bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 16
Genesis 16
Yoruba 2010
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 17 →
1
Sarai, aya Abramu, kò bímọ fún un. Ṣugbọn ó ní ẹrubinrin ará Ijipti kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hagari.
2
Ní ọjọ́ kan, Sarai pe Abramu, ó sọ fún un pé, “Ṣé o rí i pé OLUWA kò jẹ́ kí n bímọ, nítorí náà bá ẹrubinrin mi yìí lòpọ̀, ó le jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni n óo ti ní ọmọ.” Abramu sì gba ọ̀rọ̀ Sarai aya rẹ̀.
3
Lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí Abramu ti dé ilẹ̀ Kenaani ni Sarai, aya rẹ̀ fa Hagari, ará Ijipti, ẹrubinrin rẹ̀ fún un, láti fi ṣe aya.
4
Abramu bá Hagari lòpọ̀, Hagari sì lóyún. Nígbà tí ó rí i pé òun lóyún, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi ojú tẹmbẹlu Sarai, oluwa rẹ̀.
5
Sarai bá sọ fún Abramu pé, “Ibi tí Hagari ń ṣe sí mi yìí yóo dà lé ọ lórí. Èmi ni mo fa ẹrubinrin mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó rí i pé òun lóyún tán, mo wá di ẹni yẹ̀yẹ́ lójú rẹ̀. OLUWA ni yóo ṣe ìdájọ́ láàrin èmi pẹlu rẹ.”
6
Ṣugbọn Abramu dá a lóhùn pé, “Ṣebí ìkáwọ́ rẹ ni ẹrubinrin rẹ wà, ṣe é bí ó bá ti wù ọ́.” Sarai bá bẹ̀rẹ̀ sí fòòró ẹ̀mí Hagari, Hagari sì sá kúrò nílé.
7
Angẹli OLUWA rí i lẹ́bàá orísun omi kan tí ó wà láàrin aṣálẹ̀ lọ́nà Ṣuri.
8
Ó pè é, ó ní, “Hagari, ẹrubinrin Sarai, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo ni o sì ń lọ?” Hagari dáhùn pé, “Mò ń sálọ fún Sarai, oluwa mi ni.”
9
Angẹli OLUWA náà wí fún un pé, “Pada tọ oluwa rẹ lọ, kí o sì tẹríba fún un.”
10
Angẹli OLUWA náà tún wí fún un pé, “N óo sọ atọmọdọmọ rẹ di pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kì yóo le kà wọ́n tán.
11
Wò ó! oyún tí ó wà ninu rẹ, ọkunrin ni o óo fi bí, o óo sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli, nítorí OLUWA ti rí gbogbo ìyà tí ń jẹ ọ́.
12
Oníjàgídíjàgan ẹ̀dá ni yóo jẹ́, bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó, yóo máa bá gbogbo eniyan jà, gbogbo eniyan yóo sì máa bá a jà, títa ni yóo sì takété sí àwọn ìbátan rẹ̀.”
13
Nítorí náà, ó pe orúkọ OLUWA tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní “Ìwọ ni Ọlọrun tí ń rí nǹkan.” Nítorí ó wí pé, “Ṣé nítòótọ́ ni mo rí Ọlọrun, tí mo sì tún wà láàyè?”
14
Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ kànga náà ní Beeri-lahai-roi, ó wà láàrin Kadeṣi ati Beredi.
15
Hagari bí ọmọkunrin kan fún Abramu, Abramu sì sọ ọmọ náà ní Iṣimaeli.
16
Abramu jẹ́ ẹni ọdún mẹrindinlaadọrun nígbà tí Hagari bí Iṣimaeli fún un.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 17 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
Recommended Reading
Commentary
Genesis Commentaries
→
Devotional
Genesis Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→