bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 27
Exodus 27
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 28 →
1
“Ìwọ yóò sì kọ pẹpẹ igi kaṣíà kan, ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta ní gígùn; Kí ìhà rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin jẹ́ ìwọ̀n kan, ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní gíga àti ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún ní fífẹ̀.
2
Ìwọ yóò sìṣe ìwo orí ìgun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, kí àwọn ìwo náà àti pẹpẹ náà lè ṣe ọ̀kan, ìwọ yóò sì bo pẹpẹ náà pẹ̀lú idẹ.
3
Ìwọ yóò sìṣe abọ́ ìtẹ́dí rẹ láti máa gba eérú rẹ̀, àti ọkọ̀ rẹ̀, àwokòtò rẹ̀, àti fọ́ọ̀kì ẹran rẹ̀, àti àwo iná rẹ̀, gbogbo ohun èlò rẹ̀ ni ìwọ yóò fi idẹ ṣe.
4
Ìwọ yóò sí ṣe ni wẹ́wẹ́, ìṣẹ́ àwọ̀n idẹ, kí o sì ṣe òrùka idẹ sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìṣẹ́ àwọ̀n náà.
5
Gbé e sí abẹ́ igun pẹpẹ náà, kí ó lè dé ìdajì pẹpẹ náà.
6
Ìwọ yóò sí ṣe òpó igi kaṣíà fún pẹpẹ náà, kí o sì bò ó pẹ̀lú idẹ.
7
A ó sì bọ àwọn òpó náà ní òrùka, wọn yóò sì wà ní ìhà méjèèjì pẹpẹ nígbà tí a bá rù ú.
8
Ìwọ yóò síṣe pẹpẹ náà ni oníhò nínú. Ìwọ yóò sí ṣe wọ́n bí èyí tí a fi hàn ọ́ ní orí òkè.
9
“Ìwọ yóò sí ṣe àgbàlá fún àgọ́ náà. Ní ìhà gúsù gbọ́dọ̀ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ (mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta) ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́,
10
pẹ̀lú ogún (20) òpó àti ogún (20) ihò itẹ̀bọ̀ idẹ pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà, kí ó sì di àwọn òpó mú.
11
Kí ìhà àríwá náà jẹ́ mítà mẹ́rìndínláàdọ́ta ní gíga, kí ó sì ní aṣọ títa, pẹ̀lú ogun (20) òpó àti ogún ihò itẹ̀bọ̀ idẹ, pẹ̀lú ìkọ́ fàdákà tí ó sì di àwọn òpó mú.
12
“Ní ìhà ìwọ̀ oòrùn, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógún ní fífẹ̀, kí ó sì ní aṣọ títa pẹ̀lú òpó mẹ́wàá àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́wàá.
13
Ní ìhà ìlà oòrùn, sí ibi tí oòrùn tí ń jáde, àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́talélógun ní fífẹ̀,
14
Aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga ní yóò wà ní ìhà ẹnu ọ̀nà, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta,
15
Àti aṣọ títa ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀dógún ní gíga yóò wá ní ìhà kejì, pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́ta.
16
“Àti fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, pèṣè aṣọ títa, mítà mẹ́sàn-án ní gíga, ti aláró, elésèé àlùkò, ti òdòdó, àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe, pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́rin.
17
Gbogbo òpó ti ó wà ní àyíká àgbàlá náà ni a ó fi fàdákà ṣo pọ̀ àti ìkọ́, àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.
18
Àgbàlá náà yóò jẹ́ mítà mẹ́rìndìnláàdọ́ta (46 mítà) ni gíga àti mítà mẹ́talélógún (23 mítà) ní fífẹ̀, pẹ̀lú aṣọ títa ti ọ̀gbọ̀ olókùn mítà méjì ní gíga, àti pẹ̀lú ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ.
19
Gbogbo irú iṣẹ́ tí ó wà kí ó ṣe, papọ̀ pẹ̀lú gbogbo èèkàn àgọ́ náà àti fún tí àgbàlá náà, kí ó jẹ́ idẹ.
20
“Ìwọ yóò sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọn kí ó mú òróró ólífì dáradára tí a gún fún ọ wá, fún ìmọ́lẹ̀, kí fìtílà lè máa tàn ṣíbẹ̀.
21
Ní àgọ́ àjọ, lẹ́yìn òde láìsí aṣọ ìsélé tí ó wá níwájú ẹ̀rí náà, Árónì àti òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, ni yóò tọ́jú rẹ̀ lati alẹ́, títí di òwúrọ̀ níwájú OLÚWA: yóò sì di ìlànà láéláé ni ìrandíran wọn lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Isírẹ́lì.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40