bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 24
Ezekiel 24
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 25 →
1
Ní ọdún kẹsàn án, oṣù kẹwàá, ọjọ́ kẹwàá, ni ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé:
2
“Ọmọ ènìyàn, kọ ọjọ́ náà sílẹ̀, ọjọ́ náà gan an, nítorí Ọba Bábílónì náà ti dojúti Jérúsálẹ́mù ní ọjọ́ yìí gan an.
3
Sì pa òwe yìí fún ilé ọlọ́tẹ̀ náà, sọ fún wọn pé: ‘Èyí yìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Gbé ìkòkò ìdáná náà ka iná: Gbé e kaná kí o sì da omi sí i nínú.
4
Kó àwọn ègé ẹran tí a gé náà sínú rẹ̀, gbogbo àwọn ègé ẹran tí ó tóbi, itan àti apá. Kó àwọn egungun tí ó dára jù sínú rẹ̀
5
Mú àwọn tí ó jọjú nínú agbo ẹran. Kó àwọn egungun sí abẹ́ ẹ rẹ̀; sì jẹ́ kí ó hó dára dára sì jẹ́ kí àwọn egungun náà bọ̀ nínú rẹ̀.
6
“ ‘Nítorí báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà, fún ìkòkò náà tí èrúru wà nínú rẹ̀ tí èrúru kò dà kúrò lójú rẹ̀! Mú ẹran náà jáde ní ekìrí ekìrí má ṣe ṣà wọ́n mú.
7
“ ‘Nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ wà ní àárin rẹ̀; o dà á sí orí àpáta kan lásán kò dà á sí orí ilẹ̀, níbi ti erùpẹ̀ yóò ti bò ó
8
Láti bá à le jẹ́ kí ìbínú kí ó dé láti gbẹ̀san mo da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí orí àpáta kan lásán, kí o ma bà á wà ni bíbò.
9
“ ‘Nítorí náà báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run wí: “ ‘Ègbé ni fún ìlú ẹlẹ́jẹ̀ náà! Èmi pàápàá yóò jẹ́ kí òkítì iná náà tóbi.
10
Nítorí náà kó igi náà jọ sí i, kí o sì fi iná sí i. Ṣe ẹran náà dáadáa, fi tùràrí dùn ún; ki o sì jẹ́ kí egungun náà jóná
11
Lẹ́yìn náà gbé òfìfo ìkòkò náà lórí ẹyin iná kí idẹ rẹ̀ lè gbóná, kí ó lè pọ́n àti ki èérí rẹ̀ le di yíyọ́ nínú rẹ̀ kí èrúrú rẹ̀ le jó dànù
12
Ó ti fi èké dá ara rẹ̀ lágara: èrúrú rẹ̀ kò sì jáde kúrò lára rẹ̀, èrúrú náà gan an yóò wà nínú iná.
13
“ ‘Nísìn yìí èérí rẹ̀ ni ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wà. Nítorí mo gbìyànjú láti wẹ̀ ọ́ mọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò sì mọ́ kúrò nínú ìwa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ, a kì yóò sì tún wẹ̀ ọ mọ́ kúrò nínú èèrí rẹ, títí èmi yóò fi jẹ́ kí ìbínú mi balẹ̀ sórí rẹ̀.
14
“ ‘Èmi OLÚWA ni ó sọ ọ́, yóò sì ṣe, èmi yóò sì ṣe é. Èmi kì yóò pada sẹ́yìn; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá sí i, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọkàn mi padà; gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ, ni wọn yóò dá ọ lẹ́jọ́, ni OLÚWA Ọlọ́run wí.’ ”
15
Ọ̀rọ̀ OLÚWA sì tọ̀ mí wá pé:
16
“Ọmọ ènìyàn, kíyèsí i, mo mú ìfẹ́ ojú rẹ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ, nípa lílù kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ gbààwẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sunkún, bẹ́ẹ̀ ni omijé ojú rẹ kò gbọdọ̀ kán sílẹ̀.
17
Má ṣe sunkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ: má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”
18
Báyìí ni mo sọ̀rọ̀ fún àwọn ènìyàn ní òwúrọ̀, ní àṣálẹ́ ìyàwó mi sì kú. Ní òwúrọ́ ọjọ́ kejì, mo ṣe bí a ti pàsẹ fún mi.
19
Lẹ́yìn náà àwọn ènìyàn bi mí léèrè pé, “Ṣe o kò ni sọ fún wa ohun ti nǹkan wọ̀nyí ní láti ṣe pẹ̀lú wa?”
20
Mo sọ báyìí fún wọn pé, “Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá wí pé:
21
Sọ fún ilé Ísírẹ́lì, ‘Báyìí ní OLÚWA Ọlọ́run wí: Kíyèsí i, èmi yóò sọ ibi mímọ́ mi di ibi àìmọ́ títayọ agbára yín, ìfẹ́ ojú yín, ìkáànú yín, àti ọmọ yín ọkùnrin àti àwọn ọmọ yín obìnrin tí ẹ̀yin fi sílẹ̀ sẹ́yìn yóò ṣubú nípa idà.
22
Ẹyin yóò sì ṣe bí mo ti ṣe. Ẹ̀yin kì yóò bo ìsàlẹ̀ ojú yín tàbí jẹ oúnjẹ ti àwọn tí ń sọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.
23
Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí i yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò sọ̀fọ̀ tàbí sunkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedédé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrin ara yín.
24
Ísíkẹ́ẹ̀lì yóò jẹ àmì fún un yín; ẹ̀yin yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Nígbà tí èyí bá sẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLÚWA Ọlọ́run.’
25
“Pẹ̀lúpẹ̀lù ìwọ, Ọmọ ènìyàn, kì yóò ha jẹ́ pé, ní ọjọ́ náà, nígbà ti mo bá gba agbára wọn, ayọ̀ wọn àti ògo wọn, ìfẹ́ ojú wọn, ohun tí wọn gbé ọkàn wọn lé, àti àwọn ọmọ ọkùnrin wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ obìnrin wọn kúrò lọ́dọ̀ wọn,
26
ní ọjọ́ náà ẹni tí ó bá sálà yóò tọ̀ ọ́ wá láti sọ ìròyìn náà fún ọ
27
Ní ọjọ́ náà ẹnu rẹ yóò sì sí; ìwọ yóò sọ̀rọ̀, ìwọ kì yóò sì yadi mọ́. Báyìí ìwọ yóò jẹ́ àmì fún wọn; wọn yóò sì mọ̀ pé èmi ní OLÚWA.”
← Chapter 23
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 25 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48