bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 3
Exodus 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 4 →
1
Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mósè ń sọ́ agbo ẹran Jẹ́tírò baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Mídíánì. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jínjìn nínú ihà. Ó dé Hórébù, òkè Ọlọ́run.
2
Níbẹ̀ ni ańgẹ́lì OLÚWA ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́ iná ti ń jó láàrin igbó. Mósè rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run
3
Nígbà náà ni Mósè sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”
4
Nígbà tí OLÚWA rí i pe Mósè ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárin igbó náà, “Mósè! Mósè!!” Mósè sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nì yìí.”
5
Ọlọ́run sì wí fún Mósè pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.”
6
Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba yín, Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù.” Nítorí ìdí èyí, Mósè fi ojú rẹ̀ pamọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti wo ojú Ọlọ́run.
7
Ọlọ́run si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Éjíbítì, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára.
8
Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kénánì, Hétì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì.
9
Ǹjẹ́ nísinsìnyìí, wò ó, igbe àwọn ará Ísírẹ́lì ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Éjíbítì ti se ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà.
10
Ǹjẹ́ nísinsínyìí, lọ, Èmi yóò rán ọ sí Fáráò láti kó àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.”
11
Ṣùgbọ́n Mósè wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Fáráò lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì?”
12
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mósè pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé Èmi ni ó rán ọ lọ; Nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”
13
Mósè sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ̀ àwọn ará Ísírẹ́lì lọ ti mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?”
14
Ọlọ́run sì sọ fún Mósè pé, “ÈMI NI TI Ń JẸ́ ÈMI NI. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí i yín.’ ”
15
Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ‘OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísáákì àti Ọlọ́run Jákọ́bù; ti rán mi sí i yín.’ Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé, orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi láti ìran dé ìran.
16
“Lọ, kó àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì jọ, kí o sí sọ fún wọn, ‘OLÚWA Ọlọ́run Jákọ́bù; yọ sí mi, ó sì wí pé: Lóòótọ́ èmi ti ń bojúwò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Íjíbítì.
17
Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Éjíbítì wá sí ilẹ̀ Kénánì, Hítì, Ámórì, Pérésì, Hífì àti Jébúsì; ilẹ̀ tí ń sàn fún wàrà àti oyin.’
18
“Àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì yóò fetí sílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbààgbà yóò jọ tọ ọba Éjíbítì lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘OLÚWA, Ọlọ́run àwọn ará Hébérù ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú ihà láti lọ rú ẹbọ sí OLÚWA Ọlọ́run.’
19
Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Éjíbítì kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀.
20
Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Éjíbítì pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárin wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.
21
“Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Éjíbítì pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo.
22
Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun Sílífà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Éjíbítì.”
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40