bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 26
Genesis 26
Yoruba 2010
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 27 →
1
Ní àkókò kan, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tí ó mú ní ìgbà Abrahamu. Isaaki bá tọ Abimeleki ọba àwọn ará Filistini lọ ní Gerari.
2
Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un.
3
Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ.
4
N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé,
5
nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.”
6
Isaaki bá ń gbé Gerari.
7
Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin.
8
Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí Isaaki ti ń gbé ìlú náà fún ìgbà pípẹ́, Abimeleki, ọba àwọn ará ìlú Filistia yọjú lójú fèrèsé ààfin rẹ̀, ó rí i tí Isaaki ati Rebeka ń tage.
9
Abimeleki bá pe Isaaki, ó wí pé, “Àṣé iyawo rẹ ni Rebeka! Kí ni ìdí tí o fi pè é ní arabinrin rẹ fún wa?” Isaaki bá dáhùn pé, “Mo rò pé wọ́n lè pa mí nítorí rẹ̀ ni.”
10
Abimeleki bá dá a lóhùn pé, “Irú kí ni o dánwò sí wa yìí? Ǹjẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi bá ti bá aya rẹ lòpọ̀ ńkọ́? O ò bá mú ẹ̀bi wá sórí wa.”
11
Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.”
12
Isaaki dá oko ní ilẹ̀ náà, láàrin ọdún kan ṣoṣo ó rí ìkórè ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un (100) ohun tí ó gbìn nítorí OLUWA bukun un.
13
Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní àníkún títí ó fi di ọlọ́rọ̀.
14
Ó ní ọpọlọpọ agbo aguntan ati agbo mààlúù, pẹlu ọpọlọpọ iranṣẹ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Filistia bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀.
15
Gbogbo kànga tí àwọn iranṣẹ Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́ ní àkókò tí Abrahamu wà láyé ni àwọn ará Filistia rọ́ yẹ̀ẹ̀pẹ̀ dí.
16
Abimeleki bá wí fún Isaaki pé, “Kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé o ti lágbára jù wá lọ.”
17
Isaaki kúrò níbẹ̀, ó lọ tẹ̀dó sí àfonífojì Gerari.
18
Isaaki tún àwọn kànga tí wọ́n ti gbẹ́ nígbà ayé Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́, nítorí pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Abrahamu kú ni àwọn ará Filistia ti dí wọn. Ó sì sọ àwọn kànga náà ní orúkọ tí baba rẹ̀ sọ wọ́n.
19
Ṣugbọn nígbà tí àwọn iranṣẹ Isaaki gbẹ́ kànga kan ní àfonífojì náà tí wọ́n sì kan omi,
20
àwọn darandaran ará Gerari bá àwọn tí wọn ń da ẹran Isaaki jà, wọ́n wí pé, “Àwa ni a ni omi kànga yìí.” Nítorí náà ni Isaaki ṣe sọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà nítorí rẹ̀.
21
Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina.
22
Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.”
23
Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba.
24
OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.”
25
Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ.
26
Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀.
27
Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?”
28
Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu,
29
pé o kò ní pa wá lára, gẹ́gẹ́ bí àwa náà kò ti ṣe ọ́ níbi, àfi ire, tí a sì sìn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa ní alaafia.”
30
Isaaki bá se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n mu.
31
Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, wọ́n ṣe ìbúra láàrin ara wọn, Isaaki bá sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n sì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ní alaafia.
32
Ní ọjọ́ náà gan-an ni àwọn iranṣẹ rẹ̀ wá sọ fún un pé àwọn kan omi ninu kànga kan tí àwọn gbẹ́.
33
Ó sọ kànga náà ní Ṣeba. Ìdí nìyí tí orúkọ ìlú náà fi ń jẹ́ Beeriṣeba títí di òní yìí.
34
Nígbà tí Esau di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Juditi, ọmọ Beeri, ará Hiti ati Basemati, ọmọ Eloni, ará Hiti.
35
Àwọn obinrin mejeeji yìí han Isaaki ati Rebeka léèmọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ayé sú wọn.
← Chapter 25
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 27 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
Recommended Reading
Commentary
Genesis Commentaries
→
Devotional
Genesis Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→