bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Genesis 12
Genesis 12
Yoruba 2010
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 13 →
1
Ní ọjọ́ kan, Ọlọrun sọ fún Abramu pé, “Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ìbátan rẹ, ati kúrò ní ilé baba rẹ lọ sí ilẹ̀ kan tí n óo fi hàn ọ́.
2
N óo sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá, n óo bukun ọ, n óo sì sọ orúkọ rẹ di ńlá, tóbẹ́ẹ̀ tí o óo jẹ́ ibukun fún àwọn eniyan.
3
N óo súre fún àwọn tí wọ́n bá súre fún ọ, bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ bú, n óo fi òun náà bú. Nípasẹ̀ rẹ ni n óo bukun gbogbo ìdílé ayé.”
4
Bẹ́ẹ̀ ni Abramu ṣe jáde lọ, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ fún un, Lọti sì bá a lọ. Abramu jẹ́ ẹni ọdún marundinlọgọrin nígbà tí ó jáde kúrò ní Harani.
5
Abramu mú Sarai iyawo rẹ̀, ati Lọti, ọmọ arakunrin rẹ̀ lọ́wọ́ lọ, ati gbogbo ohun ìní wọn ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n jẹ́ tiwọn ní Harani. Wọ́n jáde, wọ́n gbọ̀nà ilẹ̀ Kenaani. Nígbà tí wọ́n dé ilẹ̀ Kenaani,
6
Abramu la ilẹ̀ náà kọjá lọ sí ibi igi Oaku ti More, ní Ṣekemu. Àwọn ará Kenaani ni wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà nígbà náà.
7
Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án.
8
Lẹ́yìn náà Abramu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí orí òkè tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Bẹtẹli, ó pàgọ́ sibẹ. Bẹtẹli wà ní ìhà ìwọ̀ oòrùn ibùdó rẹ̀, Ai sì wà ní ìhà ìlà oòrùn. Ó tún tẹ́ pẹpẹ mìíràn níbẹ̀, ó sì sin OLUWA.
9
Abramu ṣá ń lọ sí ìhà gúsù ní agbègbè tí à ń pè ní Nẹgẹbu.
10
Ní àkókò kan, ìyàn mú gidigidi ní ilẹ̀ Kenaani. Ìyàn náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí Abramu níláti kó lọ sí Ijipti, láti máa gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.
11
Nígbà tí ó ń wo Ijipti lókèèrè, ó sọ fún Sarai aya rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ náà mọ̀ pé arẹwà obinrin ni ọ́,
12
ati pé bí àwọn ará Ijipti bá ti fi ojú kàn ọ́, wọn yóo wí pé, ‘Iyawo rẹ̀ nìyí’, wọn yóo pa mí, wọn yóo sì dá ọ sí.
13
Wò ó, wí fún wọn pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wá, kí wọ́n lè ṣe mí dáradára, kí wọ́n má baà tìtorí rẹ pa mí.”
14
Nígbà tí Abramu wọ Ijipti, àwọn ará Ijipti rí i pé arẹwà obinrin ni aya rẹ̀.
15
Nígbà tí àwọn ìjòyè ọba Farao rí i, wọ́n pọ́n ọn lójú Farao, wọ́n sì mú un wá sí ààfin rẹ̀.
16
Nítorí ti Sarai, Farao ṣe Abramu dáradára. Abramu di ẹni tí ó ní ọpọlọpọ aguntan, akọ mààlúù, akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, iranṣẹkunrin, iranṣẹbinrin, abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ati ràkúnmí.
17
Ṣugbọn OLUWA fi àrùn burúkú bá Farao ati gbogbo ìdílé rẹ̀ jà nítorí Sarai, aya Abramu.
18
Farao bá pe Abramu, ó bi í pé, “Èéṣe tí o fi ṣe báyìí sí mi? Èéṣe tí o kò fi sọ fún mi pé iyawo rẹ ni Sarai?
19
Èéṣe tí o fi sọ pé tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni yín, tí o jẹ́ kí n fi ṣe aya? Iyawo rẹ nìyí, gba nǹkan rẹ, kí o sì máa lọ.”
20
Farao bá pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ nípa Abramu, wọ́n sì rí i pé Abramu jáde kúrò nílùú, ati òun ati aya rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 49
Chapter 50
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
Recommended Reading
Commentary
Genesis Commentaries
→
Devotional
Genesis Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→