bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 6
Exodus 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 7 →
1
Nígbà náà ní OLÚWA sọ fún Mósè pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Fáráò pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”
2
Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, “Èmi ni OLÚWA.
3
Mo fi ara hàn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù bí Ọlọ́run alágbára (Ẹ́lísàdáì) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi OLÚWA, Èmi kò fi ara mi hàn wọ́n.
4
Èmí sì tún fi idi májẹ̀mu mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kénánì, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjòjì.
5
Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn tí àwọn ará Éjíbítì mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mu mi.
6
“Sọ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì: ‘Èmi ni OLÚWA, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúró nínú àjàgà àwọn ará Éjíbítì. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúró ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá.
7
Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ̀ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúró nínú àjàgà àwọn ará Íjíbítí.
8
Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Ábúráhámù. Ísáákì àti Jákọ́bù. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, èmi ni OLÚWA.’ ”
9
Mósè sì sọ èyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mósè nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbékùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.
10
Nígbà náà ni OLÚWA sọ fún Mósè.
11
“Lọ, sọ fún Fáráò ọba Éjíbítì pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Ísírẹ́lì lọ kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”
12
Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún OLÚWA pé, “Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”
13
OLÚWA bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.
14
Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn: Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésúrónì àti Kámì. Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Rúbẹ́nì.
15
Àwọn ọmọ Ṣímóní ní Jémúẹ́lì, Jámì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọ obìnrin Kénánì. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Símónì.
16
Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn: Gésónì, Kóhábì àti Mérárì: Léfì lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.
17
Àwọn ọmọ Gésónì ni ìran wọn ni Líbínì àti Ṣímẹ́lì.
18
Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámírámù, Ísárì, Hébírónì àti Yúsíélì. Kóhátì lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.
19
Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Músíhì. Ìwọ̀nyí ni ìran Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.
20
Ámírámù sì fẹ́ Jókébédì arákùnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jókébédì sì bí Árónì àti Mósè fún un. Ámírámù lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.
21
Àwọn ọmọ Ísárì ni Kórà, Nẹ́fẹ́fì àti Ṣíkírì.
22
Àwọn ọmọ Yúṣíélì ni Míṣíháẹlì, Élíṣáfánì àti Ṣítíhírí.
23
Árónì fẹ́ Élíṣahẹ́ba ọmọbìnrin Ámínádábù tí í ṣe arábìnrin Náhísíhónì, ó sì bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.
24
Àwọn ọmọ Kórà ni Ásírì, Élíkánà àti Ábíásáfù, ìwọ̀nyí ni ìran Kórà.
25
Élíásárì ọmọ Árónì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Pútíẹ́lì ní ìyàwó, ó sì bí Fínéhásì fún un. Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Léfì ni ìdílé ìdílé.
26
Árónì àti Mósè yìí kan náà ni OLÚWA sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.”
27
Àwọn ni ó bá Fáráò ọba Éjíbítì sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni Éjíbítì, àní Mósè àti Árónì yìí kan náà ni.
28
Nígbà tí OLÚWA bá Mósè sọ̀rọ̀ ni Éjíbítì,
29
Ó ni “Èmi ni OLÚWA. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Fáráò ọba Éjíbítì.”
30
Ṣùgbọ́n Mósè sì wí ní iwájú OLÚWA pé, “Níwọ̀n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Fáráò yóò ṣe fi etí sí mi?”
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
Recommended Reading
Commentary
Exodus Commentaries
→
Devotional
Exodus Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→