bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Ezekiel 21
Ezekiel 21
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 22 →
1
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọ mi wá:
2
“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú rẹ sí ìhà Jérúsálẹ́mù, kí o sí wàásù lòdì sí ibi mímọ́. Sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí ilẹ Ísírẹ́lì.
3
Kí ó sì sọ fún un: ‘Èyí yìí ni OLÚWA sọ: Èmi lòdì sí ọ. Èmi yóò fa idà mi yọ kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀, Èmi yóò sì ké olódodo àti ènìyàn búburú kúrò ni àárin yín.
4
Nítorí pé, èmi yóò ké olódodo àti olùṣe búburú kúrò, idà mi yóò jáde láti inú àkọ̀ rẹ̀ lòdì sí gbogbo ènìyàn láti gúsù títí dé àríwá.
5
Nígbà náà gbogbo ènìyàn yóò mọ̀ pé èmi OLÚWA ti yọ idà mi kúrò nínú àkọ̀ rẹ̀; kì yóò sì padà sínú rẹ̀ mọ́.’
6
“Nítorí náà, mí ìmí ẹ̀dùn ìwọ ọmọ ènìyàn! Mi ìmí ẹ̀dùn pẹ̀lú ọkàn ìbànújẹ́ àti ẹ̀dùn ọkàn kíkorò ní iwájú wọn.
7
Bí wọ́n bá sì bi ọ́, wí pé, ‘Kí ni ó dé tí ìwọ fi ń mi ìmí ẹ̀dùn?’ Ìwọ yóò wí pé, ‘Nítorí ìròyìn tí ó ń bẹ. Gbogbo ọkàn ni yóò yọ́, gbogbo ọwọ́ ni yóò sì di aláìlera; gbogbo ọkàn ní yóò dákú, gbogbo eékún ni yóò sì di aláìlera bí omi?’ Ó ń bọ̀! Yóò sì wa sí ìmúṣẹ dandan, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”
8
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ̀ mí wá:
9
“Ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ wí pé, Èyí yìí ní OLÚWA wí: “ ‘Ìdá kan, Ìdá kan, tí a pọ́n tí a sì kùn
10
a ti pọ́n fún pípa, a sì dan an kí ó lè máa kọ bí mọ̀nàmọ́ná! “ ‘Àwa yóò ha si ọ̀pá aládé ọmọ mi Júdà? Idà kẹ́gàn gbogbo ọ̀pá.
11
“ ‘Idà ní a yàn láti pọ́n, kí ó lè ṣe é gbá mú; a pọ́n ọn a sì dan án, ó ṣetán fún ọwọ́ àwọn apani.
12
Sunkún síta, kí ó sì pohùnréré ẹ̀kún, ọmọ ènìyàn, nítorí yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi; yóò wá sórí gbogbo ọmọ aládé Ísírẹ́lì ìbẹ̀rù ńlá yóò wá sórí àwọn ènìyàn mi nítorí idà náà; nítorí náà lu oókan àyà rẹ.
13
“ ‘Ìdánwò yóò dé dandan. Tí ọ̀pá aládé Júdà èyí tí idà kẹ́gàn, kò bá tẹ ṣíwájú mọ́ ńkọ́? Ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.’
14
“Nítorí náà, ọmọ ènìyàn, sọ tẹ́lẹ̀ kí ó sì fí ọwọ́ lu ọwọ́ Jẹ́ kí idà lu ara wọn lẹ́ẹ̀méjì, kódà ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta. Ó jẹ́ idà fún ìpànìyàn idà fún ìpànìyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ Tí yóò sé wọn mọ́ níhìnín àti lọ́hùnnún.
15
Kí ọkàn kí ó lè yọ́ kí àwọn tí ó ṣubú le pọ̀, mo ti gbé idà sí gbogbo bodè fún ìparun Áà! A mú kí ó kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná, a gbá a mú fún ìparun.
16
Ìwọ idà, jà sí ọ̀tún kí o sì jà sí òsì lọ ibikíbi tí ẹnu rẹ bá dojúkọ
17
Èmi gan an yóò pàtẹ́wọ́ ìbínú mi yóò sì rẹlẹ̀ Èmi OLÚWA ti sọ̀rọ̀.”
