bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 5
Ezekiel 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 6 →
1
“Báyìí, ọmọ ènìyàn, mú ìdá tí ó mú kí o sì fi se abẹ ìfárí onígbàjámọ̀, kí o fi fá irun orí àti irùngbọ̀n rẹ. Fi irun yìí sórí ìwọ̀n kí o sì pín in.
2
Nígbà tí ọjọ́ ìgbóguntì bá parí, sun ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta ìrun yìí níná láàrin ìlú. Mú ìdá kan nínú mẹ́ta kí o fi idà bù ú káàkiri ìlú. Kí o sì tú ìdá kan yóòkù ká sínú afẹ́fẹ́. Nítorí pé pẹ̀lú idà ni èmi yóò máa lé wọn ká.
3
Ṣùgbọ́n mú díẹ̀ nínú irun yìí kí o sì ta á mọ́ etí aṣọ rẹ.
4
Tún ju díẹ̀ nínú irun yìí sínú iná, kí o sun ún níná. Torí pé láti ibẹ̀ ni iná yóò ti jáde lọ sí gbogbo ilé Ísírẹ́lì.
5
“Báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Èyí ní Jérúsálẹ́mù, tí mo gbé kalẹ̀ sí àárin àwọn orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ìlú gbogbo tí o yí i ká.
6
Síbẹ̀ nínú ìwà búburú rẹ̀ ó ti ṣọ̀tẹ̀ si òfin àti ìlànà mi ju àwọn orílẹ̀ èdè àti àwọn ilẹ̀ tó yí i ká lọ. Ó ti kọ òfin mi sílẹ̀, kò sì pa ìlànà mi mọ́.
7
“Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Nítorí pé o ti ṣe àìgbọ́ràn ju àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká lọ, tí o kò sì tẹ̀lé ìlànà mi tàbí kí o pa òfin mi mọ́. O kò tilẹ̀ tún ṣe dáadáa tó àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.
8
“Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: Èmi gan an lòdì sí ọ, Jérúsálẹ́mù, n ó sì jẹ ọ́ níyà lójú àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká.
9
Nítorí ìwà ìbọ̀rìṣà rẹ, n ó ṣe ohun tí n kò tí ì ṣe rí láàrin rẹ àti èyí tí n kò ní í ṣe irú rẹ̀ mọ́.
10
Nítorí náà láàrin rẹ àwọn baba yóò má a jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ náà yóò máa jẹ baba wọn. N ó jẹ ọ́ níyà, n ó sì tú àwọn tó bá ṣẹ́kù ká sínú èfúùfù.
11
Nítorí náà, OLÚWA Ọlọ́run wí pé, bí mo ṣe wà láàyè, nítorí pé o ti sọ ibi mímọ́ mi di àìmọ́ pẹ̀lú àwọn àwòrán ẹ̀gbin àti àwọn ohun ìríra rẹ, n ó mú ojú rere mi kúrò lára rẹ n kò ní í da ọ sí tàbí wò ọ́ pẹ̀lú àánú mọ́.
12
Ìdá mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn rẹ yóò kú nípa àjàkálẹ̀-àrùn tàbí kí ìyàn run wọ́n: ìdá mẹ́ta yóò ṣubú nípa idà lẹ́yìn odi rẹ n ó sì tú ìdá mẹ́ta yóòkù ká sínú èfúùfù, a ó sì máa fi idà lé wọn.
13
“Ìbínú mi yóò sì dúró, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú gbígbónná mi yóò sì rolẹ̀, n ó sì ti gba ẹ̀san mi. Nígbà tí mo bá sì parí ìbínú mi lórí wọn, wọn ó mọ̀ pé Èmi OLÚWA ti sọ̀rọ̀ nínú ìtara mi.
14
“Èmi yóò fi ọ́ ṣòfò, ó sì sọ ọ́ di ẹ̀gàn fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká, àti lójú àwọn tó ń kọjá
15
O ó wá di ẹ̀gàn, ẹ̀sín àti ikílọ àti ohun ẹ̀rù àti ìyanu fún àwọn orílẹ̀ èdè tó yí ọ ká nígbà tí mo bá fìyà jẹ ọ́ nínú ìbínú àti nínú ìbínú gbígbóná mi. Èmi OLÚWA ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
16
Nígbà tí mo bá ta ọfà ikú àti ìparun pẹ̀lú ìyàn, n ó ta á láti run ọ́ ni. N ó gé ìpèsè oúnjẹ kúrò, n ó sì mú ìyàn wá lọ́pọ̀lọpọ̀.
17
Èmi yóò rán ìyàn àti ẹranko búburú sí i yín, wọn yóò fi yín sílẹ ni àìlọ́mọ. Àjàkálẹ̀ àrùn àti ìtàjẹ̀-sílẹ̀ yóò kọjá láàrin yín. Èmi yóò si mú idà wá sórí rẹ. Èmi OLÚWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48