bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 42
Genesis 42
Yoruba 2010
← Chapter 41
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 43 →
1
Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ijipti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Kí ni ẹ̀ ń wo ara yín fún?
2
Ẹ wò ó, mo gbọ́ pé ọkà wà ní Ijipti, ẹ lọ ra ọkà wá níbẹ̀ kí ebi má baà pa wá kú.”
3
Àwọn arakunrin Josẹfu mẹ́wàá bá lọ sí Ijipti, wọ́n lọ ra ọkà.
4
Ṣugbọn Jakọbu kò jẹ́ kí Bẹnjamini, arakunrin Josẹfu bá àwọn arakunrin rẹ̀ lọ, nítorí ẹ̀rù ń bà á kí nǹkankan má tún lọ ṣẹlẹ̀ sí òun náà.
5
Àwọn ọmọ Israẹli lọ ra ọkà pẹlu àwọn mìíràn tí wọ́n wá ra ọkà, nítorí kò sí ibi tí ìyàn náà kò dé ní ilẹ̀ Kenaani.
6
Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
7
Josẹfu rí àwọn arakunrin rẹ̀, ó sì mọ̀ wọ́n, ṣugbọn ó bá wọn sọ̀rọ̀ pẹlu ohùn líle bí ẹni pé kò mọ̀ wọ́n rí, ó ní, “Níbo ni ẹ ti wá?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni, oúnjẹ ni a wá rà.”
8
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Josẹfu mọ̀ dájú pé àwọn arakunrin òun ni wọ́n, wọn kò mọ̀ ọ́n.
9
Josẹfu wá ranti àlá rẹ̀ tí ó lá nípa wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí ni yín, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”
10
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o, oluwa mi, oúnjẹ ni àwa iranṣẹ rẹ wá rà.
11
Ọmọ baba kan náà ni gbogbo wa, olóòótọ́ eniyan sì ni wá, a kì í ṣe amí.”
12
Josẹfu tún sọ fún wọn pé, “N kò gbà, ibi tí àìlera ilẹ̀ yìí wà ni ẹ wá yọ́ wò.”
13
Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀bẹ̀, wọ́n ní, “Ọkunrin mejila ni àwa iranṣẹ rẹ, tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa wà lọ́dọ̀ baba wa nílé, ọ̀kan yòókù ti kú.”
14
Ṣugbọn Josẹfu tẹnumọ́ ọn pé, “Bí mo ti wí gan-an ni ọ̀rọ̀ rí, amí ni yín.
15
Ohun tí n óo fi mọ̀ pé olóòótọ́ ni yín nìyí: mo fi orúkọ Farao búra, ẹ kò ní jáde níhìn-ín àfi bí ẹ bá mú àbíkẹ́yìn baba yín wá.
16
Ẹ rán ọ̀kan ninu yín kí ó lọ mú àbíkẹ́yìn yín wá, ẹ̀yin yòókù ẹ óo wà ninu ẹ̀wọ̀n títí a óo fi mọ̀ bóyá òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, mo tún fi orúkọ Farao búra, amí ni yín.”
17
Ó bá da gbogbo wọn sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọjọ́ mẹta.
18
Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Mo bẹ̀rù Ọlọrun, nítorí náà, bí ẹ bá ṣe ohun tí n óo sọ fun yín yìí, n óo dá ẹ̀mí yín sí.
19
Tí ó bá jẹ́ pé olóòótọ́ eniyan ni yín, kí ọ̀kan ninu yín wà ninu ẹ̀wọ̀n, kí ẹ̀yin yòókù ru ọkà lọ sí ilé fún ìdílé yín tí ebi ń pa,
20
kí ẹ wá mú àbíkẹ́yìn yín tí ẹ̀ ń wí wá, kí n rí i, kí á lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, ẹ óo sì wà láàyè.” Wọ́n bá gbà bẹ́ẹ̀.
21
Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn sọ̀rọ̀ pé, “Dájúdájú, a jẹ̀bi arakunrin wa, nítorí pé a rí ìdààmú ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá, ṣugbọn a kò dá a lóhùn, ohun tí ó fà á nìyí tí ìdààmú yìí fi dé bá wa.”
22
Reubẹni bá dá wọn lóhùn, ó ní, “Mo sọ fun yín àbí n kò sọ, pé kí ẹ má fi ohunkohun ṣe ọmọ náà? Ṣugbọn ẹ kọ̀, ẹ kò gbọ́, òun nìyí nisinsinyii, ẹ̀san ni ó dé yìí.”
23
Wọn kò mọ̀ pé Josẹfu gbọ́ gbogbo ohun tí wọn ń wí, nítorí pé ògbufọ̀ ni wọ́n fi ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.
24
Josẹfu bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ sọkún, ó tún pada wá láti bá wọn sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni láàrin wọn, ó dè é lókùn.
25
Josẹfu pàṣẹ pé kí wọ́n di ọkà sinu àpò olukuluku wọn, kí ó kún, kí wọ́n dá owó olukuluku pada sinu àpò rẹ̀, kí wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ tí wọn yóo jẹ lójú ọ̀nà. Wọ́n ṣe fún wọn bí Josẹfu ti wí.
26
Wọ́n di ẹrù wọn ru àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn, wọ́n sì gbọ̀nà ilé.
27
Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀.
28
Ó wí fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Wọ́n dá owó mi pada, òun nìyí lẹ́nu àpò mi yìí.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ń wo ara wọn lójú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, wọ́n ní, “Irú kí ni Ọlọrun ṣe sí wa yìí?”
29
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n kó gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, wọ́n rò fún un, wọ́n ní,
30
“Ọkunrin tíí ṣe alákòóso ilẹ̀ náà sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó ṣebí a wá ṣe amí ilẹ̀ náà ni.
31
Ṣugbọn a wí fún un pé, ‘Olóòótọ́ ni wá, a kì í ṣe eniyankeniyan, ati pé a kì í ṣe amí rárá.
32
Ọkunrin mejila ni àwa tí a jẹ́ ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ninu wa ti kú, èyí tí ó kéré jù sì wà lọ́dọ̀ baba wa ní ilẹ̀ Kenaani.’
33
Ọkunrin náà bá dáhùn pé, ohun tí yóo jẹ́ kí òun mọ̀ pé olóòótọ́ eniyan ni wá ni pé kí á fi ọ̀kan ninu wa sílẹ̀ lọ́dọ̀ òun, kí á gbé ọkà lọ sílé, kí ebi má baà pa ìdílé wa.
34
Kí á mú àbúrò wa patapata wá fún òun, nígbà náà ni òun yóo tó mọ̀ pé a kì í ṣe amí, ati pé olóòótọ́ eniyan ni wá, òun óo sì dá arakunrin wa pada fún wa, a óo sì ní anfaani láti máa ṣòwò ní ilẹ̀ Kenaani.”
35
Bí wọ́n ti tú àpò wọn, olukuluku bá owó rẹ̀ lẹ́nu àpò rẹ̀. Nígbà tí àwọn ati baba wọn rí èyí, àyà wọn já.
36
Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!”
37
Reubẹni bá wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi mejeeji, bí n kò bá mú Bẹnjamini pada wá fún ọ. Fi lé mi lọ́wọ́, n óo sì mú un pada wá fún ọ.”
38
Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.”
← Chapter 41
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 43 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
Recommended Reading
Commentary
Genesis Commentaries
→
Devotional
Genesis Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→