bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 35
Genesis 35
Yoruba 2010
← Chapter 34
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 36 →
1
Lẹ́yìn náà, Ọlọrun sọ fún Jakọbu pé, “Dìde, lọ sí Bẹtẹli kí o máa gbé ibẹ̀, kí o tẹ́ pẹpẹ kan fún Ọlọrun tí ó farahàn ọ́ nígbà tí ò ń sálọ fún Esau, arakunrin rẹ.”
2
Jakọbu bá sọ fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀ ati àwọn alábàágbé rẹ̀, pé, “Ẹ kó gbogbo ère oriṣa tí ń bẹ lọ́dọ̀ yín dànù, kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì pààrọ̀ aṣọ yín.
3
Lẹ́yìn náà ẹ jẹ́ kí á lọ sí Bẹtẹli, kí n lè tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún Ọlọrun, ẹni tí ó dá mi lóhùn ní ọjọ́ ìpọ́njú, tí ó sì wà pẹlu mi ní gbogbo ibi tí mo ti lọ.”
4
Gbogbo wọn bá dá àwọn ère oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn jọ fún Jakọbu, ati gbogbo yẹtí tí ó wà ní etí wọn, Jakọbu bá bò wọ́n mọ́lẹ̀ lábẹ́ igi oaku tí ó wà ní Ṣekemu.
5
Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun sì dà bo gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká wọn, wọn kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu.
6
Jakọbu ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ bá wá sí Lusi, tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani, èyí nnì ni Bẹtẹli.
7
Ó tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ, ó sì sọ ibẹ̀ ní Eli-Bẹtẹli, nítorí pé níbẹ̀ ni Ọlọrun ti farahàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arakunrin rẹ̀.
8
Níbẹ̀ ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú sí, wọ́n sì sin ín sí abẹ́ igi oaku kan ní ìhà gúsù Bẹtẹli, Jakọbu bá sọ ibẹ̀ ní Aloni-bakuti.
9
Ọlọrun tún fara han Jakọbu, nígbà tí ó jáde kúrò ní Padani-aramu, ó súre fún un.
10
Ọlọrun wí fún un pé, “Jakọbu ni orúkọ rẹ, ṣugbọn wọn kò ní pè ọ́ ní Jakọbu mọ́, Israẹli ni orúkọ rẹ yóo máa jẹ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe sọ ọ́ ní Israẹli.
11
Ọlọrun tún sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa bímọ lémọ, kí o sì pọ̀ sí i, ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati ọpọlọpọ ọba ni yóo ti ara rẹ jáde.
12
N óo fún ọ ní ilẹ̀ tí mo fún Abrahamu ati Isaaki, àwọn ọmọ rẹ ni yóo sì jogún rẹ̀.”
13
Ọlọrun bá gòkè lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti bá a sọ̀rọ̀.
14
Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n òkúta kan nàró níbẹ̀, ó fi ohun mímu rúbọ lórí òkúta náà, ó ta òróró sórí rẹ̀,
15
Ó sì sọ ibẹ̀ ní Bẹtẹli.
16
Wọ́n kúrò ní Bẹtẹli, nígbà tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé Efurati ni ọmọ mú Rakẹli, ara sì ni ín gidigidi.
17
Bí ó ti ń rọbí lọ́wọ́, agbẹ̀bí tí ń gbẹ̀bí rẹ̀ ń dá a lọ́kàn le pé, “Má bẹ̀rù, ọkunrin ni o óo tún bí.”
18
Nígbà tí ẹ̀mí rẹ̀ ń bọ́ lọ, kí ó tó kú, ó sọ ọmọ náà ní Benoni, ṣugbọn baba rẹ̀ sọ ọ́ ní Bẹnjamini.
19
Bẹ́ẹ̀ ni Rakẹli ṣe kú, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọ̀nà Efurati, èyí nnì ni Bẹtilẹhẹmu.
20
Jakọbu gbé ọ̀wọ̀n kan nàró lórí ibojì rẹ̀, òun ni wọ́n ń pè ní ọ̀wọ̀n ibojì Rakẹli, ó sì wà níbẹ̀ títí di òní.
21
Jakọbu tún bẹ̀rẹ̀ sí bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ, ó pàgọ́ rẹ̀ sí òdìkejì ilé ìṣọ́ Ederi.
22
Nígbà tí Israẹli ń gbé ibẹ̀, Reubẹni bá Biliha, aya baba rẹ̀ lòpọ̀, Jakọbu sì gbọ́ nípa rẹ̀.
23
Àwọn ọmọ Jakọbu jẹ́ mejila. Àwọn tí Lea bí ni: Reubẹni, àkọ́bí Jakọbu. Lẹ́hìn rẹ̀ ni ó bí Simeoni, Lefi, Juda, Isakari ati Sebuluni.
24
Àwọn tí Rakẹli bí ni: Josẹfu ati Bẹnjamini.
25
Àwọn tí Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli bí ni: Dani ati Nafutali.
26
Àwọn tí Silipa, iranṣẹbinrin Lea bí ni: Gadi ati Aṣeri. Àwọn wọnyi ni àwọn ọmọ tí wọ́n bí fún Jakọbu ní Padani-aramu.
27
Jakọbu pada sọ́dọ̀ Isaaki, baba rẹ̀, ní Mamure, ìlú yìí kan náà ni wọ́n ń pè ní Kiriati Ariba tabi Heburoni, níbi tí Abrahamu ati Isaaki gbé.
28
Isaaki jẹ́ ẹni ọgọsan-an (180) ọdún nígbà tí ó kú.
29
Ó dàgbà, ó darúgbó lọpọlọpọ kí ó tó kú. Àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Esau ati Jakọbu, sì sin ín.
← Chapter 34
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 36 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50