bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 18
Ezekiel 18
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 19 →
1
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tún tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Kín ni ẹ̀yín rò tí ẹ̀yin fi ń pa òwe nípa Ísírẹ́lì wí pé: “ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà kíkan, eyín àwọn ọmọ sì kan.’
3
“Bí mo ti wà láàyè ni OLÚWA Ọlọ́run wí, ẹ̀yin kó ni i pa òwe yìí mọ́ ni Ísírẹ́lì.
4
Nítorí pé èmi ló ní gbogbo ọkàn, ọkàn baba tèmi bẹ́ẹ̀ ni ọkàn ọmọ pàápá jẹ tèmi, ọkàn tó bá sẹ̀ ní yóò kú.
5
“Bí ọkùnrin Olódodo kan bá wà, tó ń ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ
6
tí kò bá wọn jẹun lórí òkè gíga, tí kò gbójú rẹ̀ sókè sí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ti kò sì bá obìnrin aládùúgbò rẹ̀ jẹ́ tàbí kí ó sùn ti obìnrin ni àsìkò èérí rẹ̀.
7
Kò ní ẹnikẹ́ni lára, ó sì sanwó fún onígbésè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe ìlérí fún un, kò fi ipá jalè ṣùgbọ́n ó fún ẹni tí ebi ń pa ní oúnjẹ, tí ó sì fi ẹ̀wù wọ àwọn tí ó wà ní ìhòòhò.
8
Kò yá ènìyàn ni owó ẹ̀dá tàbí kò gba èlé tó pọ̀jù. Ó yọ ọwọ́ rẹ̀ kúrò nínú ìwà ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ àìṣègbè láàrin ọkùnrin kan àti èkejì rẹ̀.
9
Tí ó ń tẹ̀lé àsẹ mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́ lotítọ́ àti lódodo. Ó jẹ́ olódodo, yóò yè nítòótọ́, ní OLÚWA Ọlọ́run wí.
10
“Bí ó bá bi ọmọkùnrin, oniwà ipá, tó ń jalè, tó tún ń pànìyàn tó sì ń ṣe gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí sí arákùnrin rẹ̀
11
(bó tilẹ̀ jẹ́ pé baba rẹ kò se irú rẹ̀): “Ó ń jẹun lojúbọ lórí òkè gíga, o ba ìyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́.
12
Ó ni àwọn talákà àti aláìní lára, ó ń fipá jalè, kì í dá padà gẹ́gẹ́ bí ìlérí, o gbójú sókè sí òrìṣà, ó sì ń ṣe ohun ìríra.
13
Ó ń fowó ya ni pẹ̀lú èlé ó sì tún ń gba èlé tó pọ̀jù. Ǹjẹ́ irú ọkunrin yìí wa le è yè bí? Kò lè wá láàyè! Nítorí pé ó ti ṣe àwọn ohun ìríra yìí, yóò kú, ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò sì wá lórí rẹ̀.
14
“Bí ọkùnrin yìí bá bímọ, tó sì rí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti baba rẹ ń ṣẹ̀ yìí, tó sì bẹ̀rù, ti kò ṣe bẹ́ẹ̀:
15
“Tí kò jẹun lójúbọ lórí òkè gíga tàbí kò gbójú sókè sí àwọn òrìṣà ilé Ísírẹ́lì, tí kò sì bá iyàwó aládùúgbò rẹ̀ jẹ́
16
tí kò ni ẹnikẹ́ni lára, tí kò hùwà ibi tí kò gba èlé tàbí kò fipá jalè ṣùgbọ́n tí ó ń fún ẹni tébi ń pa lóúnjẹ, tó sì fi aṣọ bo àwọn oníhòhò.
17
Ó ń yọ ọwọ́ rẹ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kò sì gba èlé tàbí èlé tó pọ̀jù, ó ń pa òfin mi mọ́, ó sì ń tẹ̀lé àwọn àsẹ mi. Kò ní kú fún ẹ̀ṣẹ̀ baba rẹ̀, nítòótọ́ ní yóò yè!
