bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 13
Ezekiel 13
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 14 →
1
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá pé:
2
“Ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tó ń sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn tí ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn: ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA!
3
Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Ègbé ni fún àwọn òmùgọ̀ wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkankan!
4
Ísirẹ́lì àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá.
5
Ẹ kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì kí wọ́n ba lè dúró gbọin lójú ogun lọ́jọ́ OLÚWA.
6
Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “OLÚWA wí” nígbà tí OLÚWA kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí OLÚWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.
7
Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ sọ pé, “OLÚWA wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?
8
“ ‘Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín: ni OLÚWA Ọlọ́run wí.
9
Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké. Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Ísírẹ́lì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin ó sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run.
10
“ ‘Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi sìnà, wọ́n ní, “Àlàáfíà” nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún,
11
nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ̀ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, N ó sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀.
12
Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn ò ní bi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?”
13
“ ‘Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Nínú ìbínú gbígbóná mi, èmi yóò tu afẹ́fẹ́ líle lée lórí nínú ìrunú mi, àti nínú ìbínú mi, òjò yóò sì rọ̀ púpọ̀ nínú ìbínú mi, àti yìnyín ńlá nínú ìrunú mi làti pa wọ́n run.
14
Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde. Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ ó sì mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.
15
Báyìí ni N ó ṣe lo ìbínú mi lórí odi yìí àti àwọn to fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi ẹfun kùn ún. N ó sì sọ fún yín pé, “Kò sí odi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó rẹ́ ẹ náà kò sí mọ́;
16
Àwọn wòlíì Ísírẹ́lì tí ń sọtẹ́lẹ̀ nípa àlàáfíà nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí.” ’
17
“Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojú kọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn
18
kí o sọ pé, ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálukú ènìyàn láti sọdẹ ọkàn wọn: Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi kí ẹ sì pa ọkàn yin mọ́?
19
Nítorí ẹ̀kúnwọ́ ọkà bàbà àti èérún oúnjẹ. Ẹ ti pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì fi àwọn tí kò yẹ kó wà láàyè sílẹ̀ nípa irọ́ tí ẹ ń pa fún àwọn ènìyàn mi, èyí tí àwọn náà ń fetí sí.
20
“ ‘Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Mo lòdì sí ìfúnpá òògùn tí ẹ fi ń ṣọdẹ ọkàn ènìyàn káàkiri bí ẹyẹ, Èmi yóò ya á kúrò lápá yín; Èmi yóò sì dá ọkàn àwọn ènìyàn tí ẹ ń ṣọdẹ sílẹ̀.
21
Èmi yóò ya àwọn ìbòjú yín, láti gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín, wọn kò sì ní jẹ́ ìjẹ fún yín mọ́. Nígbà náà ni ẹ ó mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA.
22
Nítorí pé ẹ ti ba ọkàn àwọn olódodo jẹ́ pẹ̀lú irọ́ yín, nígbà tí Èmi kò mú ìbànújẹ́ bá wọn, àti nítorí ẹ̀yin ti mú ọkàn àwọn ènìyàn búburú le, kí wọ́n má baà kúrò nínú ọ̀nà ibi wọn débi tí wọn yóò fi gba ẹ̀mí wọn là,
23
nítorí èyí, ẹ̀yin kò ní í ríran èké, ẹ̀yin kò sì ní fọ àfọ̀ṣẹ mọ́. Èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni OLÚWA.’ ”
← Chapter 12
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 14 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48