bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 39
Genesis 39
Yoruba 2010
← Chapter 38
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 40 →
1
Àwọn ará Iṣimaeli mú Josẹfu lọ sí Ijipti, wọ́n sì tà á fún Pọtifari ará Ijipti. Pọtifari yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ìjòyè Farao, òun sì tún ni olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba.
2
OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ninu ilé ọ̀gá rẹ̀, ará Ijipti, níbi tí ó ń gbé. Àwọn ohun tí ó ń ṣe sì ń yọrí sí rere.
3
Ọ̀gá rẹ̀ ṣàkíyèsí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ati pé OLUWA ń bukun ohun gbogbo tí ó bá dáwọ́lé.
4
Nítorí náà, ó rí ojurere Pọtifari. Pọtifari mú un sọ́dọ̀ pé kí ó máa ṣe iranṣẹ fún òun, ó fi ṣe alabojuto gbogbo ilé rẹ̀, ó sì fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ rẹ̀.
5
Nígbà tí Pọtifari ti fi Josẹfu ṣe alabojuto ilé rẹ̀ ati gbogbo ohun ìní rẹ̀, OLUWA bẹ̀rẹ̀ sí bukun ìdílé Pọtifari, ará Ijipti náà, ati ohun gbogbo tí ó ní nítorí ti Josẹfu.
6
Nítorí náà, ó fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ Josẹfu níwọ̀n ìgbà tí ó wà pẹlu rẹ̀, kò sì bìkítà fún ohunkohun mọ́, àfi oúnjẹ tí ó ń jẹ. Josẹfu ṣígbọnlẹ̀, ó sì lẹ́wà.
7
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Josẹfu wu aya ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ ọ́ pé kí ó wá bá òun lòpọ̀.
8
Ṣugbọn Josẹfu kọ̀, ó wí fún un pé, “Wò ó, níwọ̀n ìgbà tí mo wà lọ́dọ̀ ọ̀gá mi, kò bìkítà fún ohunkohun ninu ilé yìí, ó sì ti fi ohun gbogbo tí ó ní sí ìkáwọ́ mi.
9
Kò sí ohun tí ó fi jù mí lọ ninu ilé yìí, kò sì sí ohun tí kò fi lé mi lọ́wọ́, àfi ìwọ nìkan, nítorí pé aya rẹ̀ ni ọ́. Ǹjẹ́ ó tọ́ sí mi láti ṣe irú ohun burúkú yìí kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọrun?”
10
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lojoojumọ ni ó ń rọ Josẹfu, sibẹsibẹ, Josẹfu kò gbà láti bá a lòpọ̀, tabi láti wà pẹlu rẹ̀.
11
Ṣugbọn ní ọjọ́ kan nígbà tí Josẹfu wọ inú ilé lọ láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni nílé ninu àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀.
12
Obinrin yìí so mọ́ ọn lẹ́wù, ó ní, “Wá bá mi lòpọ̀.” Ṣugbọn Josẹfu bọ́rí kúrò ninu ẹ̀wù rẹ̀, ó sá jáde kúrò ninu ilé.
13
Nígbà tí ó rí i pé Josẹfu fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí òun lọ́wọ́, ati pé ó sá jáde kúrò ninu ilé,
14
ó pe àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ninu ilé rẹ̀, ó sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ wo nǹkan, ọkọ mi ni ó mú Heberu yìí wá láti wá fi ẹ̀gbin lọ̀ wá. Ó wọlé wá bá mi láti bá mi lòpọ̀, ni mo bá pariwo.
15
Nígbà tí ó sì rí i pé mo pariwo, ó sá jáde, ó fi ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́.”
16
Obinrin náà bá fi ẹ̀wù rẹ̀ sọ́dọ̀ títí tí ọ̀gá rẹ̀ fi wọlé dé.
17
Nígbà tí ó dé, obinrin yìí sọ ohun kan náà fún un, ó ní, “Ẹrú ará Heberu tí o mú wá sí ààrin wa, ni ó déédé wọlé tọ̀ mí wá láti fi ẹ̀gbin lọ̀ mí,
18
ṣugbọn nígbà tí ó rí i pé mo pariwo, ó ju ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀ sí mi lọ́wọ́, ó sá jáde.”
19
Nígbà tí ọ̀gá rẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí iyawo rẹ̀ sọ fún un pé, “Bí ẹrú rẹ ti ṣe sí mi nìyí” inú bí i gidigidi,
20
ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́.
21
Ṣugbọn OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ó sì fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀ hàn sí i, ó jẹ́ kí ó bá ojurere alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pàdé.
22
Alabojuto náà fi Josẹfu ṣe olùdarí gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ẹ̀wọ̀n, ohunkohun tí Josẹfu bá sọ, ni wọ́n ń ṣe.
23
Alabojuto ọgbà ẹ̀wọ̀n náà kì í fi nǹkan lé Josẹfu lọ́wọ́ kí ó tún bìkítà fún un mọ́, nítorí pé OLUWA wà pẹlu Josẹfu, ohunkohun tí ó bá ṣe, OLUWA ń jẹ́ kí ó yọrí sí rere.
← Chapter 38
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 40 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50