bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 11
Hosea 11
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 12 →
1
“Nígbà tí Ísírẹ́lì wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀, mo sì pe ọmọ mi jáde wá láti Éjíbítì.
2
Wọ́n rúbọ sí Báálì bí mo ṣe ń pe Ísírẹ́lì sí bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi jìnnà sí i: wọn rúbọ sí báálímu, wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
3
Lóòtọ́ mo kọ́ Éfúráímù pẹ̀lú ní ìrìn mo di wọ́n mú ní apá, ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé mo ti mú wọn lára dá.
4
Mo fó okùn ènìyàn fà wọ́n àti ìdè ìfẹ́. Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn Mo sì farabalẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.
5
“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Éjíbítì bí Ṣé Ásíríà kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronú pìwàdà?
6
Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn yóò si bá gbogbo irin ẹnú odi ìlú wọn jẹ́ yóò sì fòpin sí gbogbo èrò wọn.
7
Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi Bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ ọ̀gá-ògo júlọ, kò ní gbé wọn ga rárá.
8
“Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Éfúráímù? Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Ísírẹ́lì Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ádímà? Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣébóímù? Ọkàn mi yípadà nínú mi Àánú mi sì ru sókè
9
Èmi kò ni i mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ tàbí kí èmi wá sọ Éfúráímù di ahoro Nítorí pé Ọlọ́run ni àni, èmi kì í ṣe ènìyàn Ẹni mímọ́ láàrin yín, Èmi kò ni i wa nínú ìbínú
10
Wọn yóò máa tẹ̀lé OLÚWA; òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún Nígbà tó bá bú àwọn ọmọ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀ oòrùn.
11
Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù bi i ẹyẹ láti Éjíbítì bi i àdàbà láti Ásíríà Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,” ni OLÚWA wí.
12
Éfúráímù tí fi irọ́ yí mi ká ilé Ísírẹ́lì pẹ̀lú ẹ̀tàn. Ṣùgbọ́n Júdà sì dúró ṣinṣin pẹ̀lú Ọlọ́run Ó sì ṣe olóòótọ́ sí Ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
← Chapter 10
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 12 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14