18
Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀, nítorí pé ó jẹ́ arẹ́nijẹ, ó jalè arákùnrin rẹ, ó ṣe ohun tí kò dára láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
19
“Síbẹ̀, ẹ tún ń bèèrè pé, ‘Kí ló dé ti ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀?’ Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ ti ṣe ohun tó tọ́, tó sì yẹ, tó sì ti kíyè sí ara láti pa gbogbo àṣẹ mi mọ́, nítòótọ́ ni pé yóò yè.
20
Ọkàn tí ó bá sẹ̀ ní yóò kú. Ọmọ kò ní í ru ẹ̀bi baba rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni baba náà kò ní i ru ẹ̀bi ọmọ rẹ̀. Ìwà rere ènìyàn rere yóò wà lórí rẹ̀, ìwà búburú ti ènìyàn búburu náà la ó kà síi lọ́rùn.
21
“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tó ti dá, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa àsẹ mi mọ́, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, nítòótọ́ ni yóò yè, kò sì ní kú.
22
A kò sì ní rántí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó ti dá tẹ́lẹ̀ láti kàá sí lọ́rùn nítorí tí ìwà òdodo rẹ tó fihàn, yóò yè
23
Ǹjẹ́ se mo ni inú dídùn si ikú ènìyàn búburú bí í? Ní OLÚWA wí, dípò èyí inú mi kò ha ni i dùn nígbà tó ba yípadà kúrò ni àwọn ọ̀nà búburú rẹ̀ tó sì yè?
24
“Ṣùgbọ́n bí ènìyàn rere bá yípadà kúrò ni ọ̀nà òdodo rẹ̀ tó sì ń dẹ́sẹ̀, tó sì tún n ṣe àwọn ohun ìríra tí ènìyàn búburú ń ṣe, yóò wa yè bí? A kò ni i rántí ọ̀kan kan nínú ìwà rere rẹ̀ mọ́, nítorí ó ti jẹ̀bi ìwà àrékérekè àti ẹ̀ṣẹ̀ tó dá, yóò sì kú.
25
“Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ tún sọ pe, ‘OLÚWA kò ṣe é da kò tọ́.’ Gbọ́, ilé Ísírẹ́lì: se ọ̀nà mi ni kò tọ́? Kì í wa ṣé pé ọ̀nà ti yín gan-an ni kò tọ́?
26
Bí ènìyàn rere ba yípadà kúrò nínú ìwà rere rẹ̀, tó sì dẹ́sẹ̀, yóò ku fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, yóò kú nítorí ẹsẹ tó ti dá.
27
Ṣùgbọ́n bi ènìyàn búburú bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú tó ti se, tó si ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, yóò gba ẹ̀mi rẹ̀ là.
28
Nítorí pé ó ronu lórí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá, ó sì yípadà kúrò nínú wọn, nítootọ́ ni yóò yè; kò sí ní i kú
29
Síbẹ̀, ilé Ísírẹ́lì wí pé, ‘Ọ̀nà OLÚWA kò tọ́.’ Ọ̀nà mi kò ha tọ́ bí Ilé Ísírẹ́lì? Kì í wa se pè ọ̀nà tiyín gan an ni ko tọ?
30
“Nítorí náà, ilé Ísírẹ́lì, n ó da yín lẹ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ẹnì kọ̀ọ̀kan yín bá ṣe rí ni OLÚWA Ọlọ́run wí. Yípadà! Kí ẹ si yí kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ̀ṣẹ̀ ma ba a jẹ́ ọ̀nà ìsubú yín.
31
Ẹ kọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ ti dá sílẹ̀, kí ẹ sì gba ọkàn àti ẹ̀mi tuntun. Nitori kí ló fi máa kú, ilé Ísírẹ́lì?
32
Nítorí pé inú mi kò dùn sí ikú ẹnikẹ́ni ni OLÚWA Ọlọ́run wí. Nítorí náà, ẹ yípadà kí ẹ sì yè!
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 19 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48