bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 38
Exodus 38
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 37
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 39 →
1
Ó sì fi igi kaṣíá kọ́ pẹpẹ ẹbọ sísun, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà ni gíga rẹ̀: ìgbọ̀nwọ́ márùn ún, igun rẹ̀ ṣe déédé.
2
Ó ṣe ìwo sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, nítorí kí ìwo àti pẹpẹ náà lè jẹ́ ọ̀kan, ó sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ.
3
Idẹ ni ó ṣe gbogbo ohun èlò pẹpẹ, ìkòkò rẹ̀, ọkọ, àwokòtò rẹ̀, fọ́ọ̀kì tí a fi rí mú ẹran àti àwo iná rẹ̀.
4
Ó ṣe àrò fún pẹpẹ náà, àwọ̀n onídẹ, kí ó wà níṣàlẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀, dé ìdajì òkè pẹpẹ náà.
5
Ó dá òrùka idẹ láti mú kí ó di òpó igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin idẹ àrò náà mú.
6
Ó sì fi igi kasíà ṣe àwọn òpó náà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú idẹ.
7
Ó sì fi òpó náà bọ inú òrùka, nítorí kí ó lè wà ní ìhà pẹpẹ náà láti máa fi gbé e. Ó sì sé e ní oníhò nínú.
8
Ó ṣe agbada idẹ, o sì fi idẹ ṣe ẹṣẹ̀ rẹ̀ ti àwòjíji àwọn obìnrin tí ó ń sìn ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.
9
Ó sì ṣe àgbàlá náà. Ní ìhà gúsù ni aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára wà, ó jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gígùn (46 meters),
10
pẹ̀lú ogún òpó àti ogún (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, àti pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.
11
Ní ìhà àríwá náà tún jẹ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta (46 meters) ní gígùn, ó sì ní ogún òpó àti ogun (20) ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà.
12
Ìhà ìwọ̀ oòrùn jẹ́ mítà mẹ́talélógún (23 meters) ní fífẹ̀, ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá, pẹ̀lú fàdákà tí ó kọ́ ọ, tí ó sì de àwọn òpó náà pọ̀.
13
Fún ìhà ìlà oòrùn, sí ibi tí oòrùn ti ń yọ náà jẹ́ mítà mẹ́talélógún ni fífẹ̀ (23 meters)
14
Aṣọ títa ìhà ẹnu ọ̀nà kan jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
15
àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀ (6. 9 meters) pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà.
16
Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.
17
Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.
18
Aṣọ tita fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ ni. Ó jẹ́ mítà mẹ́sàn-án ní gígùn (9 meters), gẹ́gẹ́ bí aṣọ títa àgbàlá náà, àti gíga rẹ̀ jẹ mítà méjì (2. 3 meters),
19
pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà.
20
Gbogbo èèkàn àgọ́ tabánákù náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.
21
Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabánákù náà, tabánákù ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Árónì àlùfáà.
22
(Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà, ṣe ohun gbogbo ti OLÚWA pàṣẹ fún Mósè;
23
Pẹ̀lú rẹ̀ ni Óhólíábù ọmọ Áhísámákì, ti ẹ̀yà Dánì-alágbẹ̀dẹ́, àti oníṣẹ́ ọnà àti oníṣọ̀nà iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ní aṣọ aláró àti elésèé àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.)
24
Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ẹgbẹ̀rin (730) sékélì gẹ́gẹ́ bí i sékélì ibi mímọ́.
25
Sílífà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) talẹ́ntì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó lé mẹ́ẹ̀dógún sékélì (1,775) gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́
26
ìwọ̀n gíráàmù márùn-ún ààbọ̀ (5. 5 grams) lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀tadínlógún-ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550 men).
27
Ọgọ́run-ún talẹ́ntì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùnún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún talẹ́ntì náà talẹ́ntì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.
28
Ó lo òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀dogun sékélì (1,775 shekels) ìwọ̀n ogún gíráàmù ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ìgbànú wọn.
29
Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ntì àti egbèjìlá sékélì (2,400 shekels).
30
Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú àrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,
31
ihò ìtẹ̀bọ̀ fún àyíká àgbàlá náà àti èyí tí ó wà fún ẹnu ọ̀nà àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà fún tabánákù àti èyí tí ó wà fún àyíká àgbàlá náà.
← Chapter 37
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 39 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40