bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 3
Hosea 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 4 →
1
OLÚWA sì wí fún mi pé, “Lọ, fi ìfẹ́ hàn sí ìyàwó rẹ̀ padà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlòmíràn ti fẹ́ ẹ, tí òun sì tún jẹ́ alágbèrè. Fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ṣe fẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tẹ́lé àwọn òrìṣà tí ó sì fẹ́ràn oúnjẹ tí àwọn aláìkọlà yà sọ́tọ̀.”
2
Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀dógún (15) àti Ómírì kan àti lẹ́tíkì báálì kan.
3
Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú ù rẹ.”
4
Nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láì ní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́ láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan.
5
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà láti wá OLÚWA Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú OLÚWA pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún OLÚWA àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14