bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 42
Ezekiel 42
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 41
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 43 →
1
Lẹ́yìn náà ó mú mi lọ sí ìta gbangba ni ìhà àríwá ó sì mú mi wọ àwọn yàrá ni òdìkejì ìta gbangba ilé Ọlọ́run àti ni òdìkejì ogiri ìta ní apá ìhà àríwá.
2
Ilé tí ilèkùn rẹ̀ kọjú sí àríwá jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ó sì jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀.
3
Méjèèjì ní ogún ìgbọ̀nwọ́ ìpín láti inú ilé ìdájọ́ àti ni ìpín tí ó dojúkọ iwájú ìta ìdájọ́, ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè kọjú sì ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè ní ìdọ́gba mẹ́ta.
4
Ní iwájú àwọn ọ̀nà, yàrá wà nínú tí ó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní fífẹ̀ tí ó sì jẹ́ ọgọ́ọrùn ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn. Àwọn ilẹ̀kùn wọn wà ní apá ìhà àríwá.
5
Nísinsìn yìí àwọn yàrá òkè ṣe tóóró, nítorí ọ̀dẹ̀dẹ̀ lókè dàbí ẹni pé ó ní ààyè láti ara wọn ju láti ara àwọn yàrá ti ó wà ní ìsàlẹ̀ tàbí àárin ilé.
6
Àwọn yàrá tí ó wà ní àgbékà kẹta kò ni àwọn òpó gẹ́gẹ́ bí ilé ìdájọ́ ṣe ní; nítorí náà wọ́n kéré ni níní ààyè ju àwọn tí ó wà ní ìsàlẹ̀ àti àwọn àgbékà ti àárin.
7
Ògiri kan wà ní ìta tí ó ṣe déédé pẹ̀lú àwọn yàrá àti ìta ilé ìdájọ́; a fàá gùn ní iwájú àwọn yàrá ní àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́.
8
Nígbà tí ọ̀wọ́ yàrá ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kángun sí ìta ilé ìdájọ́ jẹ́ àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ọ̀wọ́ ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ tí ó sún mọ́ ibi mímọ́ jẹ́ ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn.
9
Yàrá ìsàlẹ̀ ni ẹnu ọ̀nà ní ìhà ìlà oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ṣe wọ inú rẹ̀ láti ìta ilé ìdájọ́.
10
Ní ìhà gúsù lọ sí ìbú ògiri ìta ilé ìdájọ́ tí o ṣe déédé pẹ̀lú àgbàlá ilé Ọlọ́run, ní òdìkejì ògiri ìta ni àwọn yàrá náà wà.
11
Àti ọ̀nà ni iwájú wọn rí gẹ́gẹ́ bí ti ìrí àwọn yàrá tí ó wà ní ọ̀nà àríwá bí wọ́n ti gùn mọ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbòòrò mọ àti gbogbo ìjáde wọn sì dàbí ìṣe wọn àti bí ìlẹ̀kùn wọn
12
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní yàrá tí òun ti ìlẹ̀kùn wọn ní ọ̀nà gúsù, ìlẹ̀kùn kan wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ojú ọ̀nà tí ó ṣe déédé pẹ̀lú ògiri tí ó gùn dé ìhà ìlà oòrùn tí ènìyàn ń gba wọ inú àwọn yàrá.
13
Ó sì wí fún mi pé, “Àwọn yàrá àríwá àti àwọn yàrá gúsù, tí ó wà níwájú ibi tí a yà sọ́tọ̀ àwọn ni yàrá mímọ́, níbi tí àwọn àlùfáà ti ń súnmọ́ OLÚWA yó máa jẹ́ ohun mímọ́ jùlọ; níbẹ̀ ní wọn o máa gbé ohun mímọ́ jùlọ kà, àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti ọrẹ ẹbọ ìrékọjá; nítorí ibẹ̀ jẹ́ mímọ́
14
Ní wọ̀n ìgbà tí àwọn àlùfáà bá ti wọ aṣọ funfun ibi mímọ́, wọn kò gbọdọ̀ lọ sí ìta ilé ìdájọ́ àfi tí wọ́n bá bọ àwọn aṣọ tí wọ́n fi ṣiṣẹ́ ìsin sílẹ̀ ní ibi tí wọn tí lò ó, nítorí wọ́n jẹ́ mímọ́. Wọn gbọdọ̀ wọ aṣọ mìíràn kí wọn tó sún mọ́ ibi tí àwọn ènìyàn yòókù máa ń wà.”
15
Nígbà tí o parí nǹkan tí ó wà nínú ilé Ọlọ́run tán, o mú mi jáde lọ sí ọ̀nà tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn, ó sì wọn agbégbé náà yípo:
16
Ó wọn ìhà ìlà oòrùn pẹ̀lú ọ̀pá ìwọ̀n ǹnkan; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́.
17
Ó wọn ìhà àríwá; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá ìwọn nǹkan.
18
O wọn ìhà gúsù; ó jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pá wíwọ̀n nǹkan.
19
Lẹ́yìn èyí ni ó wà yí padà sí ìhà ìwọ̀ oòrùn o sì wọ̀n ọ́n: ó sì jẹ́ ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ pẹ̀lú ọ̀pa wíwọ̀n.
20
Báyìí ní ó wọn agbégbé ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ó ní ògiri kan yípo rẹ̀, ọgọ́rùn-ún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀, àti ọgọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, láti ya ibi mímọ́ sọ́tọ̀ kúrò ní ibi tí gbogbo ènìyàn ń lọ sọ́tọ̀.
← Chapter 41
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 43 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48