bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 7
Genesis 7
Yoruba 2010
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 8 →
1
Nígbà tí ó yá OLUWA sọ fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ, ìwọ ati àwọn ará ilé rẹ, nítorí pé ìwọ nìkan ni o jẹ́ olódodo sí mi ní gbogbo ayé.
2
Ninu gbogbo ẹran tí ó bá jẹ́ mímọ́, mú wọn ní takọ-tabo, meje meje, ṣugbọn ninu gbogbo ẹran tí kò bá jẹ́ mímọ́, mú akọ kan ati abo kan.
3
Mú takọ-tabo meje meje ninu àwọn ẹyẹ, kí irú wọn lè wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé.
4
Nítorí pé ọjọ́ meje ló kù tí n óo bẹ̀rẹ̀ sí rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́ tọ̀sán-tòru, gbogbo ẹ̀dá alààyè tí mo dá ni yóo sì parun lórí ilẹ̀ ayé.”
5
Noa bá ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un.
6
Noa jẹ́ ẹni ẹgbẹta (600) ọdún nígbà tí ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.
7
Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati aya rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ pẹlu aya wọn, láti sá àsálà kúrò lọ́wọ́ ìkún omi.
8
Gbogbo ẹran ati àwọn tí wọ́n mọ́ ati àwọn tí wọn kò mọ́, àwọn ẹyẹ ati gbogbo ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀,
9
ní meji meji, àtakọ àtabo, gbogbo wọn bá Noa wọ inú ọkọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pa á láṣẹ fún Noa.
10
Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi bo ilẹ̀ ayé.
11
Ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù keji ọdún tí Noa di ẹni ẹgbẹta (600) ọdún, ni orísun alagbalúgbú omi tí ó wà ninu ọ̀gbun ńlá lábẹ́ ilẹ̀ ya, tí gbogbo fèrèsé omi tí ó wà ní ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀,
12
òjò sì rọ̀ fún ogoji ọjọ́, tọ̀sán-tòru.
13
Ní ọjọ́ náà gan-an ni Noa wọ inú ọkọ̀ lọ, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta, Ṣemu, Hamu, ati Jafẹti ati aya rẹ̀ ati àwọn aya àwọn ọmọ rẹ̀ mẹtẹẹta;
14
pẹlu àwọn ẹranko ati àwọn ẹran ọ̀sìn, ati àwọn ohun tí ń fàyà fà káàkiri lórí ilẹ̀, ati oniruuru àwọn ẹyẹ.
15
Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè patapata ni wọ́n wọ inú ọkọ̀ tọ Noa lọ ní meji meji.
16
Gbogbo àwọn ohun ẹlẹ́mìí, akọ kan, abo kan, ní oríṣìí kọ̀ọ̀kan wọlé gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún Noa. OLUWA bá ti ìlẹ̀kùn ọkọ̀ náà.
17
Ìkún omi wà lórí ilẹ̀ fún ogoji ọjọ́. Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi léfòó lójú omi.
18
Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i ni ọkọ̀ náà ń lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún lórí rẹ̀.
19
Omi náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi bo gbogbo àwọn òkè gíga tí wọ́n wà láyé mọ́lẹ̀.
20
Ó sì tún pọ̀ sí i títí tí ó fi ga ju àwọn òkè gíga lọ ní igbọnwọ mẹẹdogun (mita 7).
21
Gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé ni wọ́n kú patapata, ati ẹyẹ, ati ẹran ọ̀sìn, ati ẹranko, ati àwọn ohun tí wọn ń fàyà fà ati eniyan.
22
Gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń mí lórí ilẹ̀ ayé patapata ni wọ́n kú.
23
Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe pa gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé run: gbogbo eniyan, gbogbo ẹranko, gbogbo ohun tí ń rìn káàkiri lórí ilẹ̀ ati ẹyẹ. Noa nìkan ni kò kú ati àwọn tí wọ́n jọ wà ninu ọkọ̀ pẹlu rẹ̀.
24
Aadọjọ (150) ọjọ́ gbáko ni omi fi bo gbogbo ilẹ̀.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50