẹniti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ̀: nitoriti o tú aṣọ baba rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
21
Egún ni fun ẹniti o bá ẹranko dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
22
Egún ni fun ẹniti o bá arabinrin rẹ̀ dàpọ, ti iṣe ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
23
Egún ni fun ẹniti o bá iya-aya rẹ̀ dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
24
Egún ni fun ẹniti o lù ẹnikeji rẹ̀ ni ìkọkọ. Gbogbo enia ni yio si wipe, Amin.
25
Egún ni fun ẹniti o gbà ọrẹ lati pa alaiṣẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
26
Egún ni fun ẹniti kò duro si gbogbo ọ̀rọ ofin yi lati ṣe wọn. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34