bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 20
Exodus 20
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 21 →
1
OLÚWA sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé:
2
“Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde ni ilẹ̀ Éjíbítì, jáde ni oko ẹrú.
3
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.
4
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara rẹ ní àwòrán ohun kóhun tí ń bẹ ní òkè ọ̀run tàbí tí ń bẹ ní ayé, tàbí tí ń bẹ ní ìṣàlẹ̀ omi.
5
Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀sẹ̀ baba wò lára ọmọ láti ìran kìn-ín-ní títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi.
6
Ṣùgbọ́n mo ń fi ìfẹ́ hàn sí ẹgbẹ̀rún ìran nínú àwọn tí ó fẹ́ mi tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.
7
“Ìwọ kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLÚWA Ọlọ́run rẹ ní asán, nítorí OLÚWA kì yóò ka àwọn tí ó ń pe orúkọ rẹ̀ ní asán bí aláìlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀run.
8
“Rántí ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́.
9
Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,
10
Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi OLÚWA Ọlọ́run rẹ. Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kiṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkunrìn àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tó wà ní nínú ibodè rẹ.
11
Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni OLÚWA ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.
12
“Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ bá a le pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.
13
“Ìwọ kò gbọdọ̀ pa ènìyàn.
14
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.
15
“Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
16
“Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.
17
“Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí ilé aládùúgbò rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya aládùúgbò rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin tàbí sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti aládùúgbò rẹ.”
18
Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n sìgàsìgà fún ìbẹ̀rù.
19
Wọ́n wí fún Mósè pé, “Ìwọ fúnraàrẹ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnraarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”
20
Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe sẹ̀.”
21
Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mósè súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.
22
OLÚWA sì sọ fún Mósè pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnraayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá.
23
Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.
24
“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀.
25
Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a se lọ́sọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lorí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́.
26
Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’
← Chapter 19
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 21 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40