bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 17
Genesis 17
Yoruba 2010
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 18 →
1
Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé.
2
N óo bá ọ dá majẹmu kan, tí yóo wà láàrin èmi pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ lọpọlọpọ.”
3
Abramu bá dojúbolẹ̀, Ọlọrun tún wí fún un pé,
4
“Majẹmu tí mo bá ọ dá kò yẹ̀ rárá: O óo jẹ́ baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.
5
Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Abramu mọ́, Abrahamu ni o óo máa jẹ́, nítorí mo ti sọ ọ́ di baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.
6
N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.”
7
“N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ.
8
N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!”
9
Ọlọrun tún sọ fún Abrahamu pé, “Ìwọ pàápàá gbọdọ̀ pa majẹmu mi mọ́, ìwọ ati atọmọdọmọ rẹ láti ìrandíran wọn.
10
Majẹmu náà tí ó wà láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ, tí ẹ gbọdọ̀ pamọ́ nìyí, gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́.
11
Ilà abẹ́ tí ẹ gbọdọ̀ kọ yìí ni yóo jẹ́ àmì majẹmu tí ó wà láàrin mi pẹlu yín.
12
Gbogbo ọmọkunrin tí ó bá ti pé ọmọ ọjọ́ mẹjọ láàrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́, gbogbo ọmọkunrin ninu ìran yín, kì báà ṣe èyí tí a bí ninu ilé yín, tabi ẹrú tí ẹ rà lọ́wọ́ àjèjì, tí kì í ṣe ìran yín,
13
gbogbo ọmọ tí ẹ bí ninu ilé yín, ati ẹrú tí ẹ fi owó yín rà gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Èyí yóo jẹ́ kí majẹmu mi wà lára yín, yóo sì jẹ́ majẹmu ayérayé.
14
Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.”
15
Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́.
16
N óo bukun un, n óo sì fún ọ ní ọmọkunrin kan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, n óo bukun un, yóo sì di ìyá ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo wà lára atọmọdọmọ rẹ̀.”
17
Nígbà náà ni Abrahamu dojúbolẹ̀, ó búsẹ́rìn-ín, ó sì wí ninu ara rẹ̀ pé, “Ọkunrin tí ó ti di ẹni ọgọrun-un (100) ọdún ha tún lè bímọ bí? Sara, tí ó ti di ẹni aadọrun-un ọdún ha tún lè bímọ bí?”
18
Abrahamu bá sọ fún Ọlọrun pé, “Ṣá ti bá mi dá Iṣimaeli yìí sí.”
19
Ọlọrun dá a lóhùn, pé, “Rárá o, àní, Sara, aya rẹ, yóo bí ọmọkunrin kan fún ọ, o óo sọ ọmọ náà ní Isaaki. N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu rẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi majẹmu ayérayé fún atọmọdọmọ rẹ̀.
20
Ní ti Iṣimaeli, mo ti gbọ́ ìbéèrè rẹ, wò ó, n óo bukun òun náà, n óo sì fún un ní ọpọlọpọ ọmọ ati ọmọ ọmọ, yóo jẹ́ baba fún àwọn ọba mejila, n óo sì sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá.
21
Ṣugbọn n óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ pẹlu Isaaki, tí Sara yóo bí fún ọ ní ìwòyí ọdún tí ń bọ̀.”
22
Nígbà tí Ọlọrun bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, ó gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
23
Abrahamu bá mú Iṣimaeli ọmọ rẹ̀, ati gbogbo àwọn ẹrukunrin tí wọ́n bí ninu ilé rẹ̀ ati àwọn tí ó fi owó rẹ̀ rà, àní gbogbo ọkunrin tí ó wà ninu ìdílé Abrahamu, ó sì kọ gbogbo wọn ní ilà abẹ́ ní ọjọ́ náà, bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un.
24
Abrahamu jẹ́ ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un nígbà tí ó kọ ilà abẹ́.
25
Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ ọdún mẹtala nígbà tí òun náà kọlà abẹ́.
26
Ní ọjọ́ náà gan-an ni Abrahamu ati Iṣimaeli ọmọ rẹ̀ kọlà abẹ́,
27
ati gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n bí sinu ilé rẹ̀, ati àwọn tí wọ́n fi owó rà, gbogbo wọn ni wọ́n kọ nílà abẹ́ pẹlu rẹ̀.
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
Recommended Reading
Commentary
Genesis Commentaries
→
Devotional
Genesis Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→