bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 15
Exodus 15
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 16 →
1
Nígbà náà ni Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orin yìí sí OLÚWA: Èmi yóò kọrin sí OLÚWA, nítorí òun pọ̀ ní ògo. Ẹsin àti ẹni tí ó gùn un ni ó ti sọ sínú òkun.
2
OLÚWA ni agbára àti orin mi; òun ti di Olùgbàlà mi, òun ni Ọlọ́run mi, èmi ó yìn ín, Ọlọ́run baba mi, èmi ó gbé e ga.
3
Ologun ni OLÚWA, OLÚWA ni orúkọ rẹ,
4
Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ ni ó mú wọ inú òkun. Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọ ni ó rì sínú òkun pupa.
5
Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀; Wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.
6
“Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLÚWA, pọ̀ ní agbára. Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, OLÚWA, fọ́ àwọn ọ̀ta túútúú.
7
Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbi ìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú. Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ; Tí ó run wọ́n bí ìgémọ́lẹ̀ ìdí koríko
8
Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ń wọ́jọ pọ̀ Ìsàn omi dìde dúró bí odi; Ibú omi sì dìpọ̀ láàrin òkun.
9
“Ọ̀ta ń gbéraga, ó ń wí pé: ‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn. Èmi ó pín ìkógun; Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn. Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’
10
Ìwọ fẹ́ èèmí rẹ òkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀ wọ́n rì bí òjé ni àárin omi ńlá.
11
“Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, OLÚWA? Ta ló dàbí rẹ: ní títóbi, ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìn Tí ń se ohun ìyanu?
12
Ìwọ na apá ọ̀tún rẹ Ilẹ̀ si gbé wọn mì.
13
“Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í ṣákìí ìwọ se amọ̀nà Àwọn ènìyàn náà tí ìwọ ti ràpadà Nínú agbára rẹ ìwọ yóò tọ́ wọn lọ sí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.
14
Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrì Ìkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn palẹ́sítínì.
15
Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Édómù, Àwọn olórí Móábù yóò wárìrì Àwọn ènìyàn Kénánì yóò sì yọ̀ danu;
16
Ìbẹ̀rù-bojo yóò subú lù wọ́n nítorí nína títóbi apá rẹ̀ wọn yóò dúró jẹ́ ẹ́ láì mira bí i òkúta Títí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi ré kọjá, OLÚWA, Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi ré kọjá.
17
Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́n ni ori òkè ti ìwọ jogún; Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, OLÚWA. Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, OLÚWA.
18
OLÚWA yóò jọba láé àti láéláé.”
19
Nígbà ti ẹsin Fáráò, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ inú òkun, OLÚWA mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.
20
Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Árónì, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, àwọn obìnrin ti ó tẹ̀lé pẹ̀lú mú ohun èlò orin wọ́n sì ń jó.
21
Míríámà kọrin sí wọn báyìí pé: “Ẹ kọrin sí OLÚWA Nítorí òun ni ológo jùlọ Ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún Ni òun bi subú sínú òkun.”
22
Nígbà náà ni Mósè ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti òkun pupa lọ sínú aṣálẹ̀ Ṣúrì. Wọ́n lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi.
23
Nígbà tí wọ́n dé Márà, wọn kò lè mu omi Márà nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Márà: ibi ìkorò).
24
Àwọn ènìyàn ń kùn sí Mósè wí pé, “Kí ni àwa yóò mu?”
25
Mósè sì ké pe OLÚWA, OLÚWA sì fi igi kan hàn án, ó sì sọ igi náà sínú omi, omi náà sì dùn. Níbẹ̀ ni OLÚWA ti gbé ìlànà àti òfin kalẹ̀ fún wọn, níbẹ̀ ni ó sì ti dán wọn wò.
26
Ó wí pé, “Bí ìwọ bá fetísílẹ̀ dáradára sí òfin OLÚWA Ọlọ́run, ti ìwọ si ṣe ohun tí ó tọ́ ni ojú rẹ̀, ti ìwọ sì tẹ̀lé ohun tí ó pàṣẹ, ti ìwọ si pa ìlànà rẹ̀ mọ́. Èmi kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí nínú àwọn àrùn wọ̀n-ọn-nì ti mo mú wá sórí àwọn ará Éjíbítì wá sí ara rẹ, nítorí èmi ni OLÚWA ti ó mú ọ lára da.”
27
Nígbà ti wọ́n dé Élímù, nibi ti kànga omi méjìlá (12) àti àádọ́rin (70) ọ̀pẹ gbé wà, wọ́n pàgọ́ ṣíbẹ̀ ni etí omi.
← Chapter 14
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 16 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40