bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Exodus 31
Exodus 31
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 32 →
1
OLÚWA wí fún Mósè pé,
2
“Wò ó, èmi ti yan Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà,
3
Èmi sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.
4
Láti se aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ,
5
láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.
6
Ṣíwájú sí i, èmi ti yan Óhólíábù ọmọ Áhúsámákì, ti ẹ̀yà Dánì, láti ràn án lọ́wọ́. Bákan náà, èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́ ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo paṣẹ fún ọ:
7
Àgọ́ àjọ náà, àpótí ẹ̀rín pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀, àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,
8
tábìlì àti ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, pẹpẹ tùràrí,
9
pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀
10
àti aṣọ híhun pẹ̀lú, papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,
11
òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún ibi mímọ́. Kí wọ́n se wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe paṣẹ fún ọ.”
12
OLÚWA wí fún Mósè pé,
13
“Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ̀yín gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrin èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni OLÚWA, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.
14
“ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a óò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá se iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a óò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ.
15
Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún OLÚWA. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ.
16
Nítorí náà ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò se máa pa ọjọ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíràn tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mu títí láé.
17
Yóò jẹ́ àmí láàrin èmi àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni OLÚWA dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”
18
Nígbà tí OLÚWA parí ọ̀rọ̀ ṣíṣọ fún Mósè lórí òkè Ṣínáì, ó fún-un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, okuta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.
← Chapter 30
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 32 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40