bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 10
Hosea 10
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 11 →
1
Ísírẹ́lì jẹ́ igi àjàrà tó gbalé ó ń sọ èṣo fún ara rẹ̀ Bí èso rẹ̀ ṣe ń pọ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó ń kọ́ pẹpẹ sí i bí ilẹ̀ rẹ̀ ṣe ń ṣe rere Ó bu ọlá fún òkúta ìyàsọ́tọ̀ ère rẹ̀.
2
Ọkàn wọn kún fún ìtànjẹ báyìí wọ́n gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn. OLÚWA yóò wó pẹpẹ wọn palẹ̀ yóò sì pa gbogbo òkúta ìyàsọ́tọ̀ wọn run.
3
Nígbà náà ni wọn yóò wí pé, “A kò ní ọba nítorí tí a kò bọ̀wọ̀ fún OLÚWA ṣùgbọ́n bí a tilẹ̀ ní ọba, kí ni yóò se fún wa?”
4
Wọ́n ṣe ìlérí púpọ̀, wọ́n ṣe ìbúra èké, wọ́n da májẹ̀mú: báyìí ni ìdájọ́ hù sókè bí igi ìwọ̀ ni aporo oko, bi i koríko májèlé láàrin oko tí a ro.
5
Àwọn ènìyàn tí ń gbé Samáríà bẹ̀rù nítorí ere màlúù tó wà ní Bẹti-Áfẹ́nì Àwọn ènìyàn rẹ̀ yóò ṣọ̀fọ̀ le e lórí bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà rẹ̀ Gbogbo àwọn tó láyọ̀ sì dídán rẹ̀, nítorí ogo rẹ̀ nítorí o tí lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
6
A ó gbé lọ sí Ásíríà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún ọba ńlá a ó dójú ti Éfúráímù; oju yóò ti Ísírẹ́lì nítorí ere òrìṣà rẹ̀
7
Bí igi tó léfòó lórí omi ni Samaríà àti àwọn ọba rẹ yóò ṣàn lọ.
8
Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà buburú ni a o parun— Ẹ̀sẹ̀ Ísírẹ́lì ni. Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde, yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn. Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!” àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”
9
“Láti ìgbà Gíbíà, ni ó ti sẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lì ìwọ sì tún wà níbẹ̀. Njẹ́ ogun kò lé ẹ̀yin aṣebi ni Gíbíà bá bí?
10
Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n; Orílẹ̀ èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojú kọ wọn Láti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
11
Éfúráímù jẹ́ ọmọ màlúù tí a tí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkà lórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà ni èmi ó dí ẹru wúwo lé Èmi yóò mú kí a gun Éfúráímù bí ẹṣin Júdà yóò tú ilẹ̀, Jákọ́bù yóò sì fọ́ ogúlùtu rẹ̀
12
Ẹ gbin òdòdó fún ara yín kí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin, Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kòro nítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá OLÚWA, títí tí yóò fi dé, tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.
13
Ṣùgbọ́n ẹ tí gbìn buburú ẹ si ka ibi, Ẹ ti jẹ èso èké nítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀ lé agbára yín àti àwọn ọ̀pọ̀ jagun jagun yín
14
ariwo ogun yóò bo àwọn ènìyàn yín kí gbogbo odi agbára yín ba le parun. Gẹ́gẹ́ bí Ṣalìmanì ṣe pa Bétí-Ábélì run lọ́jọ́ ogun, nígbà tí a gbé àwọn ìyá ṣánlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn
15
Báyìí ni a o sì ṣe sí ọ, ìwọ Bétélì, nítorí pé ìwà buburú yín ti pọ̀jù. Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ náà, a o pa ọba Ísírẹ́lì run pátapáta.
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14