bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Deuteronomy 21
Deuteronomy 21
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 22 →
1
BI a ba ri ẹnikan ti a pa ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati gbà a, ti o dubulẹ ni igbẹ́, ti a kò si mọ̀ ẹniti o pa a:
2
Nigbana ni ki awọn àgba rẹ ati awọn onidajọ rẹ ki o jade wá, ki nwọn ki o si wọ̀n jijìna awọn ilu ti o yi ẹniti a pa na ká.
3
Yio si ṣe, pe ilu ti o sunmọ ẹniti a pa na, ani awọn àgba ilu na ki nwọn mú ẹgbọrọ abo-malu kan, ti a kò fi ṣiṣẹ rí, ti kò si fà ninu àjaga rí;
4
Ki awọn àgba ilu na ki o mú ẹgbọrọ abo-malu na sọkalẹ wá, si afonifoji ti o ní omi ṣiṣàn kan, ti a kò ro ti a kò si gbìn, ki nwọn ki o si ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abomalu na nibẹ̀ li afonifoji na:
5
Awọn alufa, awọn ọmọ Lefi yio si sunmọtosi; nitoripe awọn ni OLUWA Ọlọrun rẹ yàn lati ma ṣe iṣẹ-ìsin fun u, ati lati ma sure li orukọ OLUWA; nipa ọ̀rọ wọn li a o ti ma wadi ọ̀ran iyàn ati ọ̀ran lilù:
6
Ati gbogbo awọn àgba ilu nì, ti o sunmọ ẹniti a pa na, ki nwọn ki o wẹ̀ ọwọ́ wọn sori ẹgbọrọ abo-malu na, ti a ṣẹ́ li ọrùn li afonifoji nì:
7
Ki nwọn ki o si dahùn wipe, Ọwọ́ wa kò tà ẹ̀jẹ yi silẹ, bẹ̃li oju wa kò ri i.
8
OLUWA, darijì Israeli awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada, ki o má si ṣe kà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ si ọrùn Israeli awọn enia rẹ. A o si dari ẹ̀jẹ na jì wọn.
9
Bẹ̃ni iwọ o si mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lãrin nyin, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.
10
Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ si fi wọn lé ọ lọwọ, ti iwọ si dì wọn ni igbekun;
11
Ti iwọ ba si ri ninu awọn igbẹsin na arẹwà obinrin, ti iwọ si ní ifẹ́ si i, pe ki iwọ ki o ní i li aya rẹ;
12
Nigbana ni ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ; ki on ki o si fá ori rẹ̀, ki o si rẹ́ ẽkanna rẹ̀;
13
Ki o si bọ́ aṣọ igbẹsin rẹ̀ kuro lara rẹ̀, ki o si joko ninu ile rẹ, ki o sọkun baba rẹ̀, ati iya rẹ̀ li oṣù kan tọ̀tọ: lẹhin ìgba na ki iwọ ki o wọle tọ̀ ọ, ki o si ma ṣe ọkọ rẹ̀, on a si ma ṣe aya rẹ.
14
Bi o ba si ṣe, ti on kò ba wù ọ, njẹ ki iwọ ki o jẹ ki o ma lọ si ibi ti o fẹ́; ṣugbọn iwọ kò gbọdọ tà a rára li owo, iwọ kò gbọdọ lò o bi ẹrú, nitoriti iwọ ti tẹ́ ẹ logo.
15
Bi ọkunrin kan ba si lí aya meji, ti o fẹ́ ọkan ti o si korira ekeji, ti nwọn si bi ọmọ fun u, ati eyiti o fẹ́ ati eyiti o korira; bi akọ́bi ọmọ na ba ṣe ti ẹniti o korira;
16
Yio si ṣe, li ọjọ́ ti o ba fi awọn ọmọ rẹ̀ jogún ohun ti o ní, ki o máṣe fi ọmọ obinrin ti o fẹ́ ṣe akọ́bi ni ipò ọmọ obinrin ti o korira, ti iṣe akọ́bi:
17
Ṣugbọn ki o jẹwọ ọmọ obinrin ti o korira li akọ́bi, ni fifi ipín meji fun u ninu ohun gbogbo ti o ní: nitoripe on ni ipilẹṣẹ agbara rẹ̀; itọsi akọ́bi ni tirẹ̀.
18
Bi ọkunrin kan ba lí ọmọkunrin kan ti o ṣe agídi ati alaigbọran, ti kò gbà ohùn baba rẹ̀ gbọ́, tabi ohùn iya rẹ̀, ati ti nwọn nà a, ti kò si fẹ́ gbà tiwọn gbọ́:
19
Nigbana ni ki baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ki o mú u, ki nwọn ki o si fà a jade tọ̀ awọn àgba ilu rẹ̀ wá ati si ibode ibujoko rẹ̀;
20
Ki nwọn ki o si wi fun awọn àgba ilu rẹ̀ pe, Ọmọ wa yi, alagídi ati alaigbọran ni, on kò fẹ́ gbọ́ ohùn wa; ọjẹun ati ọmuti ni.
21
Ki gbogbo awọn ọkunrin ilu rẹ̀ ki o sọ ọ li okuta pa: bẹ̃ni ki iwọ ki o mú ìwa-ibi kuro lãrin nyin; gbogbo Israeli a si gbọ́, nwọn a si bẹ̀ru.
22
Bi ọkunrin kan ba dá ẹ̀ṣẹ kan ti o yẹ si ikú, ti a si pa a, ti iwọ si so o lori igi;
23
Ki okú rẹ̀ ki o máṣe gbé ori igi ni gbogbo oru, ṣugbọn bi o ti wù ki o ṣe ki iwọ ki o sin i li ọjọ́ na; nitoripe ẹni egún Ọlọrun li ẹniti a so; ki iwọ ki o má ba bà ilẹ rẹ jẹ́, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34