bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 37
Ezekiel 37
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 36
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 38 →
1
Ọwọ́ OLÚWA wà lára mi, ó sì mú mi jáde pẹ̀lú ẹ̀mí OLÚWA, ó mú kí ń wà ní àárin àfonífojì; ti o kún fún àwọn egungun.
2
Ó mú mi lọ síwájú àti sẹ́yìn láàrin wọn, èmi sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn egungun ní orí ilẹ̀ àfonífojì, àwọn egungun tí ó gbẹ gan.
3
OLÚWA sì bi mí léèrè, “Ọmọ ènìyàn, ǹjẹ́ àwọn egungun wọ̀nyí lè yípadà di àwọn ènìyàn bí?” Èmi sì wí pé, “Ìwọ OLÚWA àwọn ọmọ-ogun, ìwọ nìkan ni o lè dáhùn sí ìbéèrè yìí.”
4
Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Ṣọtẹ́lẹ̀ sí àwọn egungun kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin egungun gbígbẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA!
5
Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí fún àwọn egungun wọ̀nyí: Èmi yóò mú kí èémí wọ inú yín ẹ̀yin yóò sì wá di ààyè.
6
Èmi yóò so ìṣan ara mọ́ ọn yín, èmi yóò sì mú kí ẹran ara wá sí ara yín, èmi yóò sì fi awọ ara bò yín: Èmi yóò sì fi èémí sínú yín, ẹ̀yin yóò sì wà ní ààyè. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA.’ ”
7
Nítorí náà ni mo ṣe ṣọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti pa á láṣẹ fún mi. Bí mo sì ti ń ṣọtẹ́lẹ̀, ariwo wá, ìró tí ó kígbe sókè, àwọn egungun sì wà papọ̀, egungun sí egungun.
8
Mo wò ó, ìṣan ara àti ẹran ara farahàn lára wọn, awọ ara sì bò wọ́n, ṣùgbọ́n kò sí èémí nínú wọn.
9
Lẹ́yìn náà ni ó ṣọ fún mi pé, “Ṣọtẹ́lẹ̀ sí èémí; ṣọtẹ́lẹ̀, ọmọ ènìyàn, kí ó sì ṣọ fún un pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: wá láti atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìwọ èémí, kí ó sì mí èémí sínú àwọn tí a pa wọ̀nyí, kí wọn kí ó lè wà ní ààyè.’ ”
10
Nítorí náà, mo ṣọtẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe pa á láṣẹ fún mi, èémí sì wọ inú wọn; Wọ́n di alààyè, wọ́n sì dìde dúró lórí ẹṣẹ̀ wọn—pẹ̀lú ìhámọ́ra tí ó pọ̀.
11
Lẹ́yìn náà ó ṣọ fún mi: “Ọmọ ènìyàn, àwọn egungun wọ̀nyí ni gbogbo ìdílé Ísírẹ́lì. Wọ́n ṣọ wí pé, ‘Egungun wa ti gbẹ ìrètí wa sì ti lọ; a ti gé wa kúrò.’
12
Nítorí náà ṣọtẹ́lẹ̀, kí o sì ṣọ fun wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun sọ: Ẹ̀yin ènìyàn mi, Èmi yóò sí àwọn ibojì yín, èmi yóò sì mú yín wá si ilẹ̀ Isírẹ́lì.
13
Ẹ̀yin o sì mọ̀ èmi ni OLÚWA, nígbà tí èmi bá ti sí bojì yín, ẹ̀yin ènìyàn mi, ti èmi bá si mú un yín dìde kúrò nińú bojì yín
14
Èmi yóò fi èémí mi sínú yín, ẹ̀yin yóò sì yè, èmi yóò sì mú kí ẹ fi lélẹ̀ ní ilẹ̀ ẹ̀yín tìkára yín. Nígbà náà ẹ̀yin yóò mọ̀ pé OLÚWA ti ṣọ̀rọ̀, èmi sì ti ṣe ni OLÚWA wí.’ ”
15
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mi wá:
16
“Ọmọ ènìyàn, mú igi pátakó kan kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Tí ó jẹ́ ti Júdà àti ti Ísírẹ́lì tí ó ní àsṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’ Lẹ́yìn náà, kí ó mú igi pátakó mìíràn kí ó sì kọ̀wé sí ara rẹ̀, ‘Igi tí Éfúraímù jẹ́ ti Jósẹ́fù àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì tí ó ni àṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.’
