bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 10
Genesis 10
Yoruba 2010
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 11 →
1
Ìran Noa nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni Ṣemu, Hamu ati Jafẹti. Lẹ́yìn ìkún omi, àwọn mẹtẹẹta bí ọmọ tiwọn.
2
Àwọn ọmọ Jafẹti ni: Gomeri, Magogu, Madai, Jafani, Tubali, Meṣeki ati Tirasi.
3
Àwọn ọmọ Gomeri ni: Aṣikenasi, Rifati, ati Togama.
4
Àwọn ọmọ Jafani ni: Eliṣai, Taṣiṣi, Kitimu ati Dodanimu.
5
Àwọn ni baba ńlá àwọn tí wọn ń gbé etí òkun ati àwọn erékùṣù, tí wọ́n tàn káàkiri. Àwọn ọmọ Jafẹti nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
6
Àwọn ọmọ Hamu ni: Kuṣi, Ijipti, Puti ati Kenaani.
7
Àwọn ọmọ Kuṣi ni: Seba, Hafila, Sabita, Raama ati Sabiteka. Àwọn ọmọ Raama ni: Ṣeba ati Dedani.
8
Kuṣi ni baba Nimrodu, Nimrodu yìí ni ẹni kinni tí wọ́n mọ̀ ní akọni láyé.
9
Pẹlu àtìlẹ́yìn OLUWA, Nimrodu di ògbójú ọdẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n máa ń fi orúkọ rẹ̀ súre fún eniyan pé, “Kí OLUWA sọ ọ́ di ògbójú ọdẹ bíi Nimrodu.”
10
Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni.
11
Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Asiria, ó sì tẹ Ninefe dó, ati Rehoboti Iri, ati Kala,
12
ati ìlú ńlá tí wọn ń pè ní Reseni tí ó wà láàrin Ninefe ati Kala.
13
Ijipti ni ó bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Nafutuhimu,
14
Patirusimu, Kasiluhimu, (lọ́dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistia ti ṣẹ̀) ati Kafitorimu.
15
Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti.
16
Kenaani yìí kan náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, àwọn ará Girigaṣi,
17
àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki, àwọn ará Sini,
18
àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari, ati àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn náà ni ìran àwọn ará Kenaani tàn káàkiri.
19
Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa.
20
Àwọn ọmọ Hamu nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀, oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
21
Ṣemu, ẹ̀gbọ́n Jafẹti, náà bí àwọn ọmọ tirẹ̀, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Eberi.
22
Òun náà ni ó bí Elamu, Aṣuri, Apakiṣadi, Ludi, ati Aramu.
23
Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri, ati Maṣi.
24
Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela sì ni baba Eberi.
25
Àwọn ọmọkunrin meji ni Eberi bí, orúkọ ekinni ni Pelegi, nítorí pé ní ìgbà tirẹ̀ ni ayé pínyà, orúkọ ekeji ni Jokitani.
26
Jokitani ni baba Alimodadi, Ṣelefu, Hasamafeti, Jera,
27
Hadoramu, Usali, Dikila,
28
Obali, Abimaeli,
29
Ṣeba, Ofiri, Hafila, ati Jobabu, àwọn ni ọmọ Jokitani.
30
Ilẹ̀ tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Meṣa, ní ìhà Sefari títí dé ilẹ̀ olókè ti ìhà ìlà oòrùn.
31
Àwọn ni ọmọ Ṣemu, ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀. Oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.
32
Ìdílé àwọn ọmọ Noa ni wọ́n jẹ́, gẹ́gẹ́ bí ìran wọn ní orílẹ̀-èdè wọn. Lára wọn ni àwọn orílẹ̀-èdè ti tàn ká gbogbo ayé lẹ́yìn ìkún omi.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50