bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 12
Hosea 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 13 →
1
Éfúráímù ń jẹ afẹ́fẹ́; Ó n lépa afẹ́fẹ́ ìwọ̀ oòrùn ní gbogbo ọjọ́. Ó sì ń gbèrú nínú irọ́ Ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ásíríà Ó si fi òróró ólífì ránsẹ́ sí Éjíbítì.
2
OLÚWA ní ẹ̀sùn tí yóò fí kan Júdà yóò fìyà jẹ Jákọ́bù gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀ yóò sì sán fún-un gẹ́gẹ́ bí i ìṣe rẹ̀.
3
Láti inú oyun ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀, àti nípa ìpá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run
4
Ó bá ángẹ́lì ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀ Ó sunkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀ Ó bá OLÚWA ní Bẹ́tẹ́lì Ó sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,
5
àní OLÚWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; OLÚWA ni orúkọ ìrántí rẹ̀
6
Ṣùgbọ́n ìwọ́ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀; Di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo mú kí ẹ sì dúró de OLÚWA yín nígbà gbogbo.
7
Oníṣòwò ń lo òṣùnwọ̀n èké Ó fẹ́ràn láti rẹ́nijẹ.
8
Éfúráímù gbéraga, “Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀, pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́”
9
“Èmi ni OLÚWA Ọlọ́run rẹ; ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì; èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́ bí i ọjọ́ àjọ mímọ́ wọ̀n ọn nì
10
Mo sọ fún àwọn wòlíì, mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́n mo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”
11
Gílíádì ha burú bí? Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán. Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì? Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebè nínú aporo oko.
12
Jákọ́bù sá lọ si orílẹ̀ èdè Árámù; Ísírẹ́lì sìn kí o tó fẹ ìyàwó ó ṣe ìtọjú ẹran láti fi san owó ìyàwó.
13
OLÚWA lo wòlíì kan láti mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì, nípaṣẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
14
Ṣùgbọ́n Éfúráímù ti mú un bínú gidigidi; OLÚWA rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí orí rẹ̀ òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14