bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hosea 6
Hosea 6
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 7 →
1
“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ OLÚWA ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ ṣùgbọ́n yóò mú wa lára dá Ó ti pa wá lára ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
2
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
3
Ẹ jẹ́ kí a mọ OLÚWA Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀ṣíwájú láti mọ̀ ọ́. Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ, Yóò jáde; Yóò tọ̀ wá wá bí òjò bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
4
“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Éfúráímù? Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Júdà? Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùku òwúrọ̀ bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
5
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì. Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
6
Nítorí pé mo fẹ́ àánú, kì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ́ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
7
Bí i Ádámù, wọ́n da májẹ̀mú wọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi níbẹ̀.
8
Gílíádì jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
9
Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùbá de àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀; tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣékémù, tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10
Mo ti rí ohun tó bani lẹ́rù ní ilé Ísírẹ́lì. Níbẹ̀ Éfúráímù, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè Ísírẹ́lì sì di aláìmọ́.
11
“Àti fún ìwọ, Júdà A ti yan ọjọ́ pẹ̀lú ìkórè rẹ “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14