17
So wọ́n papọ̀ sí ara igi kan nítorí náà wọn yóò di ọ̀kan ní ọwọ́ rẹ.
18
“Nígbà tí àwọn ara ìlú rẹ bá béèrè lọ́wọ́ rẹ pé, ‘Ṣé ìwọ kò ní sọ ohun tí èyí túmọ̀ sí fún wa?’
19
Ṣọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò gba igi Jósẹ́fù—èyí tí ó wà ní ọwọ́ Éfúráímù—àti ti ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí ó parapọ̀ mọ́ ọn, kí ó sì só papọ̀ mọ́ igi Júdà, láti sọ wọ́n di igi kan ṣoṣo, wọn yóò sì di ọ̀kan ní ọwọ́ mi.’
20
Gbé igi pátakó tí ó kọ nǹkan síi sókè ní iwájú wọn,
21
kí ó sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí yìí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Èmi yóò mú Ísírẹ́lì jáde kúrò ní àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n ti lọ. Èmi yóò ṣà wọ́n jọ pọ̀ láti gbogbo agbègbè, èmi yóò sì mú wọn padà sí ilẹ̀ ara wọn.
22
Èmi yóò ṣe wọ́n ní orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ náà, ní orí òkè Ísírẹ́lì, Ọba kan ni yóò wà lórí gbogbo wọn, wọn kì yóò sì jẹ́ orílẹ̀ èdè méjì mọ́, tàbí kí a pín wọn sí ìjọba méjì.
23
Wọn kì yóò sì tún fi àwọn òrìṣà wọn ba ara wọn jẹ́ mọ́, tàbí ohun ìríra wọn, tàbí ohun ìrékọjá wọn: ṣùgbọ́n èmi yóò gbà wọn là kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àgàbàgebè wọn, èmi yóò sì wẹ̀ wọn mọ́. Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn.
24
“ ‘Dáfídì ìránṣẹ́ mi ni yóò jẹ Ọba lórí wọn, gbogbo wọn yóò sì ní olùṣọ àgùntàn kan. Wọn yóò sì tẹ̀lé òfin mi, wọn yóò sì ṣe àníyàn láti pa àṣẹ mi mọ́.
25
Wọn yóò gbé ní ilẹ̀ tí mo fún Jákọ́bù ìránṣẹ́ mi, ilẹ̀ tí àwọn baba yín ń gbé. Àwọn àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ọmọ ọmọ wọn ni yóò máa gbé ibẹ̀ láéláé, Ìránṣẹ́ mi Dáfídì ni yóò jẹ́ ọmọ Aládé wọn láéláé.
26
Èmi yóò dá májẹ̀mu àlàáfíà pẹ̀lú wọn, yóò sì jẹ́ májẹ̀mu títí ayérayé. Èmi yóò gbé wọn kalẹ̀, èmi yóò sì ṣọ wọ́n di púpọ̀ ní iye, èmi yóò sì gbé ilé mímọ́ mi kalẹ̀ ní àárin wọn títí láé.
27
Ibùgbé mí yóò wà pẹ̀lú wọn, Èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.
28
Nígbà náà ni àwọn orílẹ̀ èdè yóò mọ̀ pé, èmi OLÚWA ṣọ Ísírẹ́lì di mímọ́, nígbà tí ibi mímọ́ mi bá wà ní àárin wọn títí ayérayé.’ ”
← Chapter 36
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 38 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48