bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 28
Ezekiel 28
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 29 →
1
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tírè pé, ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè simi ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run; Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà ní àárin gbùngbùn òkun.” Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
3
Ìwọ gbọ́n ju Dáníẹ́lì lọ bí? Ṣé kò sí àsírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
4
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
5
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀ àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀, ọkàn rẹ gbé sókè Nitorí ọrọ̀ rẹ.
6
“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n, pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run
7
Èmi yóò mú kí àwọn àjòjì dìde sí ọ, ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀ èdè; wọn yóò yọ idà wọn sí ọ ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
8
Wọn yóò mú ọ sọ̀ kalẹ̀ wá sínú ihò ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná àwọn tí a pa ní àárin òkun.
9
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,” ní ojú àwọn tí ó pa ọ́? Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run, ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́
10
Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà ní ọwọ́ àwọn àjòjì Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní OLÚWA Ọlọ́run wí.’ ”
11
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé:
12
“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tírè kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹrẹ ìjẹ́pípé náà o kún fún ọgbọ́n, o sì pé ní ẹwà
13
Ìwọ ti wà ní Édẹ́nì, ọgbà Ọlọ́run; onírúurú òkúta iyebíye ni ìbora rẹ; sárídù, tópásì àti díámọ́ndì, bérílì oníkì, àti jásípérì, sáfírè, émérálídì àti káríbúnkílì, àti wúrà ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà láti ara wúrà, ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
14
A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù, torí èyí ni mo fi yàn ọ́. Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run; ìwọ rìn ni àárin òkúta amúbína,
15
Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ láti ọjọ́ tí a ti dá ọ títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
16
Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ ìwọ kún fún ìwà ipá; ìwọ sì dẹ́sẹ̀ Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run. Èmi sì pa ọ run, ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárin òkúta amúbínà
17
Ọkàn rẹ gbéraga nítorí ẹwà rẹ. Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí dídára rẹ. Nítorí náà mo le ọ sórí ayé; mo sọ ọ di awò ojú níwájú àwọn ọba.
18
Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìsòótọ́ rẹ ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́. Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run, èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀ lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
19
Gbogbo orílẹ̀ èdè tí ó mọ̀ ọ́ ní ẹnu ń yà sí ọ; ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù ìwọ kì yóò sì sí mọ́ láéláé.’ ”
20
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé:
21
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sídónì; kí o sì ṣọtẹ́lẹ̀ sí i
22
Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sídónì, a ó sì ṣe mí lógo láàárin rẹ. Wọn yóò, mọ̀ pé èmi ní OLÚWA, Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,
23
Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-àrùn sínú rẹ èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ ṣàn ní ìgboro rẹ ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárin rẹ pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni OLÚWA.
24
“ ‘Kì yóò sì sí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni OLÚWA Ọlọ́run.
25
“ ‘Èyí yìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Nígbà tí èmi yóò bá ṣa àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàárin wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkalára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jákọ́bù.
26
Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi sẹ sí ara àwọn tí ń ṣáátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run wọn.’ ”
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 29 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48