bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 24
Exodus 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 25 →
1
Ní ìgbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Gòkè tọ OLÚWA wá, ìwọ àti Árónì, Nádábú àti Ábíhù àti àádọ́rin (70) àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin kì ó sìn ni òkèèrè réré.
2
Ṣùgbọ́n Mósè nìkan ṣoṣo ni yóò súnmọ́ OLÚWA; àwọn tókù kò gbọdọ̀ súnmọ́ tòsí ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò gbọdọ̀ gòkè wá pẹ̀lú rẹ̀.”
3
Nígbà ti Mósè lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn, gbogbo ọ̀rọ̀ àti òfin OLÚWA, wọ́n wí ní ohùn kan pé, “Gbogbo ohun ti OLÚWA wí ni àwa yóò ṣe.”
4
Nígbà náà ni Mósè kọ gbogbo ohun tí OLÚWA sọ sílẹ̀. Ó dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mọ pẹpẹ ni ẹsẹ̀ òkè náà. Ó se ọ̀wọ́n òkúta méjìlá. Èyí ti ó dúró fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.
5
Nígbà náà ni ó rán àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Ísírẹ́lì, wọ́n sì rúbọ sísun, wọ́n fi ọ̀dọ́ màlúù rú ẹbọ àlàáfíà si OLÚWA.
6
Mósè bu ìlàjì ẹ̀jẹ̀ ẹran sínú abọ́, ó sì fi ìlàjì tókù wọn ara pẹpẹ.
7
Nígbà náà ni ó sì mú ìwé májẹ̀mú, ó sì kà á sí àwọn ènìyàn. Wọ́n dáhùn pé, “Àwa yóò ṣe gbogbo ohun tí OLÚWA wí: Àwa yóò sì gbọ́ràn.”
8
Nígbà náà ni Mósè gbé ẹ̀jẹ̀, ó sì wọn sí àwọn ènìyàn náà lára pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú yín ni ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.”
9
Mósè àti Árónì, Nádábù àti Ábíhù àti àádọ́rin àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì gòkè lọ.
10
Wọ́n sì rí Ọlọ́run Ísírẹ́lì. Ní abẹ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta sáfírè ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ niṣínniṣín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnraarẹ̀.
11
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wọ̀nyí; wọ́n ri Ọlọ́run, wọ́n jẹ, wọ́n sì mu.
12
OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Gòkè wá sí ọ̀dọ̀ mi, kí o sì dúró níhín-ín. Èmi yóò sì fún ọ ní òkúta ìkọ̀wé pẹ̀lú òfin àti ìlànà tí mo ti kọ sílẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà wọn.”
13
Nígbà náà ni Mósè jáde lọ pẹ̀lú Jọsúà arákùnrin rẹ̀. Mósè lọ sí orí òkè Ọlọ́run.
14
Ó sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsìí, Árónì àti Húrì ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnikan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.
15
Nígbà tí Mósè gun orí òkè lọ, ìkúúkùù bo orí òkè náà.
16
Ògo OLÚWA sì wà ní orí òkè Ṣí náì. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni OLÚWA kọ sí Mósè láti inú ìkùùkuu náà wá.
17
Ni ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ògo OLÚWA náà dà bí iná ajónirun ni orí òkè.
18
Nígbà náà ni Mósè wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40