bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 14
Exodus 14
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 15 →
1
OLÚWA sọ fún Mósè pé
2
“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Háhírótù láàrin Mígídólù òun òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá òkun, ní òdìkejì Baali-Séfóní.
3
Fáráò yóò ronu pé àwọn ọmọ Isírẹ́lì ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé ihà náà ti sé wọn mọ́.
4
Èmi yóò sé ọkàn Fáráò le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpaṣẹ̀ Fáráò àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.” Àwọn Isírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀.
5
Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Éjíbítì pé àwọn ènìyàn náà ti sá lọ, ọkàn Fáráò àti àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.”
6
Ó sì di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀,
7
ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Éjíbítì, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn.
8
OLÚWA ṣe ọkàn Fáráò ọba Éjíbítì le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù.
9
Àwọn ará Éjíbítì ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹsin kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bá òkun ní ìhà Pi-Hahírótù, ni òdì kejì Baali-Ṣéfónì.
10
Bí Fáráò ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Éjíbítì tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Ísírẹ́lì, wọ́n kígbe sókè sí OLÚWA.
11
Wọ́n sọ fún Móse pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Éjíbítì ní ìwọ se mú wa wá láti kú sínú ihà? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì wá?
12
Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Éjíbítì, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Éjíbítì’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Éjíbítì ju kí a kú sínú ihà yìí lọ!”
13
Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ ma bẹ̀rù, ẹ dúró sinsin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí OLÚWA yóò fifún un yín lónìí; Àwọn ará Éjíbítì ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́.
14
OLÚWA yóò jà fún un yin; kí ẹ̀yin kí ó sáà mu sùúrù.”
15
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì kí wọn máa tẹ̀ṣíwájú.
16
Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi òkun, kí ó lè pín níyà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè la òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀.
17
Nígbà náà ni èmi yóò ṣé ọkàn àwọn ará Éjíbítì le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Fáráò; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́-ògun àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.
18
Àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Fáráò: lórí kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.”
19
Nígbà náà ni ańgẹ́lì Ọlọ́run tó ti ń ṣááju ogun Ísírẹ́lì lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn.
20
Ó sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Éjíbítì àti Ísírẹ́lì. Ìkùùkuu sì su òkùnkùn sí àwọn ará Éjíbítì ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Ísírẹ́lì ni òru náà; Ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.
21
Nígbà náà ni Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, ni gbogbo òru náà ni OLÚWA fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà,
22
àwọn ọmọ Ísírẹ́lì si la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.
23
Àwọn ará Éjíbítì sì ń lépa wọn, gbogbo ẹsin Fáráò, kẹ́kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun.
24
Ní ìsọ́ òwúrọ̀ (láàárin ago mẹ́ta sí mẹ́ta òwúrọ̀) OLÚWA bojúwo ogun àwọn ará Éjíbítì láàrin òpó iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ ogun Éjíbítì.
25
Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́-ogun náà rìn. Àwọn ará Éjíbítì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àṣálà kúrò ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì nítorí OLÚWA ń bá wa jà nítorí wọn.”.
26
OLÚWA sì wí fún Mósè pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Éjíbítì, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́sin wọn.”
27
Mósè sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ìlẹ̀ mọ́. Àwọn ará Éjíbítì ń sá fún omi òkun, OLÚWA sì gbá wọn sínú òkun.
28
Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin: àní, gbogbo ọmọ ogun Fáráò ti wọn wọ inú òkun tọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn ti o yè.
29
Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn.
30
Ni ọjọ́ yìí ni OLÚWA gba Ísírẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì; Ísírẹ́lì sì rí òkú àwọn ará Éjíbítì ni etí òkun.
31
Nígbà ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti OLÚWA se fún wọn lára àwọn ará Éjíbítì, àwọn ènìyàn bẹ̀rù OLÚWA, wọ́n sì gba OLÚWA àti Mósè ìráńṣẹ́ rẹ gbọ́.
← Chapter 13
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 15 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40