18
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ mi wá:
19
“Ọmọ ènìyàn la ọ̀nà méjì fín idà ọba Bábílónì láti gbà, kí méjèèjì bẹ̀rẹ̀ láti ìlú kan náà. Ṣe àmì sí ìkòríta ọ̀nà tí ó lọ sí ìlú náà.
20
La ọ̀nà kan fún idà láti wá kọ lu Rábà ti àwọn ará Ámónì kí òmíràn kọ lu Júdà, kí ó sì kọ lu Jérúsálẹ́mù ìlú olódi.
21
Nítorí ọba Bábílónì yóò dúró ni ìyànà ní ojú ọ̀nà, ní ìkóríta, láti wá àmìn nǹkan tí ń bọ̀: Yóò fi ọfà di ìbò, yóò bèèrè lọ́wọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, òun yóò ṣe àyẹ̀wò ẹ̀dọ̀.
22
Nínú ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni ìbò Jérúsálẹ́mù yóò ti wá, ní ibi tí yóò ti gbé afárá kalẹ̀, láti pàṣẹ fún àwọn apànìyàn, láti mú ki wọn hó ìhó ogun láti gbé òòlù dí ẹnu ọ̀nà ibodè, láti mọ odi, àti láti kọ́ ilé ìṣọ́.
23
Yóò dàbí àmì èké sí àwọn tí ó ti búra ìtẹríba fún un, ṣùgbọ́n òun yóò ran wọn létí ẹbí wọn yóò sì mú wọn lọ sí ìgbèkùn.
24
“Nítorí náà èyíí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Nítorí ti ẹ̀yin ti mú ẹ̀bi yín wá sí ìrántí nípa ìṣọ̀tẹ̀ ní gbangba, ní ṣíṣe àfihàn àwọn ẹ̀sẹ̀ rẹ nínú gbogbo ohun tí ó ṣe, nítorí tí ẹ̀yin ti ṣe èyí, a yóò mú yín ní ìgbékùn.
25
“ ‘Ìwọ aláìmọ́ àti ẹni búburú ọmọ aládé Ísírẹ́lì, ẹni ti ọjọ́ rẹ̀ ti dé, ẹni tí àsìkò ìjìyà rẹ̀ ti dé góngó,
26
Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí: Tú ìwérí kúrò kí o sì gbé adé kúrò. Kò ní rí bí ti tẹ́lẹ̀: Ẹni ìgbéga ni a yóò sì rẹ̀ sílẹ̀,
27
Ìparun! Ìparun! Èmi yóò sé e ni ìparun! Kì yóò padà bọ̀ sípò bí kò se pé tí ó bá wá sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ni in; òun ni èmi yóò fifún.’
28
“Àti ìwọ, ọmọ ènìyàn sọ̀tẹ̀lẹ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí nípa àwọn ará Ámónì àti àbùkù wọn: “ ‘Idà kan idà kan tí á fa yọ fún ìpànìyàn tí a dán láti fi ènìyàn ṣòfò àti láti kọ bí ìmọ̀nàmọ́ná!
29
Bí ó tilẹ jẹ́ pé a rì èké nípa yín àti àfọ̀sẹ èké nípa yín a yóò gbé e lé àwọn ọrùn ènìyàn búburú ti a yóò pa, àwọn tí ọjọ́ wọn ti dé, àwọn tí ọjọ́ ìjìyà wọn ti dé góńgó.
30
Dá idà padà sínú akọ rẹ̀ Níbi tí a gbé sẹ̀dá yín, ní ibi tí ẹ̀yin ti sẹ̀ wá.
31
Níbẹ̀ ni èmi yóò ti ṣe ìdájọ́ yín, èmi yóò sì fi èémí ìbínú gbígbóná mi bá yín jà.
32
Ẹ̀yin yóò jẹ́ èpò fún iná náà, a yóò ta ẹ̀jẹ̀ yin sórí ilẹ̀ yín, a ki yóò rántí yín mọ́; nitorí èmi OLÚWA ní ó ti wí bẹ́ẹ̀.’ ”
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 41
Chapter 42
Chapter 43
Chapter 44
Chapter 45
Chapter 46
Chapter 47
Chapter 48